David Lyon (olóṣèlú)

(Àtúnjúwe láti David Lyon)

David Lyon (tí wọ́n bí ní ogún jọ oṣù Kejìlá ọdún 1970) jẹ́ olùṣòwọ àti olóṣèlú ọmọ ìpínlẹ̀ Bayelsa lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1] Ó yàtọ̀ sí David Lyon ọmọ ti orílẹ̀ èdè West Indies tí ó jẹ́ gbajúmọ̀ olùṣòwò àti òṣèlú bákan náà. David Lyon tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ wọlé gẹ́gẹ́ bí gómìnà-aṣẹ̀ṣẹ̀-yàn ní ìpínlẹ̀ Bayelsa lábẹ́ àṣẹ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress. Ó borí akẹgbẹ́ rẹ̀ tí ẹgbẹ́ òṣèlú People’s Democratic Party, Duoye Diri. [2] [3]

Ìgbésí ayé rẹ̀Àtúnṣe

David Lyon Perewonrimi jẹ́ olùdarí àti Aláṣẹ ilé-iṣẹ́ àdáni àbó, Darlon Security and Guard, ní ìpínlẹ̀ Bayelsa. Ó jẹ́ ọmọ bíbí ẹbí Olodiana ni ìjọba ìbílẹ̀ Southern Ijaw ni ìpínlẹ̀ Bayelsa. Ó jẹ́ gbajúmọ̀ olówó àti olùṣowò, ṣùgbọ́n wọn kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ ọ́n lágbo òṣèlú. Lọ́dún 2011 ni ó kọ́kọ́ díje dupò fún ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Ìpínlẹ̀ Bayelsa ní ẹkùn ìdìbò kẹrin ti Gúsù Ijaw lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú People's Democratic Party ṣùgbọ́n kò wọlé Lẹ́yìn náà, ó dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress lọ́dún 2015.in 2011. Lọ́dún 2019, ẹgbẹ́ APC fà á kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí adíje dupó fún gómìnà ìpínlẹ̀ Bayelsa. Ó sì borí nínú ìdìbò tó wáyé ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kọkànlá ọdún 2019. Àjọ elétò ìdìbò lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà kéde rẹ̀ lọ́jọ́ kejidinlogun oṣù kọkànlá ọdún 2019 pé òun ló wọlé. Ó wọlé pẹ̀lú àmín ìbò 352,552, akẹgbẹ́ rẹ̀ tí ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní àmìn ìbò 143,172.[4]

David Lyon ni Gómìnà àkọ́kọ́ nínú ẹgbẹ́-òṣèlú alátakò tí yóò jẹ gómìnà ní ìpínlẹ̀ Bayelsa, ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní ó tí ń wọlé gẹ́gẹ́ bíi gómìnà ìpínlẹ̀ náà láti ọdún 1999 tí òṣèlú àwarawa ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ padà lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà.[5][6]

Àwọn Ìtọ́kasíÀtúnṣe

  1. Adegun, Aanu (2019-11-18). "Profile of the incoming Bayelsa state governor David Lyon". Legit.ng - Nigeria news. Retrieved 2019-11-18. 
  2. "Bayelsa election: Buhari congratulates governor-elect, David Lyon". Punch Newspapers. 2015-12-15. Retrieved 2019-11-18. 
  3. "Bayelsa: Between Douye Diri and David Lyon - THISDAYLIVE". THISDAYLIVE. 2019-09-21. Retrieved 2019-11-18. 
  4. "INEC Declares APC’s David Lyon Winner Of Bayelsa Governorship Election". Channels Television. 2019-11-18. Retrieved 2019-11-18. 
  5. "Who be David Lyon, di new Bayelsa State Governor". BBC News Pidgin. 2019-11-18. Retrieved 2019-11-18. 
  6. "Wo ohun mẹ́wàá nípa gomina tuntun tí wọ́n dìbò yàn ní Bayelsa". BBC News Yorùbá (in Èdè Latini). November 18, 2019. Retrieved November 18, 2019.