Deborah Abiodun
Deborah Ajibola Abiodun, tí ọ̀pọ̀ ènìyàn mọ̀ sí "Kante," jẹ́ ọ̀kan lára àwọn agbábọ́ọ̀lù orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ọjọ́ kejì oṣù kọkànlá ọdún 2003 ni wọ́n bí, sí ìlú Ìbàdàn, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[2]
https://twitter.com/leaguesreporter/status/1682235398200737797?s=46&t=LDnJVTk0szyjJtkU-4H3xA | |||
Personal information | |||
---|---|---|---|
Ọjọ́ ìbí | 2 Oṣù Kọkànlá 2003 | ||
Ibi ọjọ́ibí | Ibadan, Nigeria | ||
Ìga | 1.67 m[1] | ||
Playing position | Midfielder | ||
Club information | |||
Current club | Pittsburgh Panthers | ||
Senior career* | |||
Years | Team | Apps† | (Gls)† |
Rivers Angels | |||
National team | |||
2022– | Nigeria | 3 | (0) |
* Senior club appearances and goals counted for the domestic league only. † Appearances (Goals). |
Ìfẹ́ tí Deborah ní fún eré bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá láti ìgbà èwe rẹ̀ ló mu tayọ̀ nínú eré náà.[3] Ó bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò iṣẹ́ yìí pẹ̀lú ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Rivers Angels lábẹ́ àsíà ẹgbẹ́ àwọn agbábọ́ọ̀lù-bìnrin ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìmọ̀ọ́ṣe rẹ̀ ló mu gba ètò ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ láti ọwọ́ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù fún àwọn obìnrin ti University of Pittsburgh ní United States.[4]
Ìmọ̀ọ́ṣe Deborah ló mu ṣiṣẹ́ takuntakun gẹ́gẹ́ bí i Central Midfielder (CMF), Attacking Midfielder (AMF), Defensive Midfielder (DMF) àti agbábọ́ọ̀lù tó tayọ.[5]
2023 World Cup
àtúnṣeNí ọdún 2023, ní ọmọdún mọ́kàndínlógún, Deborah kópa nínú FIFA Women's World Cup fún Nàìjíríà, ní ìtako pẹ̀lú canada fún ìpènijà ti Ashley Lawrence.[6] Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ko sí ẹgbẹ́ kankan tó ju bọ́ọ̀lù sáwọ̀n nínú eré náà, ìṣọwọ́ gbá bọ́ọ̀lù rẹ̀ mú kí ojú wà ní ara rẹ̀, títí wọ́n fi gbá bọ́ọ̀lù tán.[1]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Profile of Deborah Abiodun". soccerway.com. Soccerway. Retrieved 9 July 2023.
- ↑ Sanyaolu, Isaac (2023-07-22). "Deborah Abiodun – Nigeria | Player Profile". Futball Naija (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-01-20.

- ↑ "Nigeria’s Deborah Abiodun handed first red card of FIFA Women’s World Cup 2023". The Hindu. 23 July 2023.