Dele Bakare
Dele Bakare (tí orúkọ àbísọ rẹ̀ ń jẹ́ Oladele Ibukun Bakare ni ẃn bí ní 8 February 1989) jẹ́ onímọ̀-ẹ̀rọ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti oníṣòwò tó wá láti ìlú Ìbàdàn, ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Òun ni ó ṣe ìdásílẹ̀ Findworka, èyí tó jẹ́ ilé-iṣẹ́ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó ń gba àwọn oníṣẹ́-ẹ̀rọ láti pèsè àwọn ohun tó ní ṣe pẹ̀lú ẹ̀rọ. Ó fìgbà kan jẹ́ onímọ̀-ẹ̀rọ àgbà ní Infinion Technologies and technology, ní BudgIT.[1] Ní ọdún 2016, wọ́n yàn án fún àmì-ẹ̀yẹ Future Awards Africa ti ìmọ̀ sáyẹ̀ǹsì àti ìmọ̀-ẹ̀rọ.[2]
Dele Bakare | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Oladele Ibukun Bakare 8 Oṣù Kejì 1989 |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian, |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Anglia Ruskin University, |
Iṣẹ́ |
|
Website | findworka.com |
Iṣẹ́ tó yàn láàyò
àtúnṣeKí ó tó gba diploma nínú ìmọ̀-ẹ̀rọ ní NIIT,[3] Dele ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí onímọ̀-ẹ̀rọ ní Infinion technologies. Ó kúrò ní Infinion technologies láti lo ṣèdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ ní Nàìjíríà[4] pẹ̀lú Temitayo Olufuwa. Lọ́wọ́lọ́wọ́, ó jẹ́ ọmọ-ẹgbẹ́ Swiss Africa Business Innovation & Initiative and Founders Gym, èyí tó jẹ́ ẹ̀kọ́ orí-ayélujára tó máa ń kọ́ àwọn olùdásílẹ̀ lóríṣịríṣi láti rí owó fún ilé-iṣẹ́ wọn.
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Highlights of BudgIT-Tracka Capacity Building Workshop for CBOs in Kaduna.". Tracka Blog. May 4, 2017. Archived from the original on July 4, 2020. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "And the nominees are... The Future Awards Africa unveils those in the running for Africa's biggest prize for youth...". The future africa. 2016-12-04.
- ↑ Emeka, Mazi (October 17, 2016). "#Impact365: Connecting people to job opportunities | How Dele Bakare of findworka makes it happen". Ynaija.
- ↑ "JobsInNigeria – A Job Search Engine in Nigeria". CYFI News. 16 January 2014.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]