Sir Donald Charles "Don" McKinnon, ONZ, GCVO (tí a bí ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n ọdún kejì, ọdún 1939) ni igbákejì alákoso àgbà àti alákòóso ọ̀rọ̀ òkèèrè nígbà kan rí fún orílẹ̀-èdè New Zealand. Òun tún ni Akowe Agba fún ẹgbẹ́ Ajoni awon Orile-ede láti ọdún 2000 títí di 2008.


Sir Donald McKinnon


ONZ GCVO
4th Commonwealth Secretary-General
In office
1 April 2000 – 1 April 2008
AsíwájúEmeka Anyaoku
Arọ́pòKamalesh Sharma
12th Deputy Prime Minister of New Zealand
In office
2 November 1990 – 16 December 1996
Alákóso ÀgbàJim Bolger
AsíwájúHelen Clark
Arọ́pòWinston Peters
24th Minister of Foreign Affairs
In office
2 November 1990 – 5 December 1999
Alákóso ÀgbàJim Bolger (1990 - 1997)
Jenny Shipley (1997 - 1999)
AsíwájúMike Moore
Arọ́pòPhil Goff
Member of Parliament for Albany
In office
1978–1993
AsíwájúSeat established
Arọ́pòMurray McCully
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí27 Oṣù Kejì 1939 (1939-02-27) (ọmọ ọdún 85)
London, Ilẹ̀ọba Aṣọ̀kan Ilẹ̀ọba Aṣọ̀kan
Ẹgbẹ́ olóṣèlúNational

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n bí McKinnon sí Blackheath, ní London. Bàbá rẹ̀ ni Walter McKinnon, tó jẹ́ olóyè fún àwọn òṣìṣẹ́ gbogboogbò, ó sì tún fìgbà kan jẹ́ ààrẹ New Zealand Broadcasting Corporation. Àwọn àbúrò rẹ̀ ní John McKinnon, àti Malcom McKinnon. Àwọn àbúrò rẹ̀ yìí jẹ́ bàbá-ńlá John Plimmer, tí àwọn èèyàn tún mọ̀ sí "father of Wellington".[1]

McKinnon kàwé gboyè ní ilé-ìwé Khandallah, ó sì tún lọ Nelson College láti ọdún 1952 wọ 1953.[2] Ní ọdún 1956, ó kékọ̀ọ́ gboyè ní ilé-ìwé Woodrow Wilson, ní Washington, D.C.[3] McKinnon tún lọ ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti Lincoln Agricultural college, ní New Zealand. Ó padà di olùdarí oko kan, ó tún wá padà dí ẹni tí àwọn ènìyàn ń bẹ̀ wò fún iṣẹ́ oko.

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Dominion Post 18 June 2009 page C2
  2. Nelson College Old Boys' Register, 1856–2006, 6th edition
  3. McKinnon, Don (2006-05-25), Building Sustainable Democracies – the Commonwealth way (PDF), Center for Strategic and International Studies [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]