Doria Achour

Trans-YO=FÍranṣṢẹ̀lẹẹbù

Doria Achour (tí a bí ní 1 Oṣù Kẹẹ̀ta, Ọdún 1991) jẹ́ òṣèrébìnrin àti olùdarí eré ọmọ orílẹ̀-èdè Fránsì ati Tùnísíà.

Doria Achour
Ọjọ́ìbí1 Oṣù Kẹta 1991 (1991-03-01) (ọmọ ọdún 33)
Orílẹ̀-èdèFrench-Tunisian
Iléẹ̀kọ́ gígaParis-Sorbonne University
Paris Diderot University
Iṣẹ́Film director, actress
Ìgbà iṣẹ́2002-present

Ìsẹ̀mí rẹ̀

àtúnṣe

Achour jẹ́ ọmọ sí olùdarí fíìmù àti òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè Tùnísíà Lotfi Achour àti ìyá tí n ṣe ònkọ̀tàn ọmọ orílẹ̀-èdè Rọ́síà. Arákùnrin ẹ̀gbọ́n rẹ̀ jẹ́ ònkọ̀tàn bẹ́ẹ̀ ló sì tún ní arákùnrin àbúrò. Nígbà tí ó wà lọ́mọdé, ó maá tẹ̀lé àwọn òbí rẹ̀ ní àkókò àwọn ìgbaradì wọn fún àwọn eré wọn.[1]

Ní ọdún 2002, Achour kó ipa ọmọbìnrin Sergi Lopez nínu eré Les Femmes ... ou les enfants d'abord ..., èyí tí Manuel Poirier darí. Ìyá rẹ̀ ló ṣètò bí ó ti ṣe rí ipa náà. Lẹ́hìn kíkópa náà, Achour lọ fún àwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan ní Théâtre des Déchargeurs fún ọdún kan gbáko. Ó kó àwọn ipa amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ nínu àwọn fíìmù bíi L'enemi naturel ati L'École pour tous.[2] Láti gbájúmọ́ ètó ẹ̀kọ́ rẹ̀, Achour dá ṣíṣe iṣẹ́ fíìmù rẹ̀ dúró fún ọdún mélòó kan.[3] Achour gba oyè-ẹ̀kọ́ nínu ìmò lítíréṣọ̀ láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga Paris-Sorbonne University, lẹ́hìn náà ló gba oyè gíga nínu ìmọ̀ sinimá láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga Paris Diderot University.

Ní ọdún 2012, Achour kó ipa Yasmeen nínu eré La fille publique. Ní ọdún 2013, Achour darí àkọ́kọ́ fíìmù oníṣókí rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Laisse-moi finir, èyí tí ó dá lóri àwọn rògbòdìyàn tí ó n ṣẹlẹ̀ ní Tùnísíà lẹ́hín ìfẹ̀hónú hàn àwọn ẹlẹ́sìn mùsùlùmí. [2] Wọ́n wo fíìmù náà níbi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ayẹyẹ àjọ̀dún tó sì gba àmì-ẹ̀yẹ níbi ìdíje kan ti ọdún 2014. Iṣé takuntakun rẹ̀ nínu fíìmù La fille publique mú kí olùdarí Sylvie Ohayon pèé láti darapọ̀ mọ́ àwọn olúkópa gẹ́gẹ́ bi Stephanie nínu fíìmù Papa Was Not a Rolling Stone ti ọdún 2014. Ní ọdún 2016, Achour kó àkọ́kọ́ ipa rẹ̀ lédè lárúbáwá nínu fíìmù Burning Hope.[4] Ó tún darí fíìmù oníṣókí tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Le reste est l'œuvre de l'homme, èyítí ó gba àmì-ẹ̀yẹ níbi ayẹyẹ Sundance Film Festival ti ọdún 2017.[5] Ó tún kó ipa Leila nínu fíìmù Naidra Ayadi kan ti ọdún 2018 tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́, Ma fille.[6]

Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀

àtúnṣe
  • 2002: Les Femmes... ou les enfants d'abord...
  • 2004: L'enemi naturel
  • 2005: L'Annulaire
  • 2006: L'École pour tous
  • 2012: La fille publique
  • 2013: Laisse-moi finir (short film, director)
  • 2014: Papa Was Not a Rolling Stone
  • 2014: Demain dès l’aube (short film, director)
  • 2016: Burning Hope
  • 2017: Le reste est l’œuvre de l’homme (director)
  • 2018: Ma fille

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Doria Achour". Voici (in French). Retrieved 8 October 2020. 
  2. 2.0 2.1 "Doria Achour, la révélation de Papa was not a Rolling Stone" (in French). http://www.lexpress.fr/culture/cinema/doria-achour-la-revelation-de-papa-was-not-a-rolling-stone_1603532.html. Retrieved 8 October 2020. 
  3. "Doria Achour". Voici (in French). Retrieved 8 October 2020. 
  4. "Doria Achour, un travelling entre Paris et Tunis" (in French). https://www.lemonde.fr/afrique/article/2015/06/19/doria-achour-un-travelling-entre-paris-et-tunis_4658141_3212.html. Retrieved 8 October 2020. 
  5. Sepulveda, Elsa (29 May 2017). "« Le reste est l’œuvre de l’homme », prix du jury du concours Sundance TV". MediaKwest (in French). Retrieved 8 October 2020. 
  6. "'Ma Fille': Film Review". https://www.hollywoodreporter.com/review/ma-fille-review-1147414. Retrieved 8 October 2020. 

Àwọn ìtakùn Ìjásóde

àtúnṣe