Duncan Mighty
Duncan Wene Mighty Okechukwu (wọ́n bíi ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹwàá ọdún 1983),[2] ẹni tí a mọ̀ sí Duncan Mighty, jẹ́ olórin orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, akọrin àti olóòótú orin láti ìlú Obio-Akpor, ní ìpínlẹ̀ Rivers. [3] Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé irú ọ̀wọ́ orin rẹ̀ wà lábẹ́ ọ̀wọ́ orin ìdárayá tí àwọn olóyìnbó pè ní high-level tí ó jẹ́ ọ̀wọ́ orin gbajúgbajà, ó tún gbilẹ̀ si látàrí àwọn ìró àti àṣà àwọn ènìyàn rẹ̀ nítorí púpọ̀ àwọn orin rẹ̀ yìí ni ó kọ ní èdè abínibí rẹ̀ èdè Ikweage.[4]
Duncan Mighty | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 28 Oṣù Kẹ̀wá 1983 Port Harcourt, ìpínlẹ̀ Rivers, Nigeria |
Iṣẹ́ |
|
Olólùfẹ́ | Vivien Okechukwu (m. 2015) |
Musical career | |
Irú orin | |
Years active | 2006–present |
Labels |
|
Associated acts |
|
Wene Mighty ṣàgbéjáde àwo orin rẹ̀ tí ó kún fọ́fọ́ tí àkọlé rẹ̀ ń jẹ́ (Koliwater) ní ọdún 2009, tí àwọn ènìyàn sì tẹ́wọ́ gbà. Àwọn orin méjìlélógún inú àwo orin náà bí àwọn orin gbajúgbajà bí i "Ijeoma", "Scatter My Dada", "Ako Na Uche" tí ó sì fa ọkàn àwọn olólùfẹ́ orin síi jákèjádò orílẹ̀-èdè. Àwo orin rẹ̀ kejì tí ó pè ní, Legacy (Ahamefuna) ni ó gbé jáde ní ọdún 2010 pẹ̀lú àwọn ọ̀wọ́ orin márùndínlógún tí ó kéré sí ti t'àkọ́kọ́ tó gbé jáde. Àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ tẹ́wọ́ gba àwo dáradára pẹ̀lú àjọ aficionados.[4] àwọn orin rẹ̀ bíi "Obianuju" àti "Port Harcourt son" sọ ọ́ di ìlú-mọ̀ọ́ká tí ó sì ṣokùnfà àlékún àwọn olólùfẹ́ rẹ̀.[5] Ó wà lára àwọn tí wọ́n yàn fún àmì-ẹ̀yẹ ní ipele mẹ́ta ní NEA Ards ẹlẹ́ẹ̀kẹfà irú rẹ̀ ti ọdún 2011 tí ó sì gbégbá orókè ní ipele ti "Indigenous Artist of the Year".[6]
Ní oṣù kẹsàn-án ọdún 2012, Wene Mighty ṣàgbéjáde àwo orin tí ó pè ní Footprints, àwo ọ̀wọ́ orin méjìdínlógún pẹ̀lú àjọṣepọ̀ àwọn òṣèré látorí Timaya, Shaggy, Otuu Sax, Sandaz Black àti Wande Coal.[7] Àwọn àjọ UN foyè dáa lọ́lá gẹ́gẹ́ bíi peace Ambassador.[8]
Àtòjọ orin rẹ̀
àtúnṣeÀwo-orin ti studio
àtúnṣe- Koliwater (2009)
- Ahamefuna (Legacy) (2010)
- Footprints (2012)
- Grace & Talent (2014)
- The Certificate (2016)
Àtòjọ àwọn àmì-ẹ̀yẹ rẹ̀
àtúnṣeÈyí ni àtòjọ àwọn àmì-ẹ̀yẹ tí Duncan Mighty ti gbà.
Year | Event | Prize | Nominated work | Result | Ref |
---|---|---|---|---|---|
2011 | The Headies 2011 | Artiste of the Year | style="background: #FDD; color: black; vertical-align: middle; text-align: center; " class="no table-no2"|Wọ́n pèé | ||
Nigeria Entertainment Awards | Best Album of the Year | style="background: #FDD; color: black; vertical-align: middle; text-align: center; " class="no table-no2"|Wọ́n pèé | |||
Hottest Single of the Year | style="background: #FDD; color: black; vertical-align: middle; text-align: center; " class="no table-no2"|Wọ́n pèé | ||||
Indigenous Artist of the Year | Gbàá | [9] | |||
2012 | Ghana Music Awards | African Artist of the Year | style="background: #FDD; color: black; vertical-align: middle; text-align: center; " class="no table-no2"|Wọ́n pèé | [10] |
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Indigenous rapper out with "A Trip To The South" album". Pulse.ng. Archived from the original on 2018-11-10. Retrieved 2023-01-21.
- ↑ Emmanuel, Nancy. "Duncan Mighty Celebrates His Birthday Handing Out Bags of Rice To Widows (Photos)". Goodlife.com.ng. Archived from the original on 14 February 2014. Retrieved 5 February 2014.
- ↑ "Growing up on the street has humbled me—Duncan Mighty". Web.archive.org. http://www.thenationonlineng.net/2011/index.php/saturday-magazine/weekend-treat/entertainment/41583-growing-up-on-the-street-has-humbled-me—duncan-mighty.html.
- ↑ 4.0 4.1 "The 'Legacy' Of Duncan Mighty". TheNet.ng. 12 July 2010. Archived from the original on 1 February 2014. Retrieved 5 February 2014.
- ↑ "Duncan Mighty Ready To Rock Accra at The "Yes Boss" Concert". Peacefmonline.com. Archived from the original on 21 February 2014. Retrieved 5 February 2014. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Nigeria Entertainment Awards 2011 Winners". Information Nigeria. 6 September 2011. Retrieved 5 February 2014.
- ↑ "Duncan Mighty's Footprints". DSTV. 12 September 2012. Archived from the original on 22 February 2014. Retrieved 5 February 2014. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Duncan Mighty, Nigerian Musician". Nigeria Music Box. Archived from the original on 6 March 2014. Retrieved 6 March 2014.
- ↑ "Nigeria Entertainment Awards 2011 Winners". Information Nigeria. 6 September 2011. Retrieved 5 February 2014.
- ↑ "Ghana Music Awards 2012". Channel O. 1 March 2012. Archived from the original on 6 March 2014. Retrieved 6 March 2014. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help)