Ebrahim Desai
Ebrahim Desai (ọjọ́ ẹ̀rìn-dín-lógún oṣù kìíní ọdún 1963 sí ọjọ́ márùn-ún dín lógún oṣù kéje ọdún 2021) jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ẹ̀sìn mùsùlùmí orílẹ̀-èdè South Africa àti olófin tí ó ṣe ìdásílẹ̀ Darul Iftaa Mahmudiyyah, ojú Askimam fatawa àti pé ó jẹ́ olùkọ́ àgbà ti hadith ní Madrasah In'aamiyyah. Ó jẹ́ ọmọ ilé-ìwé ti Jamiah Islamiah Talimuddin Dabhel àti pé ó wà láàrin ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta Àwọn Mùsùlùmí tí ó ní ipa jùlọ. Ó kọ́ àwọn ìwé pẹ̀lú òrọ̀ àsọyè lórí Qaseedah Burdah, ọ̀rọ̀ ìsáájú sí Hadīth àti ọ̀rọ̀ ìsáájú sí Ìṣòwò Ìsìlámù.
Mufti Ebrahim Desai | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Richmond, Natal, South Africa | 16 Oṣù Kínní 1963
Aláìsí | 15 July 2021 Durban, South Africa | (ọmọ ọdún 58)
Iléẹ̀kọ́ gíga | Jamiah Islamiah Talimuddin Dabhel |
Gbajúmọ̀ fún | Askimam |
Notable work | list_style=margin-left:0;|Commentary on Qaseedah Burdah|Introduction to Hadīth|Introduction to Islamic Commerce |
Movement | Deobandi[1] |
Ìgbésí Ayé Rẹ̀
àtúnṣeWọ́n bí Ebrahim Desai ní ọjọ́ ẹ̀rìn-dín-lógún-lógún oṣù kìíní ọdún 1963, ní Richmond, Natal. [2] Ó kọ́ Quran sórí ní Waterval Islamic Institute àti pé ó kẹ́kọ̀ọ́ ìbílẹ̀ Dars-i Nizami ní Jamia Islamia Talimuddin ní Gujarat, orílẹ̀-èdè India. [3] Ó dá lórí Islamic jurisprudence lábẹ́ Ahmad Khanpuri. [3] Ó tún tẹ̀síwájú pẹ̀lú Grand Mufti ti Darul Uloom Deoband ti tẹ́lẹ̀, Mahmood Hasan Gangohi, òǹkọ̀wẹ́ ti multi-volume Fatawa Mahmudiyyah ó sì dí ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ tí a fún ní àṣẹ ní Sufism.[3][4]
Desai jẹ́ olùkọ́ ní Madrasah Ta῾līmuddīn, ní òkun Isipingo fún ọdún mẹ́wàá, àti pé ó jẹ́ olórí ẹ̀ka Fatwa ti Jamiatul Ulama Kwazulu Natal. [5][6] Ó sìn gẹ́gẹ́ bí ọ̀jọ̀gbọ́n àgbà ti hadith ní Madrasah In’aamiyyah fún ọdún mẹ́wàá mìíràn, ó sì ṣe olórí Darul Ifta rẹ̀. [5][6] Ní oṣù kẹta ọdún 2008, ó rin ìrìn-àjò lọ sí Hong Kong láti kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní Islamic Kasim Tuet Memorial College. [7] Ní ọdún 2011, ó yípadà sí Durban ó sì ṣètò Darul Iftaa Mahmudiyyah ní Sherwood. [5] Ó kọ́ Sahih Bukhari ní Darul Uloom Nu'maniyyah ó sì darí Darul Iftaa Mahmudiyyah, tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ ní Sherwood. Ní ọdún 2000, ó bẹ̀rẹ̀ ìbéèrè Imam Fatawa Portal, ìbéèrè Ìsìlámù lórí ẹ̀rọ ayélujára àti ibi ìpamọ́ ìdáhùn, èyí tí a rò pé ó ti fún un l'ókìkí ní àgbáyé. [8] Gẹ́gẹ́ bí V. Šisler, "Ebrahim Desai ṣe àpẹẹrẹ ọ̀mọ̀wé kan tí ó, bíótilẹ̀jẹ́pẹ́ ó ti kọ́ ẹ̀kó ní ilé-ẹ̀kọ́ tí kìí ṣe Azhari ní ìta àgbáyé Arab, gba ìdánimọ̀ àgbáyé nípasẹ̀ àtìlẹ́yìn púpọ̀ tí a kójọpọ̀ nípasẹ̀ àlàyé àti ìmọ̀-ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀."
Desai ṣiṣẹ́ bí alága FNB Islamic Finance's Shari'ah Board. Ó bẹ̀rẹ̀ Sharī῾ah Complaint Business Campaign ní ọdún 2002 “àpéjọ kan láti kọjú àwọn ọ̀ràn ìṣòwò òde òní ní Ìṣòwò Islam àti ọ̀rọ̀ owó”, ní ìbámu sí ojú òpó wẹ́ẹ̀bù Darul Iftaa Mahmudiyyah. Ó wà lára àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ènìyàn tí wọ́n ṣe àfihàn gẹ́gẹ́ bí Mùsùlùmí tí ó ní ipa jùlọ nípasẹ̀ àkójọpọ̀ ti Royal Islamic Strategic Studies Centre. Namira Nahouza tọ́ka sí i gẹ́gẹ́ bí “South African Grand Mufti ti ọmọ orílẹ̀-èdè India.” Àwọn ọmọ ilé-ìwé rẹ̀ ni Abrar Mirza, Faisal al-Mahmudi àti Husain Kadodia. Farhana nínú ìwádìí rẹ̀ tọ́ka sí pé "Desai fúnra rẹ̀ jẹ́ olùkọ́ ńlá sí àwọn ọmọ ilé-ìwé ti Darul Ifta Mahmudiyyah, ilé-ẹ̀kọ́ ibi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ àti láti ibi tí gbogbo àwọn fatwa ti gbà jáde. Ìwádìí ti ìṣètò ti fatwa lórí askimam.org ní 2011 fi hàn pé nígbà tí àwọn ọmọ ilé-ìwé Desai gbilẹ̀ láti agbègbè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ , wọ́n ṣe àgbéjáde fatwa púpọ̀, àti bí olùkọ́ olùwà ó jẹ́ aláṣẹ tó gbẹ́hìn, gẹ́gẹ́ bí a ti fihàn nípasẹ̀ ìlà ìparí ní ìparí fatwa kọ̀ọ̀kan: 'ṣàyẹ̀wò àti fọwọ́sí nípasẹ̀ Mufti Ebrahim Desai."
Desai kú ní ọjọ́ àrùn-dín-lógún oṣù kéje ọdún 2021, ní Durban. Abdur Rahman ibn Yusuf Mangera, Muhammad ibn Adam Al-Kawthari, Omar Suleiman àti Yasir Nadeem al Wajidi fi ìbànújẹ́ hàn lórí ikú rẹ̀.
Àwọn Iṣẹ́ Lítíréṣọ̀ Rẹ̀
àtúnṣeÀwọn ìlànà ẹ̀sìn Desai ti jẹ́ àtẹ̀jáde gẹ́gẹ́ bí Contemporary Fatawa ní apá mẹ́rin.[5] Àwọn iṣẹ́ rẹ̀ mìíràn ni:
- Al-Mahmood (Collection of his religious edicts)
- Imam Bukhari and his famous Al-Jāmi Al-Sahīh
- Introduction to Hadīth
- Introduction to Islamic Commerce
- Commentary on Qaseedah Burdah
Àwọn Ìtọ́ka Sí
àtúnṣe- ↑ Goran Larsson (2016). Muslims and the New Media: Historical and Contemporary Debates. Routledge. p. 105. ISBN 978-1-317-09103-5. https://books.google.com/books?id=W8QFDAAAQBAJ&q=Ebrahim+desai&pg=PA105.
- ↑ "جنوبی افریقہ کے مشہور مفتی ابراھیم ڈیسائی صاحب کا 15 جولائی کو ڈربن میں انتقال ہوا". Sadaye Haq News. 16 July 2021. https://www.sqnews.in/2021/07/MuftiIbrahimDesayi.html.
- ↑ 3.0 3.1 3.2 Farhana 2015, p. 14, 19.
- ↑ Hadhrat Mufti Mahmood HasanGangohi - His Life And Works. Talimi Board. p. 67. https://archive.org/stream/akabir/HadhratMuftiMahmoodHasanGangohi-HisLifeAndWorksByTalimiBoardKzn#page/n90/mode/1up. Retrieved 16 July 2021.
- ↑ 5.0 5.1 5.2 5.3 "جنوبی افریقہ کے مشہور مفتی ابراھیم ڈیسائی صاحب کا 15 جولائی کو انتقال ہواـ پچھلے کئی روز سے ان کی طبیعت خراب چل رہی تھی." (in ur). Baseerat Online. 16 July 2021. https://www.baseeratonline.com/151024.
- ↑ 6.0 6.1 Mohiuddin, Afshan; Suleman, Mehrunisha; Rasheed, Shoaib; Padela, Aasim I. (2020). "When can Muslims withdraw or withhold life support? A narrative review of Islamic juridical rulings". Global Bioethics 31 (1): 29–46. doi:10.1080/11287462.2020.1736243. PMC 7144300. PMID 32284707. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=7144300.
- ↑ "Talk by Islamic Scholar from South Africa". IKTMC. 26 March 2008. Archived from the original on 25 June 2011. https://web.archive.org/web/20110625162750/http://www.iktmc.edu.hk/events/20080326a.htm.
- ↑ Farhana 2015, p. 51.