Ecobank Nigeria Limited, tí gbogbo ènìyàn mọ̀ dáadáa sí Ecobank Nigeria, jẹ́ báǹkì gbogbogbò ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn báǹkì tó gbàwé àṣẹ lọ́wọ́ báǹkì gbogbo gbò Nàìjíríà, báǹkì apàṣẹ fún orílẹ̀-èdè.[2]

Ecobank Nigeria
TypePublic Company
NSE: EBN
Founded1989[1]
HeadquartersLagos, Lagos State, Nigeria
Key peopleJohn Aboh
Chairman (Nigerian)
Carol Oyedeji
Managing Director (Nigerian)
IndustryFinancial services
ProductsLoans, savings, investments, debit and credit cards, mortgages
Total assetsUS$8.1 billion (NGN:1.32 trillion) (2011)
Websiteecobank.com/ng/

Ìsọníṣókí

àtúnṣe

Báǹkì náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ọdún 1989. Ó ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi báǹkì àgbáyé, nípa pípèsè ìdúnàádúrà lọ́lọ́kan-ò-jọ̀kan fún àwọn tí bá wọn ná ní ọjà Nàìjíríà. Báǹkì náà pín iṣẹ́ rẹ̀ sí ipele mẹ́ta: (a) Báǹkì oníṣòwò kéékèèké, (b) Báǹkì ìṣọ̀wọ́ ńláǹlà àti (c) Ilé ìṣura àti ètò ìṣúná. Báǹkì yìí máa ń pèsè àyè owó yíyá àti ètò ìdókòwò.[3] Nígbà ìpín kẹ́rin ọdún 2011, ilé-iṣẹ́ Ecobank Nigeria nípasẹ̀ ilé-iṣẹ́ àgbà rẹ̀, Ecobank Transnational Inc (ETI) gba ìdá ọgọ́rùn-ún owó ìbábádòwò ní Oceanic Bank, dídá Ecobank Nigeria Limited tí ó fẹjú sílẹ̀.[4] Nìpa fífẹjú Ecobank Nigeria, ó darí ohun ìní tí ó tó US$8.1 billion (NGN:1.32 trillion),èyí tí ó sọ ọ́ di ọ̀kan lára báǹkì ńlá márùn-ún Nàìjíríà nígbà náà.[5] Nígbà náà,báǹkì yìí ní ẹ̀ka ìṣiṣẹ́ tó dá dúró mẹ́wàá lé ní ẹgbẹ̀ta, tí ó sọ ọ́ di báǹkì ńlá kejì ní orílẹ̀èdè nípa níní ẹ̀ka ìṣiṣẹ́ tó pọ̀jù.

Ohun tí Ecobank lọ́wọ́ sí

àtúnṣe

Ecobank Nigeria jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ecobank, báǹkì Olómìnira ti àkójọpọ̀ ọmọ Áfíríkà,tí olú ilé-iṣẹ́ rẹ̀ wà ní Lomé, Togo, pẹ̀lú àwọn alábáṣiṣẹ́pọ̀ ní ìwọ̀-oòrùn, ọ̀gangan àti ìlà-oòrùn Áfíríkà. Ecobank, tí a dá sílẹ̀ ní ọdún 1985, ti ní ẹ̀ka tó lé ní ẹgbẹ̀rún, gbígba ènìyàn tó lé ní ẹgbààrún pẹ̀lú ọ́fíìsì ní orílẹ̀-èdè méjìlélọ́gbọ̀n bíi Benin, Burkina Faso, Burundi, Cameroon, Cape Verde, the Central African Republic, Chad, the Republic of Congo, the Democratic Republic of Congo, Côte d'Ivoire, Gambia, Ghana, Guinea, Guinea Bissau, Kenya, Liberia, Mali, Malawi, Niger, Nigeria, Rwanda, Sao Tome, Senegal, Sierra Leone, Togo, Uganda, Zambia àti Zimbabwe.[6] Ecobank tún ń ṣe alámòjútó ẹ̀ka ìfowópamọ́ ní Paris àti ọ́fíìsì aṣojú ní Johannesburg, Dubai àti London.[7]

Ilé-iṣẹ́ àgbà

àtúnṣe

Ecobank Transnational Inc. (ETI) ni ilé-iṣẹ́ àgbà fún àwọn Ecobank Group, lára àwọn ilé-iṣẹ́ tí Wọ́n ń darí ni:[8]

  • Ecobank Development Corporation (EDC) – Lomé, Togo
  • EDC Investment Corporation – Abidjan, Ivory Coast
  • EDC Investment Corporation – Douala, Cameroon
  • EDC Securities Limited – Lagos, Nigeria
  • EDC Stockbrokers Limited – Accra, Ghana
  • Ecobank Asset Management – Abidjan, Ivory Coast
  • e-Process International SA – Lomé, Togo
  • ECV Servicios – Praia, Cape Verde

ETI máa ń ta ìṣura wọn ní ibi mẹ́ta tí wón ti ń ṣe pàṣípààrọ̀ ìṣúra ní Áfíríkà tí bíi: the Ghana Stock Exchange (GSE), the Nigerian Stock Exchange (NSE) àti the BRVM stock exchange ní Abidjan, Ivory Coast.[9]

Ẹ̀ka ìṣiṣẹ́

àtúnṣe

Ní oṣù Kejìlá, ọdún 2011, Ecobank Nigeria Limited tí a fẹ̀ lójú ni a rí pé ó ní ẹ̀ka ilé-iṣẹ́ tó tọ́ ẹgbẹ̀ta,ní gbogbo àgbègbè Federal Republic of Nigeria, títẹ̀lé àgbékalẹ́ Oceanic Bank.[10]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Ecobank Nigeria Founded In 1989". BusinessWeek. Archived from the original on 12 July 2012. Retrieved 30 December 2011.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. "List of Licensed Commercial Banks in Nigeria". Cbn.gov.ng. 7 January 1959. Retrieved 30 December 2011. 
  3. "Overview of Ecobank Nigeeria Plc". BusinessWeek. Archived from the original on 12 July 2012. Retrieved 30 December 2011.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. "Ecobank Nigeria Acquires Oceanic Bank". Allafrica.com. 24 December 2011. Retrieved 30 December 2011. 
  5. "Ecobank Nigeria's Total Assets Over NGN:1.32 Trillion". Allafrica.com. 27 December 2011. Retrieved 30 December 2011. 
  6. "The Ecobank Network". Ecobank.com. Retrieved 18 June 2012. 
  7. "Ecobank Has Banking Presence in Africa, Europe & The Middle East". Businessdailyafrica.com. 18 June 2012. Retrieved 18 June 2012. 
  8. Ecobank Subsidiaries [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]Àdàkọ:Cbignore
  9. "Ecobank Shareholding & Investment Matters". Ecobank.com. Archived from the original on 18 April 2009. Retrieved 30 December 2011.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  10. "Ecobank Nigeria With Over 600 Branches". Allafrica.com. 2 January 2011. Retrieved 30 December 2011.