Eddie Nartey
Eddie Nartey (tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹfà oṣù kọkànlá ọdún 1984) jẹ́ òṣèrẹ́kùnrin, olùdarí àti aṣàgbéjáde fíìmù ní orílẹ̀-èdè Ghana.[1] Ó kópa nínú fíìmù Frank Rajah, tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Somewhere In Africa,[2] èyí tí wọ́n yàn fún àmì-ẹ̀yẹ ní Nollywood and African Film Critics Awards,[3] àti Ghana movie awards. Wọ́n yàn án fún òṣèrékùnrin tó dára jù fún ìkópa rẹ̀ nínú fíìmù Kiss Me If You Can.[4] Ó ní àǹfààní láti jẹ́ olùdarí eré fún fíìmù Could This Be Love[5] èyí tí ó ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú Evelyn, tí wọ́n sì ní àwọn akópa bí i Majid Michel, Kwadwo Nkansah (Lil Win), Nana Ama Mcbrown, Fred Amugi, àti Gloria Sarfo.
Eddie Nartey | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 6 Oṣù Kọkànlá 1984 Korle Gonno, Accra, Ghana |
Iléẹ̀kọ́ gíga | University of Ghana |
Iṣẹ́ | Actor, Director, Producer |
Ìgbà iṣẹ́ | 2004—present |
Notable work |
|
Awards |
|
Ó ṣe iṣẹ́ pẹ̀lú Juliet Ibrahim lórí fíìmù Shattered Romance. Bákan náà, ó ṣe àkọsílẹ̀ fíìmù Royal Diadem, tí ó sì tún jẹ́ olùdarí fíìmù náà.
Ó tan mọ́ òṣèrékùnrin ilẹ̀ Britain kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Danny Erskine.
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀
àtúnṣeEddie lọ sí ilé-ìwé Korle Gonno Methodist, ó sì kẹ́kọ̀ọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti èyí tó tẹ̀le ní ìlú Accra. Ó gba ẹ̀kọ́ girama rẹ̀ ní Holy Trinity Cathedral Secondary School (HOTCASS). Ó lọ sí University of Ghana, Legon[6] níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ẹ̀kọ́ Fine Arts.
Ìgbésí ayé ara ẹni
àtúnṣeÌyàwó rẹ̀ kú ní oṣù kìíní ọdún 2021, lẹ́yìn ìgbéyàwò ọdún méjì.[7]
Àtòjọ àwọn fíìmù rẹ̀
àtúnṣeÓ ti kópa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ fíìmù, lára wọn ni:[8]
- Wedlock of the Gods
- In The Eyes Of My Husband
- Gallery of Comedy
- Last Battle
- Love & Crime
- Intimate Battle 1&2
- Believe Me
- The King Is Mine 1&2
- Return Of Beyonce (2006) - President's Bodyguard
- Crime To Christ (2007) - Milado
- Passion of the Soul (2008)
- Girls Connection (2008) - Casmir
- Agony of Christ (2008)
- Tears Of Womanhood 1&2 (2009) - David
- Ties That Bind (2011) - Godknows
- Somewhere In Africa 1&2 (2011) - Pascal
- Pool Party 1&2 (2011)
- The Silent Writer (2011)
- Testing The Waters (2012)
- Number One Fan (2013) - Kweku Mensah
- Shattered Romance (2014) - Cobra
- Chronicles of Odumkrom: The Headmaster (2015) - Kofi Bediako
- In April (2016) - Bright Ofori
- The New Adabraka (2018)
- The Don (2022) - Mike
Àwọn fíìmù tí ó ti darí, tí ó sì ti ṣàgbéjáde rẹ̀ ni;
àtúnṣe* ''Could This Be Love (2014)''
* ''Shattered Romance (2014)''
* ''Royal Diadem (2015)''
* ''She Prayed (2015)''
*Beautiful Ruins (2016)
*In April (2016)
*Samai
*Criss Cross
*The Corner TV Series
*Conversation
*The New Adabraka (2018)
*Frema
*Woman At War (2021)
*Kofi Abebrese (2021)
*Okada (2021)
*That Night (2022)
Àwọn àmì-ẹ̀yẹ rẹ̀
àtúnṣeYear | Award | Category | Result |
---|---|---|---|
2010 | Ghana Movie Awards | Best Actor | Yàán |
2011 | Ghana Movie Awards | Best Actor | Nominated |
2016 | Golden Movie Awards | Best Screenplay | Won |
2017 | Nelas Awards | Best TV Series | Nominated |
2018 | Ghana Movie Awards | Best Screenplay | Won |
2018 | Ghana Movie Awards | Best Director | Nominated |
2018 | Ghana Movie Awards | Best Picture | Nominated |
2018 | Nelas Awards | Best Short Film | Won |
2018 | Nelas Awards | Best Producer | Won |
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ filla, ghana. "Eddie directs Juliet Ibrahim's first movie". ghanafilla. Archived from the original on 15 July 2014. Retrieved 12 July 2014. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Movie, Somewhere in Africa". Chris-Vincent A. Febiri. Archived from the original on 27 April 2011. Retrieved 24 April 2011. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Eddie for awards". Retrieved 15 August 2011.
- ↑ "Kiss Me If You Can". TalkAfricanMovies. Retrieved 20 July 2013.
- ↑ "If Kumawood Was That BAD, How Come The Top English Movie Stars Are Rushing In There? Watch A Clip of Majid Michel and Lil Win In The Movie-Could This be Love?". Archived from the original on 2013-10-27. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Eddie graduates from school". Joseph Midnight. Archived from the original on 19 August 2014. https://web.archive.org/web/20140819090347/http://www.ghanashowbiz.com/film/eddie-nartey-and-naa-ashorkor-now-graduates/.
- ↑ "Eddie Nartey's wife passes on 2 years after marriage - MyJoyOnline.com". www.myjoyonline.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-01-30.
- ↑ "Eddie's movies".