Ekuru
'Ekuru jẹ́ oúnjẹ tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn ẹ̀yà Yorùbá ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Erèé ti wọ́n bó èpo ara ẹ̀ ni wọ́n máa ń lò fi ṣe èkuru.[1]
Ó farapẹ́ moin-moin nítorí pé erèé tí wọ́n bó ní wọ́n fi ń ṣe àwọn méjèèjì. Ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn méjèèjì ni pé moi-moi máa ni àwọn èròjà mìíràn bí i ata, epo, ẹja, edé, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ nínú kí wọ́n tó sè é, wọ́n kàn máa wé ekuru sínú ewé lásán ni tàbí kí wọ́n rọ ọ́ sínú agolo (gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣẹ́ ń ṣe moi-moi) kí wọ́n tó sè é.[2]
Bí wọ́n ṣé ń ṣe moi-moi náà ni wọ́n ṣe ṣe èkuru ṣùgbọ́n wọ́n kì í fi èròjà sí èkuru bí wọ́n ṣe ń fisí moi-moi. Àwọ̀ funfun ni èkuru máa ni, adùn rẹ̀ sì dàbí ọbẹ̀ díndín. Ó máa ń lọ dáadáa pẹlu ẹ̀kọ́.[3]
Èkuru máa dùn ún jẹ pẹ̀lú ọbẹ̀ díndín. Àwọn mìíràn máa gbádùn rẹ̀ pẹ̀lú ẹkọ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn kan máa ń jẹ́ pẹ̀lú ẹbá tàbí ọbẹ̀ ilá.
Oúnjẹ yìí wọ́pọ̀ láàárín àwọn ará ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.[2]
Àwọn èròjà
àtúnṣeÀwọn èròjà tí a tòjọ sí ìsàlẹ̀ yìí ni wón ń lò láti pèsè Èkuru tó dáa.[4]
- Erèé
- Òróró
Fún ata díndín
àtúnṣe- Tàmátì
- Àlùbósàá
- Maají
- Ìsebẹ̀ abbl.
- [5]
Àwọn ìtọ́kásí
àtúnṣe- ↑ Balogh, Esther (1992). "Eating Out in Nigeria - From Food Vendors to the Sheriton". In Walker, Harlan (in en). Oxford Symposium on Food and Cookery 1991: Public Eating : Proceedings. London: Oxford Symposium. pp. 32. ISBN 978-0-907325-47-5. https://books.google.com/books?id=FrWgDRkS90EC&q=Ekuru+steamed&pg=PA32.
- ↑ 2.0 2.1 Ajala, Aderemi Suleiman (2009) (in en). Rural Health Provisioning: Socio-cultural Factors Influencing Maternal and Child Health Care in Osun State, Nigeria. Frankfurt am Main, Germany: Peter Lang. pp. 42. ISBN 978-3-631-59023-2. https://books.google.com/books?id=U6SUbBKCrqQC&q=Ekuru+Osun&pg=PA42.
- ↑ Online, Tribune (2019-08-25). "Ekuru with peppered sauce". Tribune Online (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-10-11.
- ↑ Online, Tribune (2019-08-25). "Ekuru with peppered sauce". Tribune Online (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-10-11.
- ↑ NollywoodTmies. "Recipe of the day: How to prepare Ekuru (white moin moin)". Simply News and Entertainment Reports - Nollywood Times (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-10-11.
External links
àtúnṣe- Yuntunmian. Nigerianfoodtv.com.