Moin moin
Mọ́ín-mọ́ín, ọ̀lẹ̀lẹ̀ tàbí ọ̀ọ̀lẹ̀ jẹ́ ẹ̀wà tí a bo èpo rẹ̀, tí a lọ̀, tí a sì fi àwọn èròjà bíi ata, epo, iyọ̀ edé, iyọ̀ àti àwọn èròjà míràn sí ṣáájú kí wọ́n tó sè é lórí iná. Lọ́pọ̀ ìgbà wọ́n ma ń fi àlùbọ́sà, atalẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ kun kí ó lè dùn un jẹ. [1]Móí-mọ́í jẹ́ óunjẹ ìbílẹ̀ Yorùbá tí wọ́n wà ní apá ìwọ̀ ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà. Òúnjẹ yí jẹ́ ìkan pàtàkì lára àwọn óúnjẹ aṣaralóore .[2][3]
Alternative names | Moyi-Moyi, Mai-Mai, Olele |
---|---|
Type | Pudding |
Place of origin | (Nigeria, Benin and Togo) |
Region or state | Western Africa |
Created by | Yorùbá |
Main ingredients | Black-eyed beans or honey beans, onions, fresh ground peppers,oil |
Àdàkọ:Wikibooks-inline
|
Yàtọ̀ sí mọ́í-mọ́í tí wọ́n ń pèé ní ilẹ̀ Yorùbá, wọ́n tún ń pèé ní alele, tàbí ọ̀lẹ̀lẹ̀ ní apá orílẹ̀-èdè Sierra Leone ati Ghana . Wọ́n tún ma ń jẹ mọ́ímọ́í pẹ̀lú ẹ̀kọ, kòkó lọ́dọ̀ àwọn Hausa tàbí ògì. [4] Tubaani (also spelled tubani) is a similar dish found in Northern Ghana.[5] Wọ́n lè fi mọ́ímọ́í mu gàrí pẹ̀lú, wọ́n sì tún ma ń fi gbádùn ounje bíi ìrẹsì jọ̀lọ́ọ̀fù, ìrẹsì ọ̀fadà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Àwọn èròjà mọ́ímọ́í
àtúnṣeWọ́n lè lo ẹ̀wà pupa, ẹ̀wà sèsé, tàbí ẹ̀wà funfun tí wọ́n ń pe ní erèé, wọ́n ma ń fi ata, epo, òróró, edé, àlùbọ́sà, ẹyin, ẹja yíyan, iyọ̀, magí tàbí ẹran tí wọ́n ti bọ̀ si kí ó lè ládùn tó dára.
Bí a ṣe ń pèsè mọ́ímọ́í
àtúnṣeWọ́n ma ń pèsè mọ́ímọ́í pẹ̀lú kí wọ́n kọ́kọ́ rẹ ẹ̀wà èyíkéyí tí wọ́n fẹ́ lò sínú omi tútù títí yóò fi rọ̀, lẹ́yìn náà wọn yóò bo èpo ara ẹ̀wà náà kúrò.[6]Lẹ́yìn èyí ni wọn yóò lọ̀ọ́ kúná, wọn yóò wá fi àwọn èròjà tí a ti mẹ́nu bá ṣáájú. Àwọn míràn ma ń fi ẹyin, ẹran bíbọ, edé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ kun kí ó lè dùn yùngbà yùngbà. [7] Irúfẹ́ mọ́ímọ́í tí wọ́n bá pèsè pẹ̀lú àwọn èròjà tí a ti ka sílẹ̀ yí ni a lè pe ní mọ́ímọ́í ẹlẹ́mí méje. [8]
Wọ́n ma ń ṣu mọ́ímọ́í rogodo, tàbí kí wọ́n ṣù ú pẹrẹsẹ, ó da lórí ohun tí wọ́n bá fi ṣù ú. [9] Bí wọ́n bá ti fi sínú ohun tí wọ́n fẹ́ fi ṣù ú tán, wọn yóò sì gbe sí orí iná. Tí wọ́n bá fi ewé éran tàbí ewé ẹ̀bà [10] tàbí ewé ọ̀gẹ̀dẹ̀ ṣu mọ́ímọ́í ni yóò jẹ́ kí ó rí rogodo. [11] omi tó pọ̀ ni wọ́n fi ma ń se mọ́ímọ́í.
-
Sliced moin moin
-
"Ewe eran" leaves (Thaumatococcus daniellii)
-
Moin moin seller in Nigeria
Ẹ tún lè wo
àtúnṣeÀwọn itọ́ka sí
àtúnṣe- ↑ "The thriving 'Moi-moi' business in Nigeria". 22 March 2022.
- ↑ "Nigerian Moi Moi". All Nigerian Recipes (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-07-23.
- ↑ "Nigeria", The World Factbook (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì), Central Intelligence Agency, 2022-08-23, retrieved 2022-08-28
- ↑ "NEWS". miczd.gov.gh. Archived from the original on 2020-06-06. Retrieved 2020-06-07.
- ↑ Osseo-Asare, Fran; Baeta, Barbara (2015). The Ghana Cookbook. New York: Hippocrene Books. ISBN 978-0-7818-1343-3. OCLC 896840053.
- ↑ "Best Moi-moi recipe". 11 November 2020.
- ↑ "Moin-Moin". 13 April 2010.
- ↑ "Moin-Moin". 13 April 2010.
- ↑ "The Nigerian Moi-Moi". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2017-07-21. Archived from the original on 2022-07-23. Retrieved 2022-07-23.
- ↑ Iwalaiye, Temi (2021-12-17). "What should you use to wrap moi-moi?". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-07-23.
- ↑ "Moi Moi Wrapped In Banana leaves Recipe by UmmiAbdull". Cookpad (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-07-23.