Elizabeth Balogun (Ti a bi ni ọjọ Kẹsán oṣu Kẹsán odun 2000) jẹ agbabọọlu inu agbọn orilẹede Naijiria. Oun gba bọọlu inu agbọn kọlẹji fun Ẹgbẹ obinrin Kadinali Louisville ati ẹgbẹ orilẹ-ede Naijiria .

Ile-iwe giga

àtúnṣe

Balogun gbe si Hamilton Heights High School Tennessee ni ipele kẹjọ rẹ lati ilu Lagos, Nigeria . O ṣe iwọn ami ayo 15.1, atungba 4.6, bulọọki 2.7 ati iranlọwọ 2.1. O wo Ẹgbẹ Agbaọọlu inu agbon to ọbinrin ALL-USA ni ipari iduro re ni Ile-iwe giga.

Iṣẹ ile-ẹkọ giga

àtúnṣe

Balogun bẹrẹ gẹgẹ bi eni tuntun ni Georgia Tech ni ọdun 2018, O fi ẹgbẹ naa silẹ fun Louisville Cardinals lẹyin ti won ti fun Ami eye ni 2018-19 ACC nibiti o gba ami ayo 14.64 ninu ifẹsẹwọnsẹ rẹ kan'kan. Ni ọdun keji rẹ ni Louisville, wọn fi je preseason All-ACC nipasẹ awọn olukọni ati Igbimọ Ribbon Blue ati pe won tun fi orukọ rẹ sinu Akojọ Atọka Ara Naismith. [1]

Won pe Balogun lati soju D'Tigress ati lati kopa ninu idije igbaradi Olimpiiki ọdun 2019 ni Mozambique sugbon Louisville ko fi sile lati kopa ninu ìdíje naa. Won tun pe lati kopa ninu igbaradi Olimpiiki Tokyo 2020 ni Belgrade.

Igbesi aye rẹ

àtúnṣe

Balogun jẹ ọmọ keji ninu awọn ọmọ mẹta, ẹgbọn rẹ, Esekieli, ngba fun The Citadel ni South Carolina. Arabinrin rẹ aburo, Ruth, ngba funi Hamilton Heights. Iya rẹ Justina ti jẹ oloogbe, sibe ti Baba rẹ Mark gbe ni Nigeria nibiti o jẹ olukọni bọọlu inu agbọn ati ọlọpa.

Awọn itọkasi

àtúnṣe
  1. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named auto1