Esther Igbekele
Esther Igbekele jẹ́ gbajúmọ̀ olórin ẹ̀sìn ọmọ-lẹ́yìn-Jésù Ọmọ bíbí ìlú Ifọ́n, ìjọba ìbílẹ̀ Ọsẹ́ ní Ìpínlẹ̀ Òndó lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. [1] Ó jẹ́ ọmọ bíbí òjíṣẹ́ Ọlọ́run, Olúwafẹ́mi Ìgbẹ́kẹ̀lé, ṣùgbọ́n tí ó gbé lọ́dọ̀ òjíṣẹ́ Ọlọ́run mìíràn tí orúkọ wọn ń jẹ́ Àpọ́sítélì J. A. Bánkọ́lé.[2] Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ orin kíkọ lọ́dún 1996,[3] bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé láti ọmọ ọdún mẹ́rin ni ó ti nífẹ̀ẹ́ sí orin kíkọ. Ó tí gba àmìn-ẹ̀yẹ nínú iṣẹ́ orin yìí.
Ìgbésí ayé àti ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀
àtúnṣeWọ́n bí Esther sí Orílé-Ìgànmú ní Ìpínlẹ̀ Èkó, sí ìdílé Olùṣọ́ Àgùntàn, Olúwafẹ́mi Ìgbẹ́kẹ̀lé àti aya rẹ̀ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó bẹ̀rẹ̀ orin kíkọ nípa dídara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ akọrin ilé-ìjọsìn wọn nígbà tí ó wà ní ọmọdún mẹ́fà. Ọdún 1996 gan-an ní ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ orin ní àkọ̀tun. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwo orin sìn ní ó ti gbé jáde.
Esther bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ kíkà ní ilé-ìwé Central Primary school, ní Orílé-Ìgànmú ní Ìpínlẹ̀ Èkó. Bákan náà, ó tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Lagos African Church Grammar School, ní Ìfàkọ̀-Ìjàyè ní Ìpínlẹ̀ Èkó bákan náà. [4]
Àtòjọ àwọn àṣàyàn orin rẹ̀
àtúnṣe- We Give You Praise
- Praise Medley
- There Is Sense in Nonsense
- MO jí í re lónìí
- Àpáta Ayérayé
- Olorun Ayérayé
- Agbára Mi Kọ́
- Mo Mọ̀ Pé ẹ tún Lè Ṣe é
- Èdìdí. [5]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Minister Esther Igbekele Biography, Life History". GM Lyrics. 2019-12-13. Archived from the original on 2020-11-26. Retrieved 2020-11-06.
- ↑ Punch Newspaper, 18 August, 2018 People love secular music because gospel is bitter — Esther Igbekele
- ↑ "I Joined Senior Choir At Seven —Musician Igbekele". P.M. News. 2014-06-27. Retrieved 2020-11-06.
- ↑ "Gospel Singer Esther Igbekele Biography: Marriage, Husband, State Of Origin, Life History". NaijaGists.com. 2019-01-10. Retrieved 2020-11-06.
- ↑ "List Of Songs By Esther Igbekele". Believers Portal. 2016-10-12. Retrieved 2020-11-06.