Esther Oluremi Obasanjo
Esther Oluremi Obasanjo tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Màmá Ìyábọ̀ ni ó ti fìgbà kan jẹ́ obìnrin àkọ́kọ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Òun ni ó jẹ́ ìyàwó tẹ́lẹ̀ rí fún Olusegun Obasanjo tí ó jẹ́ ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1]
Esther Oluremi Obasanjo | |
---|---|
First Lady of Nigeria | |
In role 13 February 1976 – 1 October 1979 | |
Head of State | Olusegun Obasanjo |
Asíwájú | Ajoke Muhammed |
Arọ́pò | Hadiza Shagari |
Second Lady of Nigeria | |
In role 29 July 1975 – 13 February 1976 | |
Chief of Staff | Olusegun Obasanjo |
First Lady | Ajoke Muhammed |
Asíwájú | Anne Wey |
Arọ́pò | Hajia Binta Yar'Adua |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | Oluremi Akinlawon 1941 (ọmọ ọdún 82–83) |
Ọmọorílẹ̀-èdè | Nigerian |
(Àwọn) olólùfẹ́ | Olusegun Obasanjo (m. 1963; div. 1976) |
Àwọn ọmọ | 5; including Iyabo Obasanjo |
Ìgbésí ayé
àtúnṣeOlúrẹ̀mí Akínlàwọ́n jẹ́ ọmọ Mrs. Alice Akinlawon (nee Ogunlaja).[2] Ó pàdé Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ ní inú ilé-ìjọsìn Owu Baptist Church ní déédé ọmọ ọdún mẹ́rìndìnlógún.[3] Wọ́n ṣe ìgbeyàwó ní ọjọ́ kejìlélógún oṣù kẹfà ọdún 1963 ní Camberwell Green Registry, SE London nígbà tí ó di ọmọ ọdún mọ́kànlélógún láì jẹ́ kí àwọn òbí tàbí ẹbí wọn ó mọ̀ nípa rẹ̀.[1][4] Olúrẹ̀mí kẹ́kọ̀ọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ institutional management ní ìlú London.[4] O di obìnrin àkọ́kọ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lẹ́yìn ìdìtẹ̀gbàjọba tí ó sì fa iku Ààrẹ ìgbà náà, ọ̀gágun Murtala Mahammed tí ó sì gbé ọkọ rẹ̀ Oluṣẹgun Ọbasnajọ dé ipò Ààrẹ [1] [4]
Iṣẹ rẹ
àtúnṣeNí ọdún 2008, Ọbasanjọ ṣe àtẹ́jadè ìwé ìtàn -akọọlẹ igbesi aye kan tí àkọlé rẹ jẹ Bitter-Sweet: Ìgbésí ayé Mi pẹ̀lú Ọbasanjọ nínú èyí tí o ṣe àpèjúwe àwọn ìrírí ìgbésí ayé rẹ pẹ̀lú Olusegun Obasanjo tí n ṣàpèjúwe rẹ bi obìnrin oníwà-ipá. Ó ṣe àpèjúwe ara rẹ jẹ “yangan ni ọna arekereke” ó má múra ní àwọn aṣọ ìbílè.
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 1.2 Okon-Ekong, Nseobong (2010-10-02). "Nigeria: First Ladies - Colourful Brilliance, Gaudy Rays". Thisday (AllAfrica.com). http://allafrica.com/stories/201010040212.html.
- ↑ Adebayo, Adeolu (2017-10-22) (in en). Olusegun Obasanjo: Nigeria's Most successful ruler. Safari Books Ltd. ISBN 978-978-54785-2-5. https://books.google.com/books?id=hVdDDwAAQBAJ&q=Oluremi.
- ↑ Howden, Daniel (2009-01-10). "Revealed: The Secrets of an African first lady". The Independent (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-08-06.
- ↑ 4.0 4.1 4.2 Iliffe, John (2011) (in en). Obasanjo, Nigeria and the World. Boydell & Brewer Ltd. ISBN 978-1-84701-027-8. https://books.google.com/books?id=zbBhLw-Hh28C&dq=Oluremi&pg=PR9.
Àdàkọ:S-honÀdàkọ:S-end
Preceded by Ajoke Muhammed |
First Lady of Nigeria 1976 – 29 July 1979 |
Succeeded by Hadiza Shagari |