Fúnkẹ́ Bucknor-Obruthe

Funke Bucknor-Obruthe tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹfà ọdún 1976 (27 June 1976)[1] jẹ́ gbajúmọ̀ oníṣòwò àti amọ̀fin ọmọ bíbí Ìpínlẹ̀ Èkó lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Òun ni Aláṣẹ àti olùdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ Zapphaire Events, ó jẹ́ ọ̀kan lára gbajúmọ̀ ìlúmọ̀ọ́ká tí wọ́n kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ abánìṣètò ètò lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà.[2][3]

Funke Bucknor-Obruthe
Fúnkẹ́ Bucknor-Obruthe
Ọjọ́ìbíFúnkẹ́ Bucknor
27 Oṣù Kẹfà 1976 (1976-06-27) (ọmọ ọdún 48)
Ìpínlẹ̀ Èkó, Nigeria
Orílẹ̀-èdèỌmọ Nàìjíríà
Iléẹ̀kọ́ gíga
Iṣẹ́
Ìgbà iṣẹ́2003 – present
TitleAláṣẹ àti olùdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ Zapphaire Events
Olólùfẹ́Onome Obruthe
Àwọn ọmọ2

Ìgbésí ayé àti ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ni ìbẹ̀rẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n bí Fúnkẹ́ sí ìdílé Segun Bucknor àti Shola Bucknor ní Ìpínlẹ̀ Èkó, lápá iwọ̀-oòrùn Nàìjíríà.[4] Ó kàwé ní ìbéèrè ayé rẹ̀ ní Fountain Nursery and Primary School, àti Nigeria Navy Secondary School, gbogbo rẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Èkó kí ó tó tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní University of Lagos, níbi tí ó ti kàwé gboyè nínú ìmọ̀ òfin (Law) .[5] Lọ́dún 2000, ó pegedé, wọ́n sìn pè é sí Nigerian Law SchoolAbuja.[6]

Iṣẹ́

àtúnṣe

Lẹ́yìn tit Fúnkẹ́ ṣiṣẹ́ amọ̀fin fún ìgbà díẹ̀, ilé-iṣẹ́ agbódegbà ìpolówó-ọjà, Tie Communications gbà á, ó sìn ṣiṣẹ́ níbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. Nígbà tí ó di ọdún 2003,ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ abánìṣètò ètò, ó sìn dá ilé-iṣẹ́ Zapphaire Events sílẹ̀.[6] Láti ìgbà náà, ó bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn àti ilé-iṣẹ́ ṣètò àwọn ètò ayẹyẹ wọn ní Nàìjíríà àti lókè òkun. Lori iṣẹ́ yìí, ó ti gba àìmọye àmìn-ẹ̀yẹ, débi pé ilé-iṣẹ́ oníròyìn òkè òkun, CNN ṣe àfihàn rẹ̀ nínú ètò wọn kan tí wọ́n pè ní Inside Africa .[6][7] Lára àwọn àmìn-ẹ̀yẹ tí ó ti gbà ní "Oníṣòwò tó pegedé jùlo lọ́dún 2006" àmìn-ẹ̀yẹ fún abánìṣètò ètò tó dára jù lọ lọ́dún 2007.[8]

Àwọn ìwé rẹ̀

àtúnṣe
  • The Essential Bridal Handbook[9]

Àwọn gbajúmọ̀ rẹ̀

àtúnṣe

Lọ́dún 2014, ìkànnì oníròyìn ayélujára Nàìjíríà kan, YNaija dárúkọ rẹ̀ mọ́ àwọn gbajúmọ̀ oníṣòwò ọmọ Nàìjíríà mẹ́wàá tí ọjọ́ orí wọn kò ju ogójì lọ.[10] Bẹ́ẹ̀ náà lọ́dún 2016, BBC dárúkọ rẹ mọ́ ọgọ́rùn-ún gbajúmọ̀ obìnrin tí wọ́n mọ̀ ní àgbáyé.[11]

Ìgbésí ayé ara rẹ̀

àtúnṣe

Fúnkẹ́ Bucknor-Obruthe fẹ́ Onome Obruthe, wọ́n sìn bímọ méjì fún ara wọn. Òun ni ẹ̀gbọ́n fún gbajúmọ̀ agbóhùnsáfẹ́fẹ́, Tosyn Bucknor.[12][13]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Yemisi Sophie Odusanya (27 June 2016). "Funke Bucknor-Obruthe Is STUNNING At 40!". Cosmopolitan. http://www.cosmopolitan.com/ng/celebrity/g952062/untitled-content-1467065329/. Retrieved 1 December 2016. 
  2. Wole Adepoju (3 July 2016). "Funke Bucknor Obruthe counts her blessings at 40". New Telegraph. Archived from the original on 1 December 2016. https://web.archive.org/web/20161201215228/https://newtelegraphonline.com/funke-bucknor-obruthe-counts-blessings-40/. Retrieved 1 December 2016. 
  3. Declan Eytan (26 December 2014). "How Nigeria's Elite Spend Over $2 Million on Their Dream Weddings". Forbes. https://www.forbes.com/sites/declaneytan/2014/12/26/how-nigerias-rich-spend-over-2-million-on-their-dream-wedding/#2c151fe57f0c. Retrieved 1 December 2016. 
  4. "Funke Bucknor-Obruthe". businessinnigeria. 5 June 2015. Archived from the original on 1 December 2016. Retrieved 1 December 2016.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  5. "I don’t regret not having a brother —Funke Bucknor-Obruthe". The Punch News. uncova.com. 9 August 2015. Retrieved 1 December 2016. 
  6. 6.0 6.1 6.2 Folake Soetan (2 December 2012). "Master Event Planner, Funke Bucknor-Obruthe And Her Passion For Planning". Ventures Africa. Retrieved 1 December 2016. 
  7. "Touring Zapphaire Events with Funke Bucknor-Obruthe". afrikangoddessmag.com. 18 March 2013. Archived from the original on 1 December 2016. Retrieved 1 December 2016. 
  8. "Funke Bucknor-Obruthe". Business in Nigeria. Archived from the original on 2016-12-01. https://web.archive.org/web/20161201222944/http://businessinnigeria.com.ng/funke-bucknor-obruthe/. 
  9. Bucknor-Obruthe, Funke, ed (10 June 2015) (in English). The Essential Bridal Handbook (1 ed.). Funke Bucknor - Obruthe. https://www.amazon.co.uk/Essential-Bridal-Handbook-Funke-Bucknor-Obruthe-ebook/dp/B00ZEDGI5E. 
  10. Wilfred Okiche (31 March 2014). "Tara Fela-Durotoye, Tayo Oviosu, Funke Bucknor & more! We present the 10 most powerful Under-40s in Business – #YNaijaPowerList". YNaija. Retrieved 1 December 2016. 
  11. Ayoola Adetayo (22 November 2016). "Funke Bucknor-Obruthe Top wedding planner makes BBC 100 women list 2016". Pulse Nigeria. Archived from the original on 2 December 2016. https://web.archive.org/web/20161202035403/http://pulse.ng/weddings/bbc-100-women-2016-funke-bucknor-obruthe-makes-the-list-id5794797.html. Retrieved 1 December 2016. 
  12. Osagie Alonge (8 July 2014). "Event planner Funke Bucknor sets up decor company". Nigerian Entertainment Today. http://thenet.ng/2014/07/event-planner-funke-bucknor-sets-up-decor-company/. Retrieved 1 December 2016. 
  13. Sean (30 June 2016). "Funke Bucknor-Obruthe celebrates her Husband on his birthday today Says: ‘My Hubby of life, friend, partner & gbogbo e sha’". Daily Mail (Nigeria). Archived from the original on 1 December 2016. https://web.archive.org/web/20161201211111/http://dailymail.com.ng/funke-bucknor-obruthe-celebrates-husband-birthday-today-says-my-hubby-life-friend-partner-gbogbo-sha/. Retrieved 1 December 2016.