Segun Bucknor
Segun Bucknor (tí wọ́n bí ní 29 March 1946 – tó sì kú ní 11 August 2017) jẹ́ olórin ilẹ̀ Nàìjíríà àti akọ̀ròyìn láàárín ọdún 1960 àti 1970. Ó jẹ́ ajẹdùrù àti atẹgìtá, tó dájú lé àwọn ẹ̀yà orin ti tẹ̀mí, pọ́ọ̀pù àti funk.[1] Látàri iṣẹ́ kékeré wọn, Segun àti ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin jọ ṣe àgbéjáde orin ẹlẹ́yàmẹyà tó dálé àṣà àti ọ̀rọ̀ ìṣèlú ní ilẹ̀ Nàìjíríà. Èyí tí àwọn BBC pè ní "interesting slice of Nigerian pop music history and culture".[2]
Segun Bucknor | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Lagos, Colony and Protectorate of Nigeria | 29 Oṣù Kẹta 1946
Aláìsí | 11 August 2017 Lagos, Nigeria | (ọmọ ọdún 71)
Iléẹ̀kọ́ gíga | King's College, Lagos Columbia University |
Iṣẹ́ | Musician, journalist |
Ìgbà iṣẹ́ | 1964–2000s |
Olólùfẹ́ | Sola Bucknor (until his death) |
Àwọn ọmọ | Funke Bucknor-Obruthe Tosyn Bucknor |
Musical career | |
Irú orin | Soul, Pop, Funk, Groove |
Instruments | Piano, guitar |
Labels | Vampi Soul, Premier Records LTD, Afrodisia |
Associated acts | Roy Chicago Segun Bucknor and the Assembly |
Bucknor jẹ́ bàbá oníṣẹ́ ayélujára, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tosyn Bucknor àti obìnrin oníṣòwò, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Fúnkẹ́ Bucknor-Obruthe.[3]
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀
àtúnṣeA bí Bucknor ní ilu Eko ní ọjọ́ 29 oṣù kẹta, ọdún 1946.[4] Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní King's College àti Columbia University, New York.[5][6][7] Ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ akọrin ilé-ìwé náà.[8]Ó bẹ̀rẹ̀ sí í súfèé gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ ọ̀wọ́ kékeré ṣùgbọ́n ó tẹ̀síwájú láti kẹ́kọ̀ọ́ bí a ti ń lu gìtá àti bí a ṣe ń tẹ duru.[9] Lákòókò yìí, ó kẹ́kọ̀ọ́ lábẹ́ ẹgbẹ́ Roy Chicago.[10]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "5 facts about the late phenomenal Nigerian Soul legend". Pulse. 11 August 2017. Archived from the original on 11 August 2017. Retrieved 12 August 2017.
- ↑ Bren O'Callaghan. "Segun Bucknor Poor Man Get No Brother Review". BBC. Retrieved 12 August 2017.
- ↑ "Funke Bucknor-Obruthe". businessinnigeria. 5 June 2015. Archived from the original on 1 December 2016. Retrieved 1 December 2016.
- ↑ Tosyn Bucknor (29 March 2017). "Happy Birthday Segun Bucknor!". Retrieved 15 August 2017.
- ↑ Bren O'Callaghan. "Segun Bucknor Poor Man Get No Brother Review". BBC. Retrieved 12 August 2017.
- ↑ "Musician Segun Bucknor dies at 71". The Nation. http://thenationonlineng.net/musician-segun-bucknor-dies-71/.
- ↑ "Segun Bucknor". JunoRecords. Retrieved 12 August 2017.
- ↑ Collins 1985, p. 133.
- ↑ Lukmon Fasasi (12 August 2017). "Segun Bucknor, musician and father of popular media personality Tosyn passes away at 71". Net. Retrieved 12 August 2017.
- ↑ "OAP Tosyn Bucknor loses dad". Information Nigeria. 12 August 2017. Retrieved 12 August 2017.