Faithia Balogun
Faithia Williams (tí a bí ní ọjọ́ karùn-ún oṣù kejì ọdún 1969) jẹ́ òṣèré, olóòtú ati olùdarí fíìmù ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1][2]
Faithia Williams | |
---|---|
Ìbí | February 5, 1969 Ikeja, Lagos State, Nigeria | (ọmọ ọdún 55)
Iṣẹ́ |
|
Awọn ọdún àgbéṣe | 1978–present |
Ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀
àtúnṣeA bí i ní ìlú Ikeja ní oṣù kejì ọdún 1969. Ó wá láti ìlú Okpara ní ìpínlẹ̀ Delta. Ó kàwé ni ilé-ìwé alákòóbẹ̀rẹ̀ Maryland àti Maryland Comprehensive Secondary School ní ipinlẹ Eko, níbi tí ó ti gba ìwé-ẹ̀rí ti West African School Certificate kí ó tó wá tẹ̀ síwájú ní Kwara State Polytechnic níbi tí ó ti gba ìwé-ẹ̀rí diploma. Ó ti fìgbà kan fẹ́ gbajúmọ̀ òṣèré sinimá àgbéléwò mìíràn tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Saheed Balógun, ṣùgbọ́n ìgbéyàwó wọn ti foríṣánpọ́n. [3]
Iṣẹ́
àtúnṣeÓ ti kópa nínú, jẹ́ olóòtú àti adarí ọ̀pọ̀lọpọ̀ fíìmù ti ilẹ̀ Nàìjíríà fún àìmọye ọdún. Ní ọdún 2008, ó gba àmì ẹ̀yẹ tí Africa Movie Academy fún òṣèrébìnrin tí ó dára jù lọ àti pé fíìmù rẹ̀ "ìránṣẹ́ ajé gba ẹ̀bùn fíìmù tí ó dára jù lọ ní ọdún náà . Ní oṣù kẹrin ọdún 2014, ó gba àmì ẹ̀yẹ ti Africa Movie Academy lẹ́yìn tí ó yanranntí gẹ́gẹ́ bíi òṣèrébìnrin tí ó dára jù lọ pẹ̀lú Ọdúnladé Adékọ́lá tí ó gba àmì ẹ̀yẹ gẹ́gẹ́ bíi òṣèrékùnrin tí ó dára jù lọ ní ọdún náà. Ó tún gba àmì ẹ̀yẹ fún fíìmù kan tí ó ṣe tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ ìyá alálàkẹ́ ní ọdún 2015 lórí Africa-Magic Viewers' Choice AMVCA
Ìgbésí ayé ara ẹni
àtúnṣeÓ ti fìgbà kan jẹ́ ìyàwó gbajú-gbajà òṣèré tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́, Saheed Balogun .[4][5]
Àwọn fíìmù tí ó ti gbé jáde
àtúnṣe- Farayola (2009)
- Aje metta (2008)
- Aje metta 2 (2008)
- Awawu (2015)
- Teni Teka (2015) [6]
- Omo Ale (2015)
- Agbelebu Mi (2016)
- Basira Badia (2016)
- Adakeja (2016)
- Eku Eda (2016)
- OBIRIN MI (2018)
Awọn itọkasi
àtúnṣe- ↑ "Fathia Balogun: Ilúmọọka oṣere tiata, Fathia Balogun ṣetan lati ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ lọna ara. - BBC News Yorùbá". BBC News Yorùbá. January 28, 2022. Retrieved May 23, 2022.
- ↑ Akinyoade, Akinwale (October 24, 2018). "Fathia Balogun Reacts To Wizkid And Tiwa Savage's Steamy "Fever" Video - Nigeria and World News". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. Retrieved May 23, 2022.
- ↑ "Fathia Williams features ex-husband Saheed Balogun in new movie". Premium Times Nigeria. 2019-07-31. Retrieved 2020-01-04.
- ↑ "Nollywood celebrates as Saidi Balogun, ex-wife Faithia Wiliams mark birthdays". Punch Newspapers. February 5, 2022. Retrieved May 23, 2022.
- ↑ Abiodun, Alao (February 5, 2022). "Fathia, Saheed Balogun ignore each other on birthdays - The Nation Newspaper". The Nation Newspaper. Retrieved May 23, 2022.
- ↑ "Latest Fathia Balogun Movies & Filmograpghy". Archived from the original on 2018-10-05. https://web.archive.org/web/20181005030754/http://yorubamovies.com.ng/fathia-balogun-movies. Retrieved 2017-05-08.