Ọmọba Ọláyíwọlá Fatai Ọlágúnjú, tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Fatai Rolling Dollar ni wọ́n bí ní ọjọ́ Kejìlélógún oṣù Kéje, ọdún 1927(22 July 1927) tí ó sì daláìsí ní ọjọ́ Kejìlá oṣùKèfà , ọdún 3013 –(12 June 2013), ni ó jẹ́ ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ní otílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ni ó jẹ́ olórin Highlife, àti Jùjú.[1] Ó kú ní dédé ọmọ ọdún mẹfàlélọ́gọ́rin (86), Aláṣẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Goodluck Jonathan sì ṣápọ́nlé rẹ̀.[1][2][3]

Fatai Rolling Dollar
Orúkọ àbísọPrince Olayiwola Fatai Olagunju
Wọ́n tún mọ̀ọ́ bíiFatai Rolling Dollar
Ọjọ́ìbí(1927-07-22)22 Oṣù Keje 1927
Ede, Nigeria
Aláìsí12 June 2013(2013-06-12) (ọmọ ọdún 86)
Lagos, Nigeria
Irú orinJuju, Highlife
Occupation(s)Singer-songwriter, instrumentalist
InstrumentsGuitar, vocals
Associated actsEbenezer Obey

Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ orin rẹ̀ ní ọdún 1953, ó sì ti kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ olórin níṣẹ́ orin. Lára wọn ni Olóyè Ebenezer Obey àti Okóyè Orlando Owoh tó ti dolóògbé. Fàtáì di ìlú mọ̀ọ́ká pẹ̀lú ìṣọwọ́ ta jìtá rẹ̀ lọ́nà àrà. Lára àwọn orin aládùn rẹ̀ ni "Wọ́n kéré sí Si Number Wa".

Ó dá ẹgbẹ́ akọrin tirẹ̀ sílẹ̀ ní ọdún 1957 tí ó pè ní Fatai Rolling Dollar and his African Rhythm Band, lábẹ́ ilé iṣẹ́ Phillips West Africa Records.[4]

Ikú rẹ̀

àtúnṣe

Ó kú nígbà tí ó ń sùn lọ́wọ́ ní ilé rẹ̀ tí ó wà ní ìlú Ìkòròdú, ní ìpínlẹ̀ Èkó[5] Ó sì jẹ́ ẹni tí ẹ̀mí rẹ̀ gùn jù nínú àwọn olórin ilẹ̀ Nàìjíríà jùlọ.[4]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 Empty citation (help) 
  2. Samuel Abulude, "Nigeria: Pa Fatai Rolling Dollar – a Music Icon", AllAfrica, 16 June 2013.
  3. ""Last pictures of Fatai Rolling Dollars", whisperNigeria.net.". Archived from the original on 2014-02-26. Retrieved 2019-06-11. 
  4. 4.0 4.1 "Highlife singer, Fatai Rolling Dollar dies @ 85", Vanguard, 12 June 2013.
  5. .