Fausat Balogun
Fausat Balogun tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Madam ṣajẹ,[1] ní wọ́n bí ní Ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejì ọdún 1959 (February 13th, 1959) jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin ọmọ bíbí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Sinimá àgbéléwò èdè Yorùbá ni Madam ṣajẹ tí gbajúmọ̀. [2][3] Gbajúmọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣèré sinimá àgbéléwò bẹ̀rẹ̀ nígbà tí ó kópa ère àwàdà lorí tẹlifíṣàn kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Ẹ̀rín kèékèé. Nínú eré yìí ni ó ti gba orúkọ ìnagijẹ rẹ̀, Madam ṣajẹ lọ́dún 1990. Lẹ́yìn èyí, Fausat Balógun tí kópa nínú eré sinimá àgbéléwò tí ó ti ju ọgọ́rin lọ.[1][4]
Fausat Balogun | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Fausat Balogun 13 Oṣù Kejì 1959 Ifelodun, Kwara State, Nigeria |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Orúkọ míràn | Madam ṣajẹ |
Iṣẹ́ | Film actress |
Ìgbà iṣẹ́ | 1975–present |
Olólùfẹ́ | Rafiu Balógun |
Ìgbésí ayé rẹ̀
àtúnṣeFausat Balógun fẹ́ òṣèré sinimá àgbéléwò mìíràn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Rafiu Balógun, Rafiu jẹ́ ọ̀gá rẹ̀ kí wọ́n tó fẹ́ ara wọn.[1] Nígbà tí ó fi di gbajúmọ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ ti dàgbà. Àkọ́bí rẹ̀ jẹ́ olùdarí fíìmù àgbéléwò, àbígbẹ̀yìn rẹ̀ tó sì jẹ́ obìnrin náà jẹ́ òṣèré fíìmù àgbéléwò.[4]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 1.2 Bada, Gbenga (16 May 2015). "'I reject scripts from English speaking movies,' Yoruba actress reveals". Pulse Nigeria. Archived from the original on 29 December 2015. https://web.archive.org/web/20151229124348/http://pulse.ng/movies/madam-saje-i-reject-scripts-from-english-speaking-movies-yoruba-actress-reveals-id3764008.html. Retrieved 10 January 2016.
- ↑ Olonilua, Ademola (16 May 2015). "Fausat Balogun Madam Saje:How I Met My Husband Rafiu & My Journey Into Nollywood". Naija Gists. http://www.naijagists.com/fausat-balogun-madam-saje-how-i-met-my-husband-rafiu-my-journey-into-nollywood/. Retrieved 10 January 2016.
- ↑ "Why I Reject English Role... Madam Saje". Daily Times of Nigeria. 21 May 2015. Archived from the original on 9 September 2015. https://web.archive.org/web/20150909222156/http://dailytimes.com.ng/why-i-reject-english-rolemadam-saje/.
- ↑ 4.0 4.1 "Interview With Yoruba Actress Fausat Balogun a.k.a Madam Saje". Daily Mail Nigeria. 26 January 2015. Archived from the original on 8 February 2016. https://web.archive.org/web/20160208020745/http://dailymail.com.ng/interview-with-yoruba-actress-fausat-balogun-a-k-a-madam-saje/. Retrieved 10 January 2016.