[1]Ọmọọbabìnrin Fifi Ekanem Ejindu jẹ́ Ayàwòrán-ilé, oníṣòwò obìnrin àti onínúure ará ilẹ̀ Nàìjíríà. A bí i ní ìlú Ìbàdàn ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà , ó jẹ́ ọmọ ọmọbìnrin Ọba James Ekpo Bassey ti ìlú Cobham ní Calabar ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà .

Fifi Ejindu
Ọjọ́ìbíOffiong Ekanem Ejindu
1962 (ọmọ ọdún 62–63)
Ibadan, Nigeria
Orílẹ̀-èdèNigerian
Iṣẹ́
  • Architect
  • businesswoman
  • philanthropist

Ìtàn ìgbésí-ayé

àtúnṣe

Fifi jẹ́ ọmọ ọmọọmọ James Ekpo Bassey, Efik Ọba ti Ìjọba amúnisìn tí ìjókòó rẹ̀ wà ní ìlú Cobham, Calabar, Nigeria. Ọba Bassey, bàbá àgbà ìyá rẹ̀, jẹ ọba ìlú Cobham nípasẹ̀ àwọn aṣojú Queen Victoria ní 1893 . Gẹ́gẹ́ bí i àbájáde àjogúnbá yìí, Ọmọọbabìnrin Fifi ń lo Orúkọ ti H.H. Obonganwan Ọba James ní àwùjọ.

Wọ́n bí Ọmọọbabìnrin náà ní Offiong Ekanem EjinduÌbàdàn, olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Nàìjíríà. Wọ́n tún tọ́ ọ níbẹ̀.

Bàbá rẹ̀, Ọ̀jọ̀gbọ́n Sylvester Joseph Una, kàwé ní Trinity CollegeDublin àti Brown UniversityUnited States. Òun ni mínísítà ìlera àkọ́kọ́ ní former eastern region of Nigeria ti Nàìjíríà , àti ọ̀kan lára National Parliament ṣáájú òmìnira. Ó tún ṣe iṣẹ́ akadá, ó sì di ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ ilẹ̀ wa ní Yunifásítì ti Ìbàdàn.[2] Ìyá Ọmọọbabìnrin Fifi, the Obonganwan Ekpa Una, náà kàwé ní England.

Ọmọọbabìnrin Fifi lọ UNC Charlotte.

Fifi wá lọ kẹ́kọ̀ọ́ Ayàwòrán-ilé ní Pratt Institute, ilé-ẹ̀kọ́ ayàwòrán aládàáni ní Brooklyn, New York. Ní 1983, ó kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní, ó sì di obìnrin dúdú Áfíríkà àkọ́kọ́ tí wọ́n fún ní B.Arch. láti ilé-ẹ̀kọ́ náà.[3] Lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́jáde, Fifi ṣe àwọn kọ́ọ̀sì ní Massachusetts Institute of Technology kí ó tó lọ ṣiṣẹ́ ní ilé-iṣẹ́ aládàáni ní New York City. Fifi tún wá padà sí Pratt Institute láti gba Masters nínú Urban Planning lẹ́yìn èyí tí ó padà sí Nàìjíríà.[4]

Bí ó ṣe dé Nàìjíríà, Ejindu bẹ̀rẹ̀ Starcrest Group of companies. Ilé-iṣẹ́ náà bẹ̀rẹ̀ ní 1995, ó sì jẹ́ àkójọ Starcrest Investment Ltd., Starcrest Associates Ltd. àti Starcrest Industries Ltd, gbogbo àwọn wọ̀nyí tí ń kópa nínú ilẹ̀ àti ilé, epo rọ̀bì àti gáàsì, àti ilé kíkọ́.[5]

Ní 2013, wọ́n fún un ní àmì-ẹ̀yẹ African Achievers African Arts and Fashion Lifetime Achievement award.[6]

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Celebrated architect, Fifi Ejindu hits diamond". The Sun Nigeria. May 21, 2022. Retrieved August 16, 2022. 
  2. Ovation Special Edition, issue 141. Fifi through the years. 2012. p. 145. 
  3. Ovation Special Edition, issue 141. Fifi through the years. 2012. p. 148. 
  4. Ovation Special Edition, issue 141. Fifi through the years. 2012. p. 191. 
  5. "CNN profiles Nigerian architect". Daily Independent. September 30, 2013. http://dailyindependentnig.com/2013/09/cnn-profiles-nigerian-architect/. 
  6. Olasot. "Fifi Ejindu honoured with an African arts and Fashion lifetime award". InfoLodge. Archived from the original on February 12, 2014. Retrieved August 30, 2013.