Fisayo Ajisola
Fisáyọ̀ Ajíṣọlá , tí a tún mọ̀ sí Freezon, [1] jẹ́ òṣèré lorí ẹrọ amóhùnmáwòrán àti òṣèré sinima àgbéléwò àti akọrin. Ó di gbajúmọ̀ fún ipa rẹ̀ tí ó kó nínú eré oníṣe aláwòtúnwò kan tí wọ́n pè ní Jenifa's Diary, pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Funke Akindele. Ó tún di gbajúmọ̀ fún ipa rẹ̀ tí ó kó nínú àwọn eré oníṣe bíi This Life, Nectar, Shadows, Burning Spear, Circle of Interest àti The Story of Us .[2] Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ìmọ̀ Biokemisitiri níle ẹ̀kọ́ Federal University of Agriculture, Abeokuta (FUNAAB), ní Ìpínlẹ̀ Ògùn.[1]
Fisáyọ̀ Ajíṣọlá | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Oluwafisayo Ajibola Ajisola Ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìjíríà |
Iṣẹ́ | Osere, Akọrin. |
Ìgbà iṣẹ́ | 2011 – lọwọlọwọ |
Website | jef.org.ng |
Ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀
àtúnṣeFisáyọ̀ jọ ọmọ bibi ìlú Ayédùn ní ìpínlẹ̀ Èkìtì, ní apá a gúúsù ìwọ̀-oòrùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[3] Fisáyọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ń kópa nínú àwọn eré ọlọkan-ò-jọ̀kan ní ilé-ẹ̀kọ́ oníwèé mẹ́wàá ti Federal Government College tí ó wà ní ìlú Òdogbòlú ní ìpìnlẹ̀ Ògùn. Ó forúkọ sílẹ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ eré tíátà ní ilè-ẹ̀kọ́ PEFTI tí ò wà nílú Èkó ní ọdún 2010.[3] Ó kópa nìnú eré Nnena and Friends Show.[3] Ó ṣe àgbékalẹ̀ àjọ kan tí kìí ṣe ti ìjọba (NGO) tí ó pè ní Jewel Empowerment Foundation, pẹ̀lú ìrètí láti fi ṣe ìrònilágbára fún àwọn ọ̀dọ́ àti àwọn ọmọdé.[4]
Ise ise
àtúnṣeFisayo bẹrẹ iṣẹ oṣere rẹ ni ọdun 2011, pẹlu awọn ipa ninu awon ere tẹlifisiọnu Naijiria bii “Tinsel”, “Spear Burning” ati “Circle of interest”. O gba isinmi kuro nibi ere ṣiṣe ni Oṣu Kẹsan, ọdun 2011 nigbati o ri igbawole si Ile-ẹkọ giga. Ajisola ṣe ifilọlẹ iṣẹ ṣiṣe fiimu re ni ọdun 2016[1] pẹlu sise fiimu Road to Ruin ni ifowosowopo pẹlu ipilẹ rẹ, Jewel Empowerment Foundation (JEF)[3] pẹlu ero lati gba ijọba niyanju lati gbe igbese fun ipese awọn iṣẹ fun awọn ọdọ Naijiria.[5] Oṣere Raphael Niyi Stephen, ti o kopa ninu fiimu naa, ti sọ pe: "Fiimu naa jẹ ọna lati jẹ ki awon eniyan mọ ohun ti n ṣẹlẹ si awọn ọmọde ati lati tun tele ohun ti ijọba n ṣe nipa ikiri oja, lati jẹ ki awọn eniyan mọ pe ikiri oja ko ni n ti o kan fun awon omo wa".[6]
Akojo ere
àtúnṣeEre telifisonu
àtúnṣeOdun | Akole | Ipa | Agberejade/Aludari | Afikun |
---|---|---|---|---|
2011 | Tinsel | Alajose | Tope Oshin Ogun | ere Telifisonu Mnet |
2011 | Burning Spear | Asiwaju | Akin Akindele | ere Telifisonu |
2011 | Circle of Interest | Alajose | Kalu Anya | ere Telifisonu |
2012 | Shadows | Asiwaju | Tunde Olaoye | ere Telifisonu |
2014 | Nectar | Alajose | Sola Sobowale | ere Telifisonu |
2015 | This Life | Ipa atilẹyin | Wale Adenuga | ere Telifisonu |
2016 | Jenifa's Diary | Alajose | Funke Akindele | ere Telifisonu alawada |
Awọn itọkasi
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 1.2 "Fisayo Ajisola To Consolidate On Acting Career In 2016". Leadership. Retrieved 23 September 2016.
- ↑ Amu, P (25 April 2016). "I Like Playing Crazy and Sexy Roles". AM Update. Archived from the original on 18 September 2016. https://web.archive.org/web/20160918042239/http://amupdate.com/2016/04/25/i-like-playing-crazy-and-sexy-roles-fisayo-ajisola/. Retrieved 23 September 2016.
- ↑ 3.0 3.1 3.2 3.3 Ebere, P (25 April 2016). "Meet Fisayo Ajisola a young Humanitarian, intelligent, pretty and excellent Actor...". Nigeria Films. https://www.nigeriafilms.com/movie-news/105-upcoming-celebrities/18879-meet-fisayo-ajisola-a-young-humanitarian-intelligent-pretty-and-excellent-actor. Retrieved 30 September 2016.
- ↑ Ogun, Tade (10 February 2016). "How I cope with male admirers - Fisayo Ajisola". Encomium Magazine. http://encomium.ng/how-i-cope-with-male-admirers-actress-fisayo-ajisola/. Retrieved 30 September 2016.
- ↑ "Fisayo Ajisola out with new movie". New Telegraph. 18 September 2016. Archived from the original on 24 September 2016. Retrieved 23 September 2016.
- ↑ "Nollywood actress, Fisayo, produces first movie ‘Road To Ruin’". Nigerian Tribune. 11 September 2016. http://tribuneonlineng.com/nollywood-actress-fisayo-produces-first-movie-road-ruin/. Retrieved 23 September 2016.