Àwọn Òpó Márùún Ìmàle

(Àtúnjúwe láti Five Pillars of Islam)

Àwọn Òpó Márùún Islam (Arabic: أركان الإسلام) ni à ń pè àwọn ojúṣe márùn-ún tó ṣe dandan fún Mùsùlùmí. Àwọn ojúṣe wọ̀nyí ni:

  • Shahada (ìjẹ́rìísí ìgbàgbọ́ wí pé ọ̀kan ṣoṣo ni Ọlọ́run àti pé ànọ́bì muhammad ẹrúsìn àti òjíṣẹ rẹ̀ ní ń ṣe),
  • Irun (àdúrà ojoojúmọ́ fún àwọn àdáyanrí wákàtí márùn-ún),
  • Ìtọrẹ àánú Zakat jẹ ọ̀ranyàn lẹ́ẹ̀kan lọ́dún fún gbogbo Mùsùlùmí tí ó bá ní owó ní ìpamọ́ ká odindin ọdún tí bùkátà kan kò kọlù. Ìdá kan nínú ogójì ni yóò fi ta ọrẹ (ọ̀pọ̀lọpọ̀ Mùsùlùmí ma ń sábà yọ zakat wọn lóṣù Ramadan nítorí i ládá tó pọ̀ nínú oṣù náà)
  • Àwẹ̀ oṣù Ramadan jẹ́ àwẹ̀ ọ̀ràn yàn ní gbígbà nínú oṣù Ramadan fún gbogbo Mùsùlùmí, àti
  • Haji (ìrìn-àjò lọ sí Mekka, ibi tí Masjid al-Haram (MỌṣáláṣí Mímọ́) wà, tó jẹ́ mosalasi tó gbajúmọ̀ jùlọ nínú Ìmàle).