Franca Afegbua
Franca Afegbua jẹ́ oníṣẹ̀-ewà àti olóṣèlú tó ṣe aṣojú fún Bendel North, ní ọdún 1983. Wọ́n yàn-án gẹ́gẹ́ bíi Sẹ́nátò National Party of Nigeria. Òun sì ni obìnrin àkọ́kọ́ tó wà níipò náà.[1]
Ìlú Okpella, ní Ipinle Edo ni wọ́n bí Afegbua sí. O parí ètò èkọ́ rẹ̀ ní ìlú Sofia, ní orílẹ̀-èdè Bulgaria. Kó tó dìgbà ìjọba ológun kejì, ó ṣisẹ́ gẹ́gé bíi onídìrí ní Ipinle Eko, ó sì ń gba àwọn oníbàárà olówó.[2] Afegbua súnmọ́ Joseph Tarka gan-an tó mu wọ ẹgbẹ́ olóṣèlú NPN nígbà náà. Ní ọdún 1983, ó fi lélẹ̀ pé òun fẹ́ wọ ipò Sẹ́nátọ̀ ní Bendel, àwọn èèyàn díè sì fun ní àǹfààní.[2] Ẹgbẹ́ tó wá nígbà náà wà ní ìtakò pèlú gómínà tó fẹ́ wọlé nígbà náà. Àmọ́ Afegbua gbapò kìíní nínú ìdíje àwọn onídìrí tí wọ́n se ní ọdún 1977.[2]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Gabriel, Emameh (12 July 2015). "The Okpella demand from Edo people - Vanguard News". Vanguard News. https://www.vanguardngr.com/2015/07/the-okpella-demand-from-edo-people/. Retrieved 4 February 2018.
- ↑ 2.0 2.1 2.2 Keazor, Emeka (25 March 2015). "Five Nigerian electoral case studies 1923-1983". Retrieved 4 February 2018.