Francis Agu

Òṣéré orí ìtàgé

Francis Agu tàbí Francis Okechukwu Agu jẹ́ òṣèré orí-ìtàgé sinimá ati orí ẹ̀rọ amóhù-máwòrán ọmọ ń orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí wọ́n bí ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù Kejì ọdún 1965. Ó di ìlú-mòọ́ká látàrí ipa rẹ̀ tí ó kó ní eré onípele àtìgbà-dégbà tí wọ́n ṣe àfihàn rẹ̀ ní orí ẹ̀rọ amóhù-máwòrán tí wọ́n pe àkòrí rẹ̀ ní Checkmate.

Francis Agu
Fáìlì:FrancisAgu.jpg
Ọjọ́ìbíFrancis Agu
(1965-02-18)18 Oṣù Kejì 1965
Lagos, Lagos, Nigeria
Aláìsí20 March 2007(2007-03-20) (ọmọ ọdún 42)
Ọmọ orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Ìgbà iṣẹ́1980s–2007
Notable workLiving in Bondage

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n bí Francis ní Ìpínlẹ̀ Èkó ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù Kejì ọdún 1965, sínú ẹbí ọ̀gbẹ́ni Fedelis àti aya rẹ̀ Virginia Agu tí wọ́n jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Wnugu-Nwogu ní Ìpínlẹ̀ Enugu òun sì ni àbíkẹ́yìn àwọn òbí rẹ̀. [1] Ó kẹ́kọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ Ladi-Lak Institute ní ìlú Alágoméjì ní agbègbè Èbúté-Mẹ́taÌpínlẹ̀ Èkó ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ ti St. Finbarr's College níbi tí Alàgbà Rev. Fr. Dennis Joseph Slattery sì tọ dàgbà tí ó jẹ́ olùdásílẹ̀ ilé-ẹ̀kọ́ náà. Ó tún lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Yunifásitì Ìpínlẹ̀ Èkó níbi rí ó ti kọ́ nípa ìmọ̀ ìbá ọ̀pọ̀ ènìyàn sọ̀rọ̀.

Iṣẹ́ rẹ̀

àtúnṣe

Agu bẹ̀rẹ̀ eré orí-ìtàgé ní inú ilé ìjọsìn wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ó ti ń bá ilé-iṣẹ́ ìfowó-pamọ́ Arab Bank ṣiṣẹ́ nígbà náà. Àkọ́kọ́ eré tí Agu yóò kópa níbẹ̀ ni wọ́n pe àkọ́lé eré tí James Ene Henshaw kọ tí Isaac John sì gbé jáde tí wọ́n pe àkọ́lé eré náà ní This is Our Chance. Agu kópa nínú eré yí gẹ́gẹ́ bí Ọba Damba . Àwọn eré mìíràn tún ni The Gods Are Not to BlameỌlá Rótìmí kọ, àti Trials of Brother Jero, eré tí ọ̀jọ̀gbọ́n Wọlé Ṣóyínká ṣe akọsílẹ̀ rẹ̀.

Gbajú-gbajà adarí eré Ṣẹ́gun Ọ̀Jẹ́wuyì darí eré kan tí Agu ti kópa tí ó pè ní The Man Who Never Died. Oríṣiríṣi eré tún ni Agu ti kópa pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn lààmì-laaka òṣèré bí Chuck Mike. Agu tún kópa nínú eré onípele àtìgbà-dégbà Checkmate níbi tí ó ti kópa gẹ́gẹ́ Benny, ní ọdún 1990. Ó tún kópa gẹ́gẹ́ bí Ichie Million nínú eré tí wọ́n pe akọ́lt rẹ̀ ní "Living in Bondage", eré yí mi ó sì sọọ́ si ìlú-mòọ́ká ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Agu gbé eré àkọ́kọ́ tirẹ̀ jáde ní ọdún 1994 tí ó pe akọ́lé rẹ̀ ní Jezebel, ó tún gbé awọn eré mìíràn tí ó tún darí awọn eré náà pẹ̀lú. Lára wọn ni In the name of Father, Love and Pride, A Devine Call, The Boy is Mine, Body and Soul, A Dance in the Forest àti Take me to Jesus.

Ikú rẹ̀

àtúnṣe

Agu ṣe àìsàn ní inú oṣù Kẹwàá ọdún 2006, ó sì papò dà ní inú ogúnjọ́ oṣù Kẹta ọdún 2007.

Àwọn àṣàyàn eré rẹ̀

àtúnṣe
  • Living in Bondage (1992)
  • Bloodbrothers
  • Bloodbrothers 2
  • A Minute to Midnite
  • Untouchable
  • Circle of Doom (1993)
  • Jesus
  • Blood Money (1997)

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe

Ìtàkùn ìjásóde

àtúnṣe

Àdàkọ:Authority control