Living in Bondage (Gbígbé nínú Ìgbèkùn), Apá kìn-ín-ní àti Apá kejì jẹ́ eré àgbéléwò asaragágá orílẹ èdè Nàìjíríà tí Chris Obi Rapu jẹ́ Olùdarí rẹ̀, a sì ti ọwọ́ Kenneth Nnebue àti Okechukwu Ogunjiofor,[1] kọ ọ́. Aṣagbátẹrù erè yìí ni Ogunjiofor,  Jafac Wine ló ṣe onígbọ̀wọ́ eré náà. Lára àwọn  Akópa inú eré-oníṣe àgbéléwò,[2] yìí ni Kenneth Okonkwo àti Nnenna Nwabueze nínú ẹ̀dá-ìtàn àlàjá wọn. Ó jẹ́ eré-oníṣe àgbéléwò orílẹ -èdè Nàìjíríà àkọ́kọ́ tí ó  dé ipile àṣeyọrí tó ní iyì nínú.[3]

Living in Bondage
Fáìlì:Living in Bondage 1992.jpg
AdaríChris Obi Rapu
Olùgbékalẹ̀Ken Nnebue
Òǹkọ̀wéKenneth Nnebue
Okechukwu Ogunjiofor
Àwọn òṣèréKenneth Okonkwo
Nnenna Nwabueze
Okechukwu Ogunjiofor
Francis Agu
Bob-Manuel Udokwu
Déètì àgbéjáde
  • 1992 (1992) (Part 1)
  • 1993 (1993) (Part 2)
Àkókò163 minutes
Orílẹ̀-èdèNigeria
ÈdèIgbo

Ní Oṣù Kẹjọ ní ọdún 2015,Charles Okpaleke gba ẹ̀tọ́ lórí Living in Bondage fún àkókò ọdún mẹ́wàá lábé ìṣàkóso ilé-isẹ́ ìsagbátẹrù Play Entertainment Network.[4] Ní oṣù kọkànlá ọdún 2019, A fi Eré-oníṣe Àgbéléwò ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀lẹ́ tí gbogbo  tí tomodé-tàgbá tí ń ṣàfẹ́rí Living in Bondage: Breaking free,[5][6] hàn, fún ìgbà Àkọ́kọ́ ni ìlú Eko.[7]

Ìtàn Eré

àtúnṣe

Andy Okeke (Kenneth Okonkwo) àti ìyàwó rẹ̀ Merit (Nnenna Nwabueze) bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ìjákunlẹ̀ pàdé – bí ìṣe ṣe ń bọ́ lọ́wọ́ wọn, ni wọ́n tún yan ara wọn jẹ nípa ṣíṣe Àgbèrè, wọn pàdánù owó Ìfipamọ́ wọn nínú Ìdókòwó ńlá. Àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ọkùnrin wọ̀bìà àti onífẹ̀ẹ́-kú-fẹ̀ẹ́ ló máa kọnu ìfẹ́ sí Merit, pàápàá jù lọ àwọn ọ̀gá rẹ̀ Ichie Million (Francis Agu) àti Chief Omego (Kanayo O. Kanayo). Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, Andy máa ń sábà ṣe àfiwéra àìlóríre ti rẹ̀ pẹ̀lú Àṣeyọrí àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ pàápàá Paul (Okechukwu Ogunjiofor) tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́-tímọ́ rẹ̀. Pẹ̀lú gbogbo àtìlẹ́yìn àti sùúrù tí Merit ní, Andy ń wá gbogbo ọ̀nà láti dí olówó pẹ̀lú ohunkóhun àti ọ̀nàkọnà tí ó bá fẹ́ gbà. Pọ́ọ̀lù ọlọ́gbọ́n Àrékérekè tú àṣírí rẹ̀ - Ẹgbẹ́ òkùnkùn tí gbogbo ọmọ  ẹgbẹ́ máa ń dá májẹ̀mú Ìsòótọ́ àti ìdúróṣinṣin pẹ̀lú Lucifer, tí wọ́n sì tún máa ń pá àwọn tí wọ́n fẹ́ràn gẹ́gẹ́ bí ohun ètùtù láti rí ọrọ̀ àti owó jaburata. Láì fi àkókò ṣòfò Andy gbà láti fi ìyàwó rẹ̀ Merit ṣe ìrúbọ ètùtù. Merit kú sí ilé ìwòsàn lẹ́yìn ọjọ́ tí wọ́n ṣe ètùtù kí ó tó kú ó fi ọkọ rẹ̀ ré.

Ọrọ̀ pàjáwìrì àti ìgbéyàwó ẹlẹ́kejì tí Andy ní fa Àkíyèsí àwọn àna rẹ̀ àná, èyí tí ó mú kí wọ́n fi ẹ̀sùn pípa ọmọ wọn Merit kàn án. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní àwọn ìdojúkọ- bí àwọn ayàwòrán gbajúmò ṣe máa ń dá sí ìgbé sí ayé ojoojúmọ́ rẹ̀, ìyàwó tuntun rẹ̀ Ego (Ngozi Nwosu)  gbé owó rẹ̀ sàlo lẹ́yìn ìgbéyàwó wọn, àti bí ẹ̀mí òkú Merit ṣé ń lé e kiri tí ó ṣì ń seru bà á ní àwọn ìgbà tí kò lérò. Andy tẹ̀síwájú láti máa bá Chinyere (Jennifer Okere) gbé gẹ́gẹ́ bí ìyàwó, obìnrin míràn tí ọ̀rẹ́ Merit Caro (Ngozi Nwaneto), mú u pàdé. Chinyere kú ikú àìtọ́jọ́ lẹ́yìn ìgbà tí Caro fún ní májèlé jẹ. Lẹ́yìn èyí Caro gbìyànjú láti sá lọ sí òkè òkun pẹ̀lú owó tí Chinyere jí lọ́wọ́ ọkọ rẹ̀. Caro kú nígbà tí ó ń lọ sí ilé ọkọ̀-òfuurufú lẹ́yìn ìgbà tí awakọ̀ kán gba lóju títì. Àwọn apànìyàn pa Paul lẹ́yìn  tí Andy dalẹ́bi  fún ìdí tí ó fi wọ́ inú ẹgbẹ́ òkùnkùn.

Lẹ́yìn gbogbo èyí, Andy padà lọ bèrè ìrànwọ́ nínú ẹgbẹ́ òkùnkùn náà, ṣùgbọ́n olúwo ẹgbẹ́ náà ní dandan ni ki ó pẹ̀rọ̀ fún òkú ìyàwó nípa gígé nǹkan ọmọ ọkùnrin rẹ̀ àti fífọ́ ara rẹ lójú. Ó kọ̀, ó sì di erè tí ó ń gbé lábẹ́ afárá di ìgbà tí Tina (Rita Nzelu)- ẹni tí ó ń ṣe iṣẹ́ Aṣẹ́wó tẹ́lẹ̀ nígbà tí Andy kọ́kọ́ pàdé rẹ̀ tí ó mú lọ sí ẹgbẹ́ òkùnkùn wọn gẹ́gẹ́ bí ohun èlò ètùtù kí àṣírí rẹ̀ tó tú , mú u lọ sí ilé-ìjọsìn níbi tí Andy tí jẹ́wọ́ wí pé òun lòún pá Merit, ìyá Andy (Grace Ayozie) sunkún létí ibojì ìyàwó ọmọ rẹ̀ ó sì tọrọ ìdáríjì.

Ní ìgbẹ̀yìn eré, Andy tí gba ìwòsàn, ó sì ń jọ́sìn pẹ̀lú àwọn ajíhìnrere onígbàgbó, tí wọ́n dáa lójú wí pé ó ti gba ìdáríjì fún gbogbo ẹ̀sẹ̀ rẹ̀.[8][9][10]

Àwon akópa

àtúnṣe
  • Kenneth Okonkwo as Andy Okeke[11]
  • Nnenna Nwabueze as Merit, Andy's wife
  • Kanayo O. Kanayo as Chief Omego, cult member
  • Felicia Mayford as Obidia
  • Francis Agu as Ichie Million, cult member and Merit's boss
  • Okechukwu Ogunjiofor as Paul, Andy's friend and cult member[12]
  • Ngozi Nwaneto as Caro, Merit's friend and Paul's girlfriend
  • Ngozi Nwosu as Ego, Andy's mistress
  • Clement Offiaji as Robert, fraudster
  • Chizoba Bosah as Merit's aunt
  • Bob-Manuel Udokwu as Mike, cult member
  • Sydney Diala as cult member/initiator
  • Daniel Oluigbo as cult chief priest
  • Obiageli Molugbe as cult mother
  • Rita Nzelu as Tina, local prostitute
  • Jennifer Okere as Chinyere, Caro's friend
  • Ruth Osu as Andy and Merit's neighbour
  • Grace Ayozie as Andy's mother
  • Benjamin Nwosu as Andy's father

Albètẹ́lẹ̀.

àtúnṣe

Ní ọdún 2015, àwọn àgbà Òṣèré Ramsey Nouah àti  Charles Okpaleke gba ẹ̀tọ́ lórí Living in Bondage láti ọwọ́ Kenneth Nnebue àtúnṣe eré náà ni ilẹ̀ Europe, America àti Nàìjíríà. Ìròyìn jáde lórí instagram ṣùgbọ́n ipele ìdàgbàsókè ló wà fún àkókò ọdún mẹ́ta.

Ní 2018, Nouah ṣe ìkéde pé àtúnṣe eré náà yóò wáyé ní ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀lẹ́ èyí tí a pe àkọlé rẹ̀ ní Living in Bondage: Breaking Free, èyí tí ó jáde ní November 8, 2019. Nouah tí ó ṣe olúwo tuntun ṣé ìfarahàn àkọ́kọ́ gẹ́gẹ́ bíi Olùdarí  eré náà pẹ̀lú àwọn Òṣèré míràn tí wọ́n kópa nínú eré náà nígbà àkọ́kọ́ tí a gbé e jáde bíi Okonkwo, Udokwu, àti Kanayo. Ìtàn èyí dá lórí ọmọ Andy Nnamdi àti bí ó ṣe fi ìwà burúkú jọ bàbà rẹ̀.  MBGN àná Muna Abii ṣé ìfarahàn àkọ́kọ́ gẹ́gẹ́ bí osere pẹ̀lú Swanky JKA tí ó ṣe ìpadàbọ̀ gẹ́gẹ́ bí Òṣèré nínú eré yìí.

Ní Oṣù karùn-ún, ọdún 2020, á gbé fíìmù Àgbéléwò yìí sórí Netflix.

Àwon iltọ́kasí

àtúnṣe
  1. Jagoe, Rebecca. "From Living in Bondage to the Global Stage: The Growing Success of Nollywood". The Culture Trip. Retrieved 2016-05-12. 
  2. Tucker, Neely (5 February 2005). "Nollywood, In a Starring Role". The Washington Post (Washington, D.C., USA). https://www.washingtonpost.com/wp-dyn/articles/A66-2005Feb4.html. Retrieved 7 August 2010. 
  3. Igwe, Amaka; Kelani, Tunde; Nnebue, Kenneth; Esonwanne, Uzoma (2008). "Interviews with Amaka Igwe, Tunde Kelani, and Kenneth Nnebue". Research in African Literatures 39 (4): 24–39. doi:10.2979/RAL.2008.39.4.24. ISSN 0034-5210. JSTOR 30131177. https://www.jstor.org/stable/30131177. 
  4. BellaNaija.com (2019-10-28). "We Had an Exclusive Chat with Charles Okpaleke, Executive Producer of "Living In Bondage: Breaking Free"". BellaNaija (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-11-03. 
  5. Living in Bondage: Breaking Free
  6. "'Living in Bondage: Breaking Free' is perfect for Ramsey Nouah's directorial debut (Review)". www.pulse.ng (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-10-31. Retrieved 2019-11-03. 
  7. "Charles Okpaleke's 'Living in Bondage the Sequel' Premieres". www.thisdaylive.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-11-08. Retrieved 2019-11-09. 
  8. "Nollywood dreams". Melbourne, Australia: The Age Company Ltd.. 31 July 2004. http://www.theage.com.au/articles/2004/07/28/1090694021912.html. Retrieved 7 August 2010. 
  9. Adebajo, Adekeye. "SA and Nigeria must throw culture into foreign policy mix". Johannesburg, South Africa: Times LIVE. Retrieved 7 August 2010. 
  10. "Nollywood turns out 2,000 films a year". Port of Spain, Trinidad: Trinidad and Tobago Newsday. 25 October 2006. Retrieved 7 August 2010. 
  11. "Andy has overtaken my real name, Kenneth Okonkwo cries out - Vanguard News". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2014-10-25. Retrieved 2016-05-12. 
  12. "Okechukwu Ogunjiofor". IMDb. Retrieved 2016-05-12.