Francis Odega jẹ́ òṣèré ẹlẹ́fẹ̀ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tí ó ma ń ṣe àwàdà, tí ó sì ti gba amì-ẹ̀yẹ fún àwàdà lórí fọ́rán fidio rẹ̀ tí ó gbòde kan lórí ẹ̀rọ ayélujára. Fọ́nrán fídíò yí ni ó sọ ọ́ si gbajú-gbajà tí ó fi rí ìbáṣepọ̀ òun pẹ̀lú àwọn ìlú mọọ́ká ní òkè òkun bíi: 50 Cents. [1]

Francis Odega
Ọjọ́ìbíAniocha North, Ìpínlẹ̀ Delta, Nàìjíríà
Iléẹ̀kọ́ gígaAmbrose Alli University
Iṣẹ́
Ìgbà iṣẹ́1996–present
Gbajúmọ̀ fúncomic roles and viral video clips

Etò ẹ̀kọ́ àti iṣẹ́ rẹ̀ àtúnṣe

Francis kẹ́kọ́ gboyè nínú ìmọ̀ Economics láti ilé-ékọ́ Ambrose Alli University. Òun ló ni ètò Night Of A Thousand Laughs tí ó wà fún pípa àwọn ènìyàn lẹ́rìín.[2] Francis gba àmì-ẹ̀yẹ "Best Actor" òun pẹ̀lú Hlomla Dandala fún òṣèré tí ó peregedé jùlọ "Best African Collaboration" ní ọdún 2013 Ghana Movie Awards 2013.[3] Francis di ìlú-mọ̀ọ́ká lẹ́yìnntí ó kópa nínú eré Back From South Africa tí gbajú-gbajà olórin 50 Cent àti Tinie Tempah ti kópa. Lára ipa tí ó kó ni bí ó ṣe ń sọ èdè Amẹ́ríkà nínú ẹ̀fẹ̀ rẹ̀.[4]

Àwọn àṣàyàn fíímù tí ó ti kópa àtúnṣe

Eré àtìgbàdégbà àtúnṣe

  • Clinic Matters

Àwọn Ìbáṣepọ̀ rẹ̀ àtúnṣe

Lẹ́yìn tí fídí rẹ̀ di ìlúmọ̀ọ́ká , Francis tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ Etisalat gẹ́gẹ́ bí aṣojú wọn.[5]

Àwọn Ìtọ́kasí àtúnṣe

Àwọn Ìtàkùn ìjásóde àtúnṣe