Gambo Sawaba
Hajia Gambo Sawaba tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù kejì ọdún 1933, tí ó sìn ṣaláìsí lóṣù kẹwàá ọdún 2001 (15 February 1933 – October 2001) jẹ́ ajìjàǹgbara ẹ̀tọ́ obìnrin, afowóṣàánú àti òṣèlú ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.[1][2] Òun ni igbákejì alága ẹgbẹ́ òṣèlú Great Nigeria People's Party, tí wọ́n sìn tún yàn án gẹ́gẹ́ bí olórí àwọn obìnrin nínú ẹgbẹ́ Northern Element Progressive Union (NEPU).[3]
Aáyan gẹ́gẹ́ bí òṣèlú àti ajàfẹ̀tọ́ọ̀ ènìyàn
àtúnṣeLáti ọmọ ọdún méjìdínlógún ni Sawaba tí bẹ̀rẹ̀ òṣèlú. Lásìkò náà, ẹgbẹ́ òṣèlú Northern People's Congress ní ó gbajúmọ̀ jùlọ lápá àríwá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, tí àwọn ọba wọ́n pẹ̀lú àwọn Aláṣẹ ìjọba Amúmisìn láti orílẹ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì ń gbè wọ́n lẹ́yìn nígbà náà, ṣùgbọ́n ní tìrẹ, ó dára pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò, Northern Element Progressive Union (NEPU). Ó jẹ́ olùpolongo tako gbígbé ọ̀dọ́mọbìnrin màjèsín ní ìyàwó, iṣẹ́-ipá àti aṣègbè ẹ̀kọ́ kíkà lápá àríwá Nàìjíríà.[4] Gambo, bẹ̀rẹ̀ sí ní gbajúmọ̀ nígbà tí ó bọ́ síta pẹ̀lú ìgboyà níbi ìdánilẹ̀kọ̀ọ́ òṣèlú kan tí ó sìn sọ̀rọ̀ níbi ìdánilẹ̀kọ̀ọ́ náà tí ó kún fún ọkùnrin ṣọ́ṣọ́.[4] Arábìnrin Fúnmiláyọ̀ Ransome-Kuti ní ó tọ́ ọ sọ́nà nígbà náà, tí ó sìn wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní ìlú Abẹ́òkúta lẹ́yìn ìgbà náà.[3] Òun obìnrin àkọ́kọ́ tí ó bẹ̀rẹ̀ ìjàǹgbara àwọn obìnrin apá àríwá Nàìjíríà.[4]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Kwewum, Rima (2004). THE GAMBO SAWABA STORY (second ed.). Abuja: Echo Communications Limited. pp. 52. ISBN 978-37305-0-9.
- ↑ Paul, Mamza. "Nigeria's Unsung Heroes (10). Feminism As a Prowess: The Profile of Chief (Mrs.) Margaret Ekpo and Hajiya Gambo Sawaba". Gamji. Retrieved 19 September 2017.
- ↑ 3.0 3.1 "Hajia Gambo Sawaba". NigeriaGalleria. Galleria Media Limited. Retrieved 19 September 2017.
- ↑ 4.0 4.1 4.2 "A Brief History Of Hajiya Gambo Sawaba -The Fearless Politician Who Fought For The Freedom Of Northern Women In Spite Of Several Imprisonments". Women.ng. Archived from the original on 3 November 2017. Retrieved 19 September 2017.