Gbénga Adébóyè (1959 –oṣu Kẹrin 2003) jẹ́ akọrin, apanilẹ́rìín, olótùú ètò orí rèdíò àti olùdarí ayẹyẹ.

Gbenga Adeboye Abefe Funwontan
Ọjọ́ìbíSeptember 30, 1959
Osun State, Nigeria
AláìsíApril 30, 2003
Nigeria
Orílẹ̀-èdèNigerian
Orúkọ mírànFunwontan Oduology
Ọmọ orílẹ̀-èdèNigerian
Iṣẹ́Comedian
Olólùfẹ́Omolara Gbenga Adeboye[1]
Parent(s)Rebecca Tinuola Adeboye (mother)[2]
Àwọn olùbátanDamilola Gbenga Adeboye (Daughter)[3]

Ibẹ̀rẹ̀ aye rẹ̀ àtúnṣe

Elijah Olúwágbémiga Adébóyè ni wọ́n bí ní ọgbọ̀n Ọjọ́ oṣù Késàn ọdún 1959 (30,9,1959), ní ìlú Ọdẹòmu ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, ní gúsù ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà[4]

Ìgbòkè-gbodò iṣẹ́ rẹ̀ àtúnṣe

Ó jẹ́ ògbóntagì sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ Orí rédíò ní Ipinlẹ̀ Èkó ní ibẹ̀rẹ̀ ọdún 1980, ní bi tí ó ti gba ìnagijẹ rẹ̀ "Fúnwọntán Oduọ́lọ́jì". Gbajúgbajà òṣèré orí-ìtàgé ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Ìdòwú Philip tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí "Ìyá Rainbow" ṣàpèjúwe Gbenga gẹ́gẹ́ bí adẹ́rìín-pòṣónú àti aláwàdà tí ó ma ń tọrẹ àtinúwá fẹ́ni tó bá ni lo ìrànlọ́wọ́. Nigba tí ó ń sọ bí Gbenga ṣe fun òun ní ọkọ ayọ́kẹ́lẹ́ àkọ́kọ́ tí òun kọ́kọ́ ní láyé òun. Wọ́n tu ṣàpèjúwe olóògbé náà gẹ́gẹ́ bí òntajà àti aláfihàn fàbú lọ́nà ìbílẹ̀ ṣáájú kí ó tó ku látàrí àìsàn tí ó nííṣe pẹ̀lú kídìnrín, ní ọjọ́ Kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù Kẹ́rin, ọdún 2003.[5]

Ẹ tún lè wo àtúnṣe

Àwọn ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. "I Kill Ram Yearly For My Husbands Remembrance - ...Regret Ever Marrying From Adeboyes Family - Lar". modernghana.com. Retrieved 11 February 2015. 
  2. "Gbenga Adeboye's Mother For Burial Sept 13". thenigerianvoice.com. Retrieved 11 February 2015. 
  3. "Dad was a car freak — Gbenga Adeboye’s daughter". The Punch - Nigeria's Most Widely Read Newspaper. Archived from the original on 29 January 2015. Retrieved 11 February 2015. 
  4. "Find Gbenga Adeboye's songs, tracks, and other music". Last.fm. 2018-10-10. Retrieved 2019-08-16. 
  5. Awojulugbe, Oluseyi (2016-05-01). "5 things to remember about Gbenga Adeboye". TheCable. Retrieved 2023-02-03.