Gentille Assih
Gentille Menguizani Assih (tí wọ́n bí ní 2 Oṣù Kẹẹ̀rin, Ọdún 1979) jẹ́ olùdarí eré àti agbéréjáde ọmọ orílẹ̀-èdè Tógò.
Gentille Assih | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 2 Oṣù Kẹrin 1979 Kpalimé |
Orílẹ̀-èdè | Togolese |
Iṣẹ́ | Film director, film producer |
Ìgbà iṣẹ́ | 2004-present |
Ìsẹ̀mí rẹ̀
àtúnṣeWọ́n bí Assih ní ìlú Kpalimé, orílẹ̀-èdè Tógò ní ọdún 1979.[1] Ó fẹ́ràn ṣíṣe iṣẹ́ sinimá láti ìgbà kékeré rẹ̀. Ní ọdún 2001, ó kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀-ẹ̀rọ kọ̀mpútà àti fọ́tòyíyà. Ní ọdún 2006, Assih tún kẹ́kọ̀ọ́ ìtàn-eré kíkọ ní orílẹ̀-èdè Sẹ̀nẹ̀gàl. Nígbà yìí kan náà ni ó gba oyè-ẹ̀kọ́ nínu ìmọ̀ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga African Institute of Commercial Studies Ní ọdún 2009, Assih gba oyè-ẹ̀kọ́ nínu ìmọ̀ ìṣàkóso àwọn òṣìṣẹ́.[2]
Assih ṣiṣẹ́ ní ilé-iṣẹ́ kan tó n rísí bíbáraẹnisọ̀rọ̀ fún ọdún méjì ṣáájú kí ó tó dá ilé-iṣẹ́ tirẹ̀ sílẹ̀ tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní “World Films”.[3] Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi olùdarí eré ní ọdún 2004 pẹ̀lú ṣíṣe àwọn fíìmù oníṣókí kan tí àkọ́lé wọ́n jẹ́ Le prix du velo àti La vendeuse contaminee. Ní ọdún 2008, ó ṣe adarí eré Itchombi.[4]
Ní ọdún tí ó tẹ̀le, Assih ṣe adarí àti agbéréjáde fún fíìmù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Bidenam, l’espoir d’un village ní ìlú Johannesburg, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹgbẹ́ Goethe Institute. Fíìmù náà dá lóri ayé Bidenam, ẹnití ó padà sí abúlé rẹ̀ lẹ́hìn ọdún mẹ́fà tí ó ti wà láárè, tó sì pinnu láti kọ́ àwọn ẹbí rẹ̀ bí wọ́n ti ń ṣe ètò ọ̀gbìn ní ìlànà ìbomirin. Àbúrò rẹ̀ obìnrin tí ó lọ kẹ́kọ̀ọ́ ní orílẹ̀-èdè Mòrókò ni ó mú àbá ìtàn eré náà wá.[5] Ní ọdún 2012, Assih ṣe adarí eré ìrírí gígùn kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Le Rite, la Folle et moi.[6]
Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀
àtúnṣe- 2004: Le prix du velo
- 2004: La vendeuse contaminee
- 2008: Itchombi
- 2009: Bidenam, l’espoir d’un village
- 2012: Le Rite, la Folle et moi
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Les Cinemas du Monde - 2e edition 2010" (PDF). Les Cinemas du Monde. Retrieved 15 October 2020.
- ↑ "Gentille Assih". Africultures (in French). Retrieved 14 October 2020.
- ↑ "Gentille Assih". Africultures (in French). Retrieved 14 October 2020.
- ↑ "Les Cinemas du Monde - 2e edition 2010" (PDF). Les Cinemas du Monde. Retrieved 15 October 2020.
- ↑ Waffo, Stephane (22 April 2010). "Entrevue avec Gentille M. Assih" (in French). Touki Montreal. https://www.toukimontreal.com/2010/04/22/entrevue-avec-gentille-m-assih/. Retrieved 15 October 2020.
- ↑ "Gentille Assih". Africultures (in French). Retrieved 14 October 2020.