Gideon Okeke jẹ́ òṣèrékùnrin ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, gbajúmọ̀ àti olóòtú ètò lórí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán.[1][2][3] Ó di gbajúmọ̀ ní ọdún 2006, nígbà tí ó kópa nínú ìdíje ti Big Brother Nigeria. Ní ọdún 2008, Gideon dara pọ̀ mọ́ àwọn akópa ti fíìmù M-NET tí wọ́n máa ń ṣàfihàn lórí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán, ìyẹn Tinsel.[4]

Gideon Okeke
Gideon Okeke at the 2021 AMA Awards
Ẹ̀kọ́Biochemistry, Nnamdi Azikiwe University
Iléẹ̀kọ́ gígaNnamdi Azikiwe University
Iṣẹ́Actor, Model, and TV Presenter.
Ìgbà iṣẹ́2006–present
Notable workRelentless
TelevisionBig Brother Nigeria
Tinsel
Àwọn ọmọ1

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀

àtúnṣe

Gideon jẹ́ ọmọ kan ṣoṣo tí àwọn òbí rè bí, ó sì dàgbà sí Ajegunle, èyí tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlú tó kún fún jàgídíjàgan ní Ìpínlẹ̀ Èkó.[5] Ó kẹ́kọ̀ọ́ ní Nnamdi Azikiwe University, níbi tí ó ti kọ́ nípa applied bio-chemistry. Lẹ́yìn náà ni ó forúkọ sílẹ̀ ní Lee Strasberg Institute, ní New York, níbi tí ó ti gba ẹ̀kọ́ nípa eré ṣíṣe.[5]

Iṣẹ́ rẹ̀

àtúnṣe

Iṣẹ́ rẹ̀ lórí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán

àtúnṣe

Lẹ́yìn tó farahàn nínú ìdíje Big Brother Nigeria Àkọ́kọ́, Gideon darapọ̀ mọ́ àwọn akópa eré Tinsel, èdá-ìtàn Phillip Ade Williams, sì ló ṣe.[6][7] Gideon ti farahàn nínú fíìmù ilẹ̀ South Africa kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Jacobs cross.[7] Ní ọdún 2014, ó ṣe ẹ̀dá-ìtàn Bernard nínú fíìmù irokotv kan, tí àkọ́lé rè ń jẹ́ Poisoned Bait, èyí ti Leila Djansi darí. Bákan náà, Gideon ni olóòtú ètò DSTV kan tó ń jẹ́ Money Drop.[8]

Eré Àgbéléwò

àtúnṣe

Eré Àgbéléwò àkọ́kọ́ tí Gideon máa ṣe ní Agbo Òseèré Nàìjíríà kan, tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Relentless, ní ọdún 2010. Lára àwọn akópa mìíràn tí wọ́n jìjọ ṣe fíìmù náà ni Jimmy Jean-Louis àti Nneka Egbuna.[9] Fíìmù ẹ̀kejì rẹ̀ ni fíìmù ọdún 2014 kan, tó jẹ́ mọ́ ìwá̀-ọ̀daràn, tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ A Place in the Stars. INí ọdún kan náà, ó ṣe ẹ̀dá-ìtàn Tobena, nínú fíìmù ajẹmọ́fẹ̀ẹ́ kan, tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ When Love Happens. Àwọn fíìmù mìíràn tí ó ṣe ni Gbomo Gbomo Express, àti 93 Days.[10][11]

Àtòjọ àwọn fíìmù rẹ̀

àtúnṣe

Eré orí-ìtàgé

àtúnṣe
Year Title Role Ref
Fractures
Fela... Arrest the Music Fela
Saro the Musical 2 Azeez

Eré orí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán

àtúnṣe
Year Title Role
2007 Big Brother Naija Himself
2008–present Tinsel Phillip Ade Williams
Jacob's cross
2014 Poisnned Bait
Money Drop Host

Fíìmù àgbéléwò

àtúnṣe
Year Title Role
2006 Relentless Obi
2014 A Place in the Stars Kim Dakim
...When Love Happens Tobena
2016 93 Days Morris-Ibeawuchi
Gbomo Gbomo Express Francis
2021 Loving Rona Benny Ramsey
2022 Obsession (2022 film)

Àwọn àmì-ẹ̀yẹ rẹ̀

àtúnṣe
Year Award Category Work Result Ref
2022 Africa Magic Viewers' Choice Awards Best Actor in A Comedy Loving Rona   Iṣẹ́ ń lọ lórí ẹ̀ [12]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Gideon Okeke is Dapper & Outspoken in the New Fratres Styleman Series - "Africa is more elegant than sack cloth, animal skin or loin clothing" - BellaNaija". www.bellanaija.com. 
  2. Izuzu, Chidumga. "Gideon Okeke: 7 things you probably don"t know about talented "Tinsel" actor". Archived from the original on 2017-08-10. Retrieved 2024-04-16. 
  3. Olowolagba, Fikayo (2022-03-09). "Don't envy us, we earn peanuts in Nollywood - Gideon Okeke". Daily Post Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-07-20. 
  4. NJOKU, BENJAMIN. "I’m an ambitious actor – Gideon Okeke, of Tinsel fame". 
  5. 5.0 5.1 "How Tinsel changed my story –Gideon Okeke". 12 October 2013. 
  6. "Africa Magic Official Website". Africa Magic Official Website. 
  7. 7.0 7.1 Izuzu, Chidumga. ""Tinsel": Show celebrates 1500th episode". Archived from the original on 2017-08-02. Retrieved 2024-04-16. 
  8. "Gideon Okeke hosts the Money drop Nigeria - Vanguard News". 12 January 2013. 
  9. Okoi-Obuli, Wendy. "Review – Andy Okoroafor’s ‘Relentless’ (Arthouse Exploration Of Contemporary Nigeria) - IndieWire". www.indiewire.com. 
  10. Izuzu, Chidumga. "Gideon Okeke: Actor is "Morris Ibeawuchi" in Steve Gukas" upcoming film "93 Days"". [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  11. "93 Days Top AMVCA Award Nominations List". Archived from the original on 2021-11-09. Retrieved 2024-04-16. 
  12. "2022 Africa Magic Awards Nominees don land- See who dey list". BBC News Pidgin. https://www.bbc.com/pidgin/tori-60818021.