Ginella Massa
Ginella Massa (a bí ní ọjọ́ kọ̀kandílógún oṣù kìíní, ọdún 1987)[1][2] jẹ́ oníròyìn telífísàn ti Kánádà. Ó jẹ́ oníròyìn Mùsùlùmí Afro-Latina[3] àti olùdarí ètò, òun ni oníròyìn amóhùn-máwòrán àkọ́kọ́ ní orílẹ̀ èdè Kánádà tí ń borí rẹ̀ lórí ètò ni ọdún 2015, òun sì ni àsọròyìn àkọ́kọ́ tí ń borí rẹ̀ nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí ní darí ètò ìròyìn ti ago mọ́kànlá fún CityNews lórí CITY-DT ní Toronto, Ontario, ní ọjọ́ kẹtàdínlógún Oṣù Kọkànlá, ọdún 2016.[4]
Ìgbé Ayé àti Iṣẹ́ Rẹ̀
àtúnṣeÓ kàwé gboyè pẹ̀lú àmì ẹ̀yẹ láti Yunifásítì York àti Ilé Ìwé Gíga fún àwọn olùkọ́ ti Seneca, ó ti ṣiṣẹ́ lẹ́yìn àti lórí papa eré fún àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn ni agbègbè àti orílẹ̀ èdè Kánádà láti ọdún 2010, pẹ̀lú CTV News, CFRB and Rogers Television, a sì ti gbe jáde ní The Globe and Mail àti ní National Post.Àdàkọ:Cn
Ní ọdún 2020, ilé iṣẹ́ ìròyìn Canadian Broadcasting Corporation kéde ré pé Massa lè dara pọ̀ ilé iṣẹ́ náà gẹ́gẹ́ bí adarí ètò prime-time lórí CBC News Network àti akọ̀wé ìròhìn fún The National.[5] Ètò rẹ̀, Canada Tonight, bẹ̀rẹ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ ni ọjọ́ kọkànlá oṣù kìíní, ọdún 2021, lórí CBC News Network.[6] Ní oṣù kẹwàá, ọdún 2022, Massa gba àyè ìsinmi tí àwọn ìyá titun máa ń gbà láti tọ́jú ọmọ rẹ̀ titun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bìí,[7] èyí tó mú kí Dwight Drummond di adarí ètò Canada Tonight fún ìgbà díè jálẹ̀ ọdún tí ó tẹ̀ le.[8][9]
Ní oṣù keje, ọdún 2023, Massa kéde lílọ kúrò rẹ̀ ní Ilé Iṣẹ́ Ìròyìn CBC láti gba iṣẹ́ olùkó fún apákan àkókò pẹ̀lú Yunifásítì Toronto Metropolitan.[7] Travis Dhanraj ni ó gba iṣẹ́ lọ́wọ́ Massa gẹ́gẹ́ bí adarí ètò tó yẹ fún Canada Tonight ni oṣù kìíní, ọdún 2024.[10]
Ìgbé Ayé Rẹ̀
àtúnṣeMassa fẹ́ ọkọ rẹ̀ ní ọdún 2018 ni Ìlú Toronto.[11]
Ní ọdún 2019, ó ṣe pancreaticoduodenectomy láti yọ máásì kúrò nínú òrónró rẹ̀.[12]
Àwọn Ìtọ́kási
àtúnṣe- ↑ "Reporter becomes Canada's first hijab-clad news anchor". The Guardian. November 26, 2016. https://www.theguardian.com/world/2016/nov/26/reporter-becomes-canadas-first-hijab-clad-news-anchor. ""Massa, 29...""
- ↑ Àdàkọ:Cite tweet
- ↑ Nouser, Mariam (February 2018). "Meet the Four Muslim Women That Have Inspired My Soul". Retrieved January 24, 2019.
Ginella is an Afro-Latina Muslim, and works as a reporter for CityNews, a local news channel in Toronto. She was born to a Christian family in Panama City, and became Muslim early on as a child when her mother converted to Islam.
- ↑ "Reporter becomes Canada's first hijab-clad news anchor". Hindustan Times. November 26, 2016. http://www.hindustantimes.com/world-news/ginella-massa-becomes-canada-s-first-news-anchor-in-hijab/story-PhSj34njHEp5zRrCjLXcAK.html. Retrieved November 26, 2016.
- ↑ Jackson Weaver, "Ginella Massa to join CBC News Network as primetime host". CBC News, October 28, 2020.
- ↑ Bruce DeMara, "Journalist Ginella Massa steps into national spotlight as host of Canada Tonight". Toronto Star, January 8, 2021.
- ↑ 7.0 7.1 Joshua Chong, "Ginella Massa, trail-blazing journalist and inaugural host of ‘Canada Tonight,’ to leave CBC News". Toronto Star, July 20, 2023.
- ↑ "Revolving Door". Broadcast Dialogue. 2022-10-27. Retrieved 2022-12-29.
- ↑ Àdàkọ:Cite tweet
- ↑ Thiessen, Connie (2023-11-20). "Travis Dhanraj named new host of CBC's 'Canada Tonight'". Broadcast Dialogue (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-01-23.
- ↑ "I Met My Husband The Love is Blind Way. Sort Of". www.msn.com. Retrieved March 14, 2020.
- ↑ "My Story Of Unintentional Weight Loss | Chatelaine". www.chatelaine.com. Retrieved March 14, 2020.
External links
àtúnṣe- Official website Archived 2023-12-05 at the Wayback Machine.