Godman Akinlabi
Godman Akinlabi (tí wọ́n bí ní 28 December 1974) jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó sì tún jé òǹkọ̀wé, asọ̀rọ̀-ní-gbangba, àti onímọ̀-ẹ̀rọ. Òun ni olùdarí ìjọ The Elevation Church.[1]
Godman Akinlabi | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Godman Akinlabi 28 Oṣù Kejìlá 1974 Oyo State, Nigeria |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iṣẹ́ | Pastor |
Ìgbà iṣẹ́ | 2010–present |
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ àti ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeWọ́n bí Godman Akinlabi ní December 28, 1974. Ìlú Igbo-Ora, ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ló ti wá, ìyẹn ní apá Ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà. Ìlú Ìbàdàn ló dàgbà sí, ó sì lọ sí ilé-ìwé Government College, Ibadan, ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, níorílẹ́-èdè Nàìjíríà láti ọdún 1985 wọ 1990. Ní ọdún 1992, wọ́n gbà á sí Federal University of Technology Akure, ní Ìpínlẹ̀ Òndó láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Mining àti Mineral Engineering, ní èyí tó sì gboyè èkọ́ Bachelor of Technology (B.Tech.) ní ọdún 1997. Ó gboyè ẹ̀kó ti master's degree ní international diplomacy ní University of Lagos. Ó jé akẹ́kọ̀ọ́ gboyè láti Manchester Business School, England, níbi tó ti gboyè MBA.[2]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Chika Ebuzor (3 January 2017). "The Clergy - Focus on Pastor Godman Akinlabi" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Pulse Nigeria. Archived from the original on 7 July 2017. Retrieved 23 November 2023.
- ↑ "Meet Pastor Godman" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2017-04-07.