Hafsat Abiola
Hafsat Olaronke Abiola-Costello (tí wọ́n bí ní ọjọ́ ọkàn lé lógún oṣù kéje ọdún 1974) ní ìlú Èkó. Ó jẹ́ àjàfẹ́tọ̀ọ́ ẹ̀tọ́ ọmọ Nàìjíríà, àwọn ẹ̀tọ́ aráàlú, àjàfẹ́tọ̀ọ́ ìjọba ara wa, àti olùdásílẹ̀ Kudirat Initiative for Democracy (KIND), èyí tí ó ń wá láti fún àwùjọ aráàlú lágbára àti ìgbélárugẹ ìjọba tiwa-n-tiwa ní ilẹ̀ Nàìjíríà.
Hafsat Abiola | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Hafsat Olaronke Abiola 21 Oṣù Kẹjọ 1974 Lagos, Nigeria |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Harvard University Tsinghua University |
Olólùfẹ́ | Nicholas Costello m.2005 |
Àwọn ọmọ | Khalil Anabella |
Parents |
|
Website | kind.org/whoweare/board |
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ Ayé Rẹ̀ àti Ètò Ẹ̀kọ́
àtúnṣeAbiola-Costello ni ọmọ kẹjọ ti Ààrẹ tí wọ́n yan ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí kò jẹ́, Olóyè Moshood Abíọ́lá àti Olóògbé Kudirat Abíọ́lá. Bàbá rẹ̀, Moshood Abíọ́lá, tí wọ́n fi sẹ̀wọ̀n l'ọ́wọ aṣẹ̀jọba Gen Sani Abacha fún ìwà ọdaràn lẹ́yìn tí ó ti kéde ara rẹ̀ ní ààrẹ. Àgbà Abíọ́lá kú nígbà tí ó wà ní àtìmọ́lé ní ọdún 1998.[1] Láàkókò tí wọ́n pa ìyá rẹ̀ ní àkókò ìfihàn kan fún ìtúsílẹ̀ ọkọ rẹ̀ ní ọdún 1996.[2] Ní oṣù kẹfà ọdún 2018, ààrẹ Muhammadu Buhari fún un ní olórí aláàkóso fún bàbá rẹ̀ tó kú, Olóyè Moshood Abíólá, fún ẹni tí ó yẹ kó jáwé olúborí nínú ìdìbò ààrẹ ní ọjọ́ kejìlá oṣù kẹfà ọdún 1993. (GCFR).[1] [2] [3][4]
Abiola-Costello lọ ilé-ìwé gíga rẹ̀ ní Queens College, Yaba, ìlú Èkó. Ó kàwé gboyè ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga Phillips Academy, Andover, ní ọdún 1992 àti Harvard College ní ọdún 1996 níbití ó ti gba oyè kan ní Ètò-ọ̀rọ̀ Ìdàgbàsókè (Development Economics) àti lẹ́hìn náà gba M.Sc. ní International Development láti Tsinghua University, Beijing.
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "CNN - Nigerian opposition leader Abiola dies - July 7, 1998". edition.cnn.com. Archived from the original on 2022-04-16. Retrieved 2022-04-16.
- ↑ The Brutal Assassination of Kudirat Abiola Archived 2017-10-06 at the Wayback Machine., NAIJArchives, Retrieved 8 February 2016
- ↑ "Buhari declares June 12 Democracy Day, honours Abiola with GCFR". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-06-07. Retrieved 2022-03-25.
- ↑ "Buhari formally confers GCFR on Abiola". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-06-12. Retrieved 2022-04-16.
- ↑ "Our Board". KIND (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-06-08.