Hannah Idowu Dideolu Awolowo
Hannah Idowu Dideolu Awolowo (àbísọ Adelana; Ọjọ́ karùndínlọgbọ̀n Oṣù kọkànlá Ọdún 1915 – Ojọ́ ọkàndínlógún Oṣù kẹsán Ọdún 2015), tí àwọn ènìyàn mọ̀ sí HID,[1] jẹ́ ọmọ bíbí ìlú kékeré kan tí wọ́n ń pè ní Ikenne ní ìpínlẹ̀ Ògùn ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ó kàwé ní Methodist Girls High School, ní ìlú Èkó.[2] Ó fẹ́ olóṣèlú tí a mọ̀ sí Obafemi Awolowo láti Ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n Oṣù kejìlá Ọdún 1937 di ìgbà tí olóṣèlú náà fi kú ní ọdún 1987. O máa ń pèé ní "Òkúta iyebíye tí kò lẹ́gbẹ́".[3]
Hannah Idowu Dideolu Awolowo | |
---|---|
Àwòrán HID Awolowo ní ìwájú ilé ẹbí rẹ̀ | |
Ìyàwó olórí ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà | |
In office Ọjọ́ kínín Oṣù kẹwá ọdún 1954 – Ọjọ́ kínín Oṣù kẹwá ọdún 1960 | |
Arọ́pò | Faderera Aduke Akintola |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | Hannah Idowu Dideolu Adelana 25 Oṣù Kọkànlá 1915 Ikenne, British Nigeria |
Aláìsí | 19 September 2015 | (ọmọ ọdún 99) (ọ̀kàndínlọgọrún)
Ọmọorílẹ̀-èdè | Ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà |
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | Unity Party of Nigeria (1978–1983) Action Group (1950–1966) |
(Àwọn) olólùfẹ́ | Obafemi Awolowo (m. 1937; died 1987) |
Ẹbí | Yemi Osinbajo (ọkọ-ọmọ ẹ̀) Dolapo Osinbajo (ọmọ-ọmọ rẹ̀) |
Àwọn ọmọ | Segun Awolowo Tola Oyediran Oluwole Awolowo Ayodele Soyode Tokunbo Awolowo-Dosunmu |
Residence | Ìpínlẹ̀ Ògùn |
Education | Methodist Girls' High School |
Profession | Oníṣòwò obìrin |
Ìgbésíayé
àtúnṣeHID jẹ́ ògbónta oníṣòwò àti olóṣèlú. Ó kó ipa ribiribi nínú òṣèlú ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. O dúró ti ọkọ rẹ̀ nìgbà àjọṣepọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú NCNC àti AG, tí wọ́n pè ní United Progressive Grand Alliance (UPGA), nígbà tí ó ń ṣẹ̀wọ̀n lọ́wọ́.
Èrò wọn ni wípé kí ó díje fún ìbò náà tí ó bá sì wọlé kí ó sì jẹ́ kí ọkọ rẹ̀ bọ́ sórí àléfà làtàri ìbò tiwantiwa. Kí ó lè di ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ó ń tẹ̀lé ọkọ rẹ̀ kákàkiri orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti rọ àwọn ènìyàn kí wọn ó dìbò fún. Ó tún jẹ́ adarí àwọn obìrin ẹ̀gbẹ́ òṣèlú náà tí ó sì maa ń wà ní gbogbo ìpàdé ẹgbẹ́ náà. Gẹ́gbẹ́ bí oníṣòwò, ó jẹ́ obìnrin àkọ́kọ́ tí ó máa jẹ́ alábápin ọjà fún Nigerian Tobacco Company (NTC) ní ọdún 1957. Ohun ní ó máa kọ́kọ́ ko aṣo léèsì àti àwọn aṣo míràn bẹ́è wọ Nàìjíríà. Ní Ojọ́ ọkàndínlógún Oṣù kẹsán Ọdún 2015, ó jẹ́ olọ́run nípè lẹ̀yìn tí ó lo ọdún ọ̀kàndínlọgọrún láyé, oṣù mẹ́jì kí ó ṣe ọjọ́ ìbí ọgọ́rún ọdún.[4][5][6] Wọ́n sìnkú rẹ̀ sí ẹ̀gbẹ̀ ọkọ rẹ̀ ní Ikenne ní Ojọ́ karún Oṣù kẹsán Ọdún 2015.[7]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Oyetimi, Kehinde. "Hannah Idowu Dideolu Awolowo(HID) clocks 95 on Thursday". Archived from the original on 17 December 2013. Retrieved 5 August 2013. More than one of
|accessdate=
and|access-date=
specified (help) - ↑ Musa Odoshimokhe (November 25, 2015). "How Awolowo met, married HID". The Nation. http://thenationonlineng.net/how-awolowo-met-married-hid/. Retrieved June 16, 2016.
- ↑ Adeniyi, Tola (1993). The jewel: the biography of Chief (Mrs.) H.I.D. Awolowo. Gemini Press. ISBN 978-978-31953-0-1.
- ↑ "Late politician's wife dies at 99". Pulse Nigeria. 19 September 2015. Archived from the original on 20 November 2016. https://web.archive.org/web/20161120212242/http://pulse.ng/local/hid-awolowo-late-politicians-wife-dies-at-99-id4183795.html. Retrieved 19 September 2015.
- ↑ Samuel Awoyinfa. "Mama died in my arms – Tokunbo Awolowo-Dosunmu". Nigeria: The Punch. http://www.punchng.com/news/mama-died-in-my-arms-tokunbo-awolowo-dosunmu/. Retrieved September 22, 2015.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ Earnest Nwokolo (September 20, 2015). "H. I. D. AWOLOWO 1915 – 2015 ‘Mama died singing, praying’". the Nation. http://thenationonlineng.net/hid-awolowo-passage-of-a-matriarch-mama-died-singing-praying/. Retrieved September 22, 2015.
- ↑ Daud Olatunji (November 27, 2015). "Hannah Idowu Dideolu Awolowo: Buried in grand style". The Vanguard. http://www.vanguardngr.com/2015/11/hannah-idowu-dideolu-awolowo-buried-in-grand-style/. Retrieved December 6, 2015.