Yemi Osinbajo

Olóṣèlú

Olúyẹmí Olúlékè Òṣínbàjò (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kẹjọ oṣù karùn-ún ọdún 1947) jẹ́ òṣèlú àti igbákejì Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà [1] . Ó gorí àléfà fún sáà àkókò pẹ̀lú Ààrẹ Muhammadu Buhari lọ́jọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù karùn-ún ọdún 2015. Lọ́dún 2019, ó tún wọlé lẹ́ẹ̀kejì gẹ́gẹ́ bí igbákejì Ààrẹ, òun ti Ààrẹ Muhammadu Buhari. Òṣínbàjò jẹ́ agbẹjọ́rọ̀-àgbà (Senior Advocate of Nigeria, SAN).

Yẹmí Òṣínbàjò
Yemi Osinbajo 2017-05-27.jpg
Yẹmí Òṣínbàjò, Vice President of Nigeria, at the 43rd G7 summit
14th Vice President of Nigeria
Lọ́wọ́lọ́wọ́
Ó gun orí àga
29 May 2015
ÀàrẹMuhammadu Buhari
AsíwájúNamadi Sambo
President of Nigeria
Acting
In office
7 May 2017 – 19 August 2017
AsíwájúMuhammadu Buhari
Arọ́pòMuhammadu Buhari
In office
19 January 2017 – 13 March 2017
AsíwájúMuhammadu Buhari
Arọ́pòMuhammadu Buhari
In office
6 June 2016 – 19 June 2016
AsíwájúMuhammadu Buhari
Arọ́pòMuhammadu Buhari
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí
Oluyemi Oluleke Osinbajo

8 Oṣù Kẹta 1957 (1957-03-08) (ọmọ ọdún 64)
Lagos, British Nigeria
(now Nigeria)
Ẹgbẹ́ olóṣèlúAll Progressives Congress
(Àwọn) olólùfẹ́Oludolapo Osinbajo
Àwọn ọmọ3
EducationUniversity of Lagos (LLB)
Nigerian Law School
London School of Economics (LLM)
WebsiteOfficial website

Ìgbéyàwó, ẹbí àti ìgbésí ayé.Àtúnṣe

Yemí Òşínbàjò ni wón bí sí'nú ebí Opéolúwa Òşínbàjò ní ojó kejo oşù keta (Oşù Erénà), odún 1957 ní ilé ìwòsàn ti Kírííkìì (Creek Hospital) ní Ìlú Èkó. Òşínbàjò şe ìgbeyàwó pèlú u Dolápò Òşínbàjò, eni tí orúko bàbá a rè ń jé Şóyodé. Dolápò jé omo sí omo bíbí inú u olóyè Obáfémi Awólówò. Wón ní àwon omo méta; méjì nínú u won jé omobìnrin tí orúko won sì ń jé Dámilólá àti Kányinsólá, àti tí omokùnrin won a sì má a jé Fìyìnfólúwa Òşínbàjò.

ÈkóÀtúnṣe

Yemí Òşínbàjò kó èkó ní ilé èkó o alákòóbèrè Kòrónà (Corona) ní ìlú Èkó ní orílè èdè Nàìjíríà. Láàrín in odún 1969 sí odún 1975, ó lo sí Kóléèjì Igbóbì, Yaba ni Èkó bákan náà, níbi tí ó ti gba àmì èye ti Ìpínlè ní odún 1971. Ó gba èbùn ti ilé ìwé fún fífo èdè Gèésì ní odún 1972; èbùn ti Adé Oba fún fífo èdè Gèésì l'áti odún 1972 títí di odún 1975; èbùn Elias fún eni tí işé e rè dára jù lo nínú èkó ìtàn (History) nínú èsì ìdánwò oníwè é méwàá (WASC) ti odún 1973. Ó tún gba èbùn ilé ìwé gíga ti HSC fún èkók Lítíréşò ní odún 1975.

Léhìn náà, ó lo k'ékòó gb'oyè àkókó ní ilé èkó gíga Yunifásitì Èkó láàárín odún 1975 sí odún 1978. Ìgbà yì í ni ó k'ékò ó gba oyè onípele ìkejì ní ilé ìwé gíga l'órí ìmò òfin. Níbí ni ó tún ti gba àmì èye ti Graham-Douglas fún òfin ìdókòwò (Commercial Law). Ní odún 1979, ó parí ìkékòó àmòdájú olódún kan tí ó pon dandan ní ilé èkó ìmò òfin Nàìjíríà níbi tí wón ti gbà á l'áti má a ş'işé gégé bí i amòfin àti agbejórò ilé ejó gíga (Supreme Court) ti ilè Nàìjíríà ní odún 1980.

Iṣé Òfin.Àtúnṣe

L'áti odún 1979 sí odún 1980, Òşínbàjò kó'pa ní'nu sínsin orílè èdè e rè, èyí tí ó pon dandan fún odún kan, gégé bí i ògá amòfin pèlú u ilé işé tí ó ń rí sí ìdàgbàsókè àti ètò Béńdèl (BDPA) ní Ìpínlè Béńdèl.

Ní odún 1981, wón gba Òşínbàjò sí'şé gégé bí i olùkóni ní'mò òfin ní ilé èkó gíga Yunifásitì Èkó, Nàìjíríà. L'áti odún 1983 sí odún 1986, ó jé olùkó àgbà l'órí i ìmò òfin ní Yunifásitì Èkó. L'áti odún un 1988 sí odún 1992, ó jé onímòràn (onímòràn òfin àti ejó) sí Agbejórò Gbogboògbò (Attorney General) àti Mínísìtà fún ìdàjó, Bólá Ajíbólá. Òşínbàjò bèrè işé olùkóni ní omo odún métàlélógùn.

Láti odún un 1997 sí odún un 1999, wón so Òşínbàjò di òjògbón nínú u ìmò òfin àti olórí i èka òfin ti gbogbo ènìyàn ti èka ìkékòó òfin ní Yunifásiti Èko. Láti odún un 1999 sí odún un 2007, Òşínbàjò jé omo egbé ìgbìmò ilé işé ìdájó ti Ìpínlè Èkó. Ní odún un 2007 bákannáà, wón fi Òşínbàjò je ògá alábàáaşepò ti àwon alábàáaşepò SimmonsCooper (àwon Amòfin àti àwon Agbejóro) ní Nàìjíríà. Òşínbàjò tún jé olùkóni àgbà ní Yunifásiti ti Ìpínlè Èkó. Òun tún ni Agbejórò Gbogboògbò (Attorney General) àti Komíşánnà fún ètò ìdájó. L'áti odún un 2007 sí odún un 2013, Òşínbàjò tún gba işé gégé bí i òjògbón onímò òfin ní Yunifásiti Èkó.

Iṣé Olùşó ÀgùntànÀtúnṣe

Yemí Òşínbàjò ni olùşó àgùntàn tí ó ń şe àmójútó ekùn ilé ìjosìn ìkejì-dín-l'áàádóta ti Igi Ólíífì (Olive Tree Provincial Headquarter) ti Ìjo Ìràpadà Ti Krístì tí ó wà ní Ìlú Èkó.

Igbákejì ÀàreÀtúnṣe

Ìgbà àkókóÀtúnṣe

Àwọn ìdìbò ọdún 2015Àtúnṣe

Léhìn tí won şe ìdásílè egbé onígbàálè (All Progressive Congress) ní odún 2013, wón fún Yemí pèlú u àwon olókìkí omo ilè Nàìjíríà mìíràn ní işé láti şe àgbékalè àkosílè àwon ètò àti oun tí egbé tuntun yì í má a múlò. Eléyì í ló yo'rí sí àkójopò tí wón pè ní "ìlànà sí Nàìjíríà tuntun", èyí ni ìwé àkosílè kan tí egbé onígbàálè (All Progressive Congress) ké'de rè gégé bí àkosílè ètò àti ìşe tí egbé yì í má a şe nígbà tí wón bá yàn wón sí orí i àlèéfà. Àwon ohun pàtàkì nínú un ìlànà yì í ni ètòt oúnje òfé fún àwon omo ilé ìwé, fífi owó ránşé pèlú u gbè-n-déke (conditional cash transfer) sí mílíònù méèdógbòn àwon aláìní jù lo omo ilè Nàìjíríà tí wón bá fi orúko omo won sí'lè l'áti lo ilè ìwé, tí wón sì tún gba abéré àjesára fún won. Àwon onírúurú u ànfààní ètó sí orò ajé fún òpòlopò òdó omo Nàìjíríà ni ó tún wà.

Ní ojó ketàdínlógún odún 2014, olùdíje fún Ààre l'ábé e egbé e Onígbàálè (All Progressive Congress), ògágun-fèhìntì Mòhámmódù Bùhárí ké'de Òşínbàjò gégé bí i amúgbálégbè é rè àti olùdíje fún igbákejì Ààrr fún ìdìbò gbogboògbò ti odún un 2015.

Ní ojó kokànlélógbòn oşù keta (Oşù Erénà) odún un 2015, àjo tí ó ń rí sí ètò ìdìbò jérì í sí yíyan Bùhárí gégé bí i eni tí ó bo'rí ìdìbò ti Ààre. Báyì í ni Òşínbàjò şe di igbákejì Ààre tí a d'ìbò yàn fún orílè èdè Nàìjíríà. Wón bú'ra fún àwon méjèèjì ní ojó kokàndínlógbòn oşù karùn un (Oşù Èbìbí) odún 2015. Ní ojó ketàdínlógún oşù kejo (Oşù Ògún) odún 2017, igbákeji Ààre Yemí Òşínbàjò şe àpèjúwe òrò ìkóríra gégé bí i èyà ìpaniláya.

ÀkókòÀtúnṣe

 
Igbẹhin ti Igbakeji Aare

Yemí Òşínbàjò dá'wó lé işé gegegégé bí i igbákejì Ààre orílè èdè Nàìjíríà ní ojó kokàndínlógbòn oşù karùn ún ní gbàgede ti Eye Idì (Eagle Square) ní Àbújá. Ojúşe rè ni l'áti bójútó àti l'áti ròyìn nípa egbé tí ó ń rí sí ètòt orò ajé, kí ó sì şe ètò nípa ìgbani ní ìyànjú lo sí òdò Ààre, eni tí yí ò mú ìpinnu wá gbèhìn. Gégé bí i ìpìnlè e rè niínú ìmò ò ofin àti ìrírì i rè gégé bí i komísánnà fún ètò ìdájó ní Ìpínlè Èkó fún odún méjo, òpò ènìyàn l'érò pé yí ò k'ópa tó jo'jú nínú u àtúnşe tí a ní'lò ní'nú ètò òfin orí'lè èdè e wa. Nígba tí egbé Onígbàálè (All Progressive Congress) ń polongo fún ìbò ní odún 2014/15, Yemí Òşínbàjò şe òpòlopò ìpàdé pèlú àwon ará ìlú yíká orílè èdè ní ìlòdì sí ìpòlo-n-go gba-n-gba tí òpò omo orí'lè èdè Nàìjíríà òun olóşèlú u won má a ń şe télè. Òkan nínú àwon ìlérí tí ó şe ní'gbà ìpolo-n-go ìbò, tí ó sì tún so láìpé yìí ni ti ètò l'áti fi oúnje èèkan l'ójúmó bó omo ilé ìwé kòòkan. Yàtò sí fífún omo ilé ìwé ní oúnje, ó tún te'nu mo láìpé pé ètò yìí yó ò pèsè oríşiríşi işé (ilérí ìpolo-n-go ìbò míràn) fún àwon tí ó bá da'ra pò l'áti ş'işé l'ábé e ètò yìí l'áti mu wá sí ìmúşe.

Adelé ÀàreÀtúnṣe

Ààre Mùhámmádù Bùhárí ko àkosílè ní ojó kesàán osù karùn-ún odún 2017 sí Ààre ilé ìgbìmò aşòfin àgbà àti ti ilé ìgbìmò aşòfin kékeré lórí i ìpinnu rè láti bèrè ìrìn àjò fún ìtójú àìlera rè. Wón ka ìwé yì í ní ojó kesàn án oşù karùn ún odún 2017 ní ibi àpérò àwon ilé méjèèjì, ti aşòfin àgbà àti ti kékeré ní şíşè-n-tèlé. Igbákejì Ààre, òjògbón Yemí Òşínbàjò ni wón jíròrò lé so di adelé Ààre fún àkókò tí Ààre Bùhárí yí ó ò fi wà ní ìsinmi nítorí i àìlera rè.

Ní ojó keje oşù kejo odún 2018, Òşínbàjò yo ògá àgbà tí ó ń rí sí ààbò ará ìlú, Làwál Dàùra kúrò l'énu işé fún wíwo ilé Aşòfin ti àwon tí ó di ìhámóra ogun pèlú u ìbòjú l'áti èka ilé işé rè wà á ní ònà tí kò tó. Dàùra ni wón ti fi Mathew Seiyefa ró'pò o rè.

Àkókò KejìÀtúnṣe

Awon itokasiÀtúnṣe

  1. "Vice President Yemi Osinbajo". The Statehouse, Abuja. 2018-05-06. Retrieved 2021-09-11.