Hárúnà Bello Ìṣọ̀lá (1919 - 9 November, 1983) jẹ́ gbajúgbajà Olórin Àpàlà ọmọ bíbí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. [1]

Iṣẹ́ orin kíkọ

àtúnṣe

Ìlú Ibadan ni wọ́n bí wọn sí, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[2]

Àwo-orin akọ́kọ́ tí Ishola ṣe jáde ní ọdún 1948. Ní ọdún 1955, wọ́n tún orin náà gbà sílẹ̀ lẹ́yìn tí ọba Adeboye wàjà nínú ìjàmbá ọkọ̀ òfurufú kan.[3] Orin tí wọ́n tún kọ yìí mú wọn gbajúmọ si.[4] Haruna Ishola bẹ̀rẹ̀ sí kọ orin àpàlà, tí ó si tún ń gba á sílẹ̀ ní ọdún 1955, èyí sì sọ ọ́ di olókìkí si. Nínú orin rẹ, ó máa ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn òwe Yorùbá àti ẹsẹ Kuraani. Ni ọdún 1950, o fi Ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ kun orin rẹ̀, ó sì kọ orin "Punctuality is the Soul of Business" fún Decca Records.[3]

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe