Hauwa Muhammed Sadique
Hauwa Muhammed Sadique (tí wọ́n bí ní February 6, ọdún 1969) jẹ́ onímọ̀ ẹ̀rọ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti Ààrẹ ẹ̀kẹrìnlá ti Association of Professional Women Engineers of Nigeria (APWEN).[1][2] Òun ni ẹni àkọ́kọ́ láti ilẹ̀ Àríwá tó jẹ Ààrẹ ẹgbẹ́ náà.[3]
Hauwa Muhammed Sadique | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | February 6, 1969 |
Orílẹ̀-èdè | Nigeria |
Ẹ̀kọ́ | Army command children school, Kaduna
Queen Amina college University of Maiduguri Bayero university |
Organization | Nigeria society of Engineers Society of Women engineers |
Parent(s) | Abubakar & Amina Muhammed |
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀
àtúnṣeWọ́n bí Hauwa ní ọjọ́ kẹfà oṣù kejì ọdún 1969, sínú ìdílé Muhammed Abubakar, àti Amina Muhammed Shuwa.[4] Ó jẹ́ ọmọ ìlú Mafa, láti Ìpínlẹ̀ Borno, ní Nàìjíríà.[5]
Ó lọ sí ilé-ìwé alákọ̀ọbẹ̀rẹ̀ Army Command Children School ní ipinle Kaduna ní ọdún 1976. Ó sì tún lọ sí Queen Amina College, ní Kakuri fún ìwé girama. Ó gba national diploma nínú ẹ̀kọ́ Agricultural Engineering Technology, ó sì tún padà gba B.Eng ní ọdún 1994, láti University of Maiduguri.[5] Ní ọdún 2005, ó gba M.Sc nínú ẹ̀kọ́ Economics láti Bayero University.
Isẹ́ rẹ̀
àtúnṣeHauwa bẹ̀rè gẹ́gẹ́ bí i olùkọ́ ní Airforce Primary School ní Kano. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní Family Economic Advancement Programme (FEAP) nínú ọdún 1999. Wọ́n padà fi sí ẹ̀ka ẹ̀rọ ti Federal Ministry of Agriculture àti Water Resources. Ó padà di chief engineer ní dams and reservoir operations department ní Kano.
Òun ni ààrẹ ẹlẹ́ẹ̀kẹrìnlá ti Association of Professional Women Engineers ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, (APWEN) àti ààrẹ àkọ́kọ́ ti ẹgbẹ́ àwọn tó wà ní apá Àríwá. Wọ́n yàn án sípò ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kejì, ọdún 2016. Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí i financial secretary, general secretary, ex-officio àti vice-president fún ẹgbẹ́ náà.
Ó jẹ́ ọmọ-ẹgbẹ́ Nigerian Society of Engineers, Society of Women Engineers, National Institute of Cost àti Appraise Engineers, àti Council for the Regulation of Engineering ní Nàìjíríà.[6][7]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "14th Apwen President | APWEN". www.apwen.org.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "Female engineers storm Wilson Group Nsukka factory". The Sun Nigeria. 31 August 2016.
- ↑ Tofa, Aysha (18 February 2017). "The story behind Startup Kano's Women Founders Conference". She Leads Africa. Archived from the original on 2 April 2023. Retrieved 7 February 2024.
- ↑ "Page 211". My Engineers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-05-29.
- ↑ 5.0 5.1 Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs named:0
- ↑ "We shall leave no stone unturned as we project more Women to professional limelight- Engr. (Mrs.) Hauwa Sadique". My Engineers. 4 March 2016.
- ↑ "Who is Engr Hauwa Muhammed Sadique, the new Nigerian Women Engineers' President?". My Engineers. 7 February 2016.