Henry McNeal Turner (February 1, 1834 – May 8, 1915) je olusoagutan-rere, oloselu, ati bisoobu apaguusu akoko fun Ijo Metodisti Olusoagutan-rere ara Afrika; o je asiwaju ni ipinle Georgia nipa isakojo awon ijo olominira awon alawodudu ni Amerika leyin opin Ogun Abele ara Amerika.[1] O je bibisaye ni ipinle South Carolina, Turner ko lati mooko mooka ko to di oniwaasu ijo Metodisti. O darapo mo Ijo AME ni St. Louis, Missouri ni odun 1858, nibi to ti di olusoagutan-rere; leyin re o tun se oniwaasu ni Baltimore, Maryland ati Washington, DC.

Henry McNeal Turner ninu aso oniwaasu

Ni odun 1863 lasiko Ogun Abele ara Amerika, Turner je yiyansipo bi oniwaasu alawodudu akoko awon omo ologun United States Colored Troops. Leyin eyi, won tun yansipo si Freedmen's Bureau ni Georgia. O gunle si ilu Macon, Georgia nibi ti won ti diboyan si ileasofin ipinle na ni 1868 nigba Reconstruction. O ko opo Ijo AME si Georgia leyin ogun. Ni odun 1880 won diboyan bi bisoobu apaguusu akoko fun gbogbo Ijo AME. Nitori iwa eleyameya ati nitori awon ofin Jim Crow ti won se ni kaakiri Guusu ni opin orundun okandinlogun, Turner bere si ni se itileyin fun isetolomoorile-ede alawodudu ati ikorapada awon alawodudu lo si Afrika. Ohun ni eni pataki akoko to seyi ni opin orundun okandinlogun ko to di pe o gboro leyin opin Ogun Agbaye Akoko.


Itokasi àtúnṣe