Humuani Amoke Alaga, (1900 - 29 January 1993)ti gbogbo eniyan mọ si Mama Humuani Alaga jẹ ọmọ ilu Ibadan, ni ipinle Nigeria. A bi ni ọdun 1900 ni ilu Ibadan, Nigeria. Humani jẹ olufilọ ati olutaja alainikankan ti o wa sinu iṣowo ọrọ. O ko awọn alainitelorun awọn obinrin ni ọdun 1938 lati beere fun iye owo ti o dọgba ati ipo iṣẹ ti o dara julọ fun awọn obinrin. O jẹ ikan ninu awon oludasile ti igbimọ awọn awujọ awọn obirin ti ipinle ni ọdun 1959 [1] . O tun da Isabatudeen Women's Society ni ọdun 1958. [2]. O ku ni Oṣu Kini, Ọjọ mokandilogbon, Ọdun 1993 ni Ibadan .

Ni ibẹrẹ aye àtúnṣe

A bi Humuani si ilu Ibadan ni odun 1900. Oruko baba re si je Alfa Alaga ti o je alufaa Musulumi ati oluṣowo, iya re si je Asmau Ladebo Alaga. Humani ni abikẹhin ninu idile re. O ni egbon meta, obinrin meji ati okunrin kan. O beere si ni ta oja aso ati ileke ni igba ti o kere gan. O ṣe igbeyawo ni igba ti o pe ọmọ ọdun mejidinlogun.

Ise àtúnṣe

Humuani bẹrẹ owo rẹ nipa tita aso, lẹyin igbeyawo rẹ ni ọdun 1925. Lẹhinna o ṣii itaja kan laarin 1928 ati 1929 o si di oniṣowo fun awọn ile-iṣẹ miiran. O di adari awọn ti wọn ta aṣọ ni ọdun 1934 ni ọja Gbagi ni ilu ibadan. O wa laarin awon oludasile egbe Ifelodun ni ọdun 1930. O da egbe Isabatudeen silẹ ni ọdun 1958.[3][4] Ni ọdun 1958, lẹhin igbati wọn ko gba ọmọ re obirin si ile-iwe Kristiani, oun pẹlu awọn obinrin mọkanla miiran da awujọ kan ti o gba orukọ Isabatudeen Society (WA)) lati ṣẹda ile-iwe alakoko kan fun awọn ọmọbirin. O da ipilẹ ile-ẹkọ giga ọmọbirin Isabatudeen.[5]

Ijajagbara àtúnṣe

Awọn Obinrin Iṣowo Aṣọ ni ọdun 1938 se atako si awọn oniṣowo ara ilu Lebanoni ti n ṣe bi alarina ninu iṣowo asọ. Humani se atako si awọn oniṣowo ara ilu Lebanon to ta ọja ni aarin awon ibi ti o ye ki awọn oloja ibilẹ wa. Nipa atako yi ni o pada yori si ṣiṣẹda National Council of Women's Societies (NCWS) ni ọdun 1959.[6] Ni ọdun 1953, o dari Ẹgbẹ Ile-iṣẹ aṣọ ti Ilu Ibadan si igbogunti lodi si gbigbe ọja Dugbe lọ si ibi titun. Awọn alatako lọ si afin ọba lai wọ bata, wọn si sọ fun ọba pe ko gbọdọ gbe ọja na kuro. O tun mu awọn obinrin ọjà lọ si aaye gomina lati fi ehonu han ni pipa nipa bi awọn ologun se pa awọn alatako ni ọdun 1978. O tun ṣe iṣeduro fun owo dogba fun okunrin ati obinrin nigba ibẹwo re si Gomina Ipinle.

Awọn itọkasi àtúnṣe

  1. "NCWS prioritises better women representation » Features » Tribune Online". Tribune Online. 19 May 2017. 
  2. Uthman, Ubaydullah a. Y. O. D. E. J. I. "IBRAHIM OLATUNDE UTHMAN MUSLIM WOMEN IN NIGERIA. THE POSITION OF FOMWAN AND LESSONS FROM ISLAMIC MALAYSIA" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2018-10-14. Retrieved 2020-04-30. 
  3. Oloyede, Ishaq O. (1 July 1987). "The council of Muslim youth organizations of Oyo state in Nigeria: origins and objectives". Institute of Muslim Minority Affairs. Journal. pp. 378–386. doi:10.1080/02666958708716045. 
  4. "Humuani’s life is a pride to Muslims — Jadesola Oyewole". Vanguard News. 27 February 2014. 
  5. "Gbadamosi hails Humuani Alaga". Vanguard News. 13 March 2014. 
  6. https://digitalcommons.kennesaw.edu/cgi/viewcontent.cgi?article=1047&context=jgi.  Missing or empty |title= (help)