Ibikunle Amosun

Olóṣèlú

Ọjọ́ karùndílọ́gbọ̀n oṣù Ṣẹrẹ ọdún 1958 ní wọ́n bí ọ̀kan lára àwọn olóṣèlú orílẹ̀-èdè Nàíjíríà tí ó ti fi ìgbà kan jẹ gómìnà ìpínlẹ̀ Ogun rí, Ìbíkúnlé Amósùn[1], bẹ́ẹ̀ náà ni ó jẹ sẹ́nátọ̀ orílẹ̀-èdè Nigeria rí léèmejì. Oṣù Igbe 2003 sí oṣù Igbe 2007 ní Ìbíkúnlé fi jẹ sẹ́nẹ́tọ̀ fún agbèagbè àrin gbùgbù ìpínlẹ̀ Ogun, orílẹ̀-èdè Nàíjíríà. Ó di gómìnà ní ìpínlẹ̀ Ògùn lábẹ́ àsíá ẹgbé ACN ní ọdún 2011 léyìn tí ó fìdí rẹmi ní ìgbà àkọ́kọ́ tó díje dupò.[2][3] Ó díje dupò fún ipò gómìnà fún sáà kejì ní abẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, lẹ́yìn tí ó wọlé, wọ́n ṣe ìbúra fún un ní ọjọ́ kankàndílọ́gbọ̀ ọṣù Èbìbí ọdún 2015.[4]

Ìtọ́kasí.Àtúnṣe

  1. "Biography of Ibikunle Amosun; Accountant; Ex-Governor; Politician; Senator; Ogun State Cebebrity". biography.hi7.co. Retrieved 2022-03-30. 
  2. "Ibikunle Amosun: An enigma @ 60". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-01-24. Retrieved 2022-03-10. 
  3. "Ibikunle Amosun of ACN wins Ogun State". InDepth Nigeria. April 27, 2011. Retrieved 2011-04-29. 
  4. "How we received ammunition from Amosun, by Ogun police command". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-06-28. Retrieved 2022-02-21. 
Àṣìṣe ìtọ́kasí: <ref> tag with name "self" defined in <references> is not used in prior text.