Ibrahim Gambari

Olóṣèlú

Ibrahim Agboola Gambari, CFR tí wọ́n bí ní ọjọ́ Kẹrìnlélógún osu Kẹta, ọdún 1944(24-03-1944) ní ìlú Ìlọrin, ní Ìpínlẹ̀ Kwara, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, jẹ́ olórí àwọn òṣìṣẹ́ (Chief of Staff) aṣẹ̀ṣẹ̀-yàn Ààrẹ Muhammadu Buhari.[1]. Kí ó tó di àsìkò yìí, ó jẹ́ onímọ̀ àti aṣojú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó ti fi ìgbà kan jẹ Mínísítà fún Iṣẹ́ Òde láàrín ọdún 1984 àti 1985. Bákan náà, ó jẹ́ aṣojú United Nations ( UN) , ti ó si tún jẹ́ akọ̀wé àpapọ̀ Ban Ki-moon yàán gẹ́gẹ́ bí Alága àti agbẹnusọ fún Ìgbìmọ̀ àjọ Adúláwọ̀ nínú àjọ United Nations fún ní àárín Darfur ní ọdún 2010. [2] Òun ni Olùgbani nímọ̀ràn pàtàkì lórí International Compact pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Iraq àti àwọn ọ̀rọ̀ mìíràn fún Akọ̀wé-Gbogbogbò ti Àjọ Àgbáyé. Ó ti kọ́kọ́ ṣiṣṣ lábẹ́ Akọ̀wé-Gbogbogbò Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé (USG) ní Ẹ̀ka ti Ìṣèlú (DPA). Wọ́n yàán ní oṣù Kẹ̀wá ọdún 2005, ó si bẹ̀rẹ̀ ṣẹ́ naa.

Àwòrán Ibrahim Gambari

On March 4, 2013, Ibrahim Gambari was named by the Kwara State Governor, AbdulFatah Ahmad, as the pioneer chancellor of the Kwara State University, making him the ceremonial head of the university who presides over convocations to award degrees and diplomas and also supports the vision and mission of the university in all respects, including fundraising, social, economic and academic goals. As a university that continues to gain credence as a community development university with world class standards, the selection of Gambari is expected to give the institution additional international boost and recognition. Gambari is also co-chair of the Albright-Gambari Commission.

Ẹ̀kọ́ rẹ̀

àtúnṣe

Gambari lọ sí Kings College Lagos . Lẹ́yìn náa, Ó lọ sí Ilé-ẹ̀kọ́ ìmọ̀ Okòwò ti Ìlú Lọndọnu níbi ti Ó ti gba B. Sc. (Ẹ̀kọ́ Ìṣòwòeto) (1968) Ti ó si gba dìgírì nínú International Relation. Ó tún gba oyè Ìmọ̀ MA (1970) àti Ph. D. (1974) láti Fásitì Columbia, ní ìlú New York, ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà nínú Ìmọ̀-ọ̀rọ̀ Ìṣèlú àti International Relation.

Ìgbòkègbodò iṣẹ́ àti ẹ̀kọ́ rẹ̀

àtúnṣe

Gambari bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ olùkọ́ rẹ ní ọdún 1969, ní University University of New York ṣáájú Ki ó to ṣiṣẹ́ ní University of Albany . Lẹ́yìn náà, ṣiṣẹ́ olùkọ́ ní University Ahmadu Bello, ní Zaria, Ìpínlẹ̀ Kaduna, Ilé-ẹ̀kọ́ gíga keji tí ó tóbi jùlọ ní ilẹ̀ Afíríkà. Láti ọdún 1986 sí 1989, ó jẹ́ Olùkọ́ Alábẹ̀wò sí àwọn Ilé-ẹ̀kọ́ gíga mẹ́ta ní ìlú Washington, DC : Ile-iwe Johns Hopkins ti Iwadi International, University Georgetown ati Ile-ẹkọ Howard . Ó tún jẹ́ akópa nínú iṣẹ́ ìwadi ní Brookings Institution ní Washington DC àti onímọ̀ ní Bellagio Study, àti Ilé ìwádí Ìmọ̀ Rockefeller ní Ìlú Italia . Wọ́n fun ní oyè ti gba ni ọwọ, o jẹ honoris causa , tí ó jẹ́ oyè Dókítà ti Humane lẹ́tà (D.Hum). Litt.) Láti University of Bridgeport . Ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ti Ìgbìmọ̀ Onímọ̀-akọọ́lẹ ti Johns Hopkins University. Ìjọba orílẹ̀ èdè Nàìjíríà fi oyè Commander OF Federal Republic (CFR) da lọ́lá

Àwọn ìjápọ̀ ìta

àtúnṣe
  1. "Buhari Appoints Ibrahim Gambari as Chief of Staff". THISDAYLIVE. 2020-05-12. Retrieved 2020-05-12. 
  2. Onasanya, Angelicus (2010). Ibrahim Agboola Gambari : the man for all challenges. S.l.: Xilibris Corp. ISBN 9781453532126.