Ijeoma Lucia Ojukwu
Ijeoma Lucia Ojukwu jẹ́ ọmọbìnrin tí a bí ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kejìlá ọdún 1966 ní Kaduna, ní ilẹ̀ Nàìjíríà. Ó kọ́kọ́ gba satífíkéètì òye (WAEC) àkọ́kọ́ rẹ̀ ní ọdún 1985. Ó jẹ́ Adájọ́ Ilé-ẹjọ́ gíga ti ìjọba àpapọ̀ ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó wá láti ìpínlẹ̀ Abia. [1]
Ayé Rẹ̀
àtúnṣeArábìnrin náà wá láti Akuma ní ìjọba ìbílẹ̀ ìwọ̀-oòrùn Oru ní ìpínlẹ̀ Imo, ó sì tì jẹ́ ìyàwó pẹ̀lú Ọ̀jọ̀gbọ́n Ernest Ojukwu, SAN tí ó jẹ́ ọmọ ìlú Isuikwuato ní ìpínlẹ̀ Abia. [2] Ó sì ti bímọ márùn-ún. [1]
Ìrìn Àjò Iṣẹ́ Rẹ̀ Gẹ́gẹ́ Bí Adájọ́
àtúnṣeOnídájọ́ Ojukwu gbajúgbajà fún bí ó ṣe ṣe ìtọ́jú ẹjọ́ Omoyele Sowore, Akòròyìn Nàìjíríà àti Àpéjọ #RevolutionNow àti olùjẹ́jọ́ rẹ̀, Olawale Bakare, ṣe olórí ilé-ẹjọ́ 5 ní agbègbè Abuja ti ilé-ẹjọ́ náà. A pè é sí ẹgbẹ́ adájọ́ (Bar) ní ọdún 1990 àti pé ó ní òye Másítà ní Òfin (LLM).
Ìrìn-àjò rẹ̀ lórí ibùjókòó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú yíyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Alákoso Àgbà kejì ní Ilé-ìgbìmọ̀ Ìdájọ́ Ìpínlẹ̀ kan ní Oṣù Kẹfà ọdún 1996 níbití ó ti ṣiṣẹ́ nípasẹ̀ àwọn ipò títí di Oṣù Kìíní ọdún 2006 nígbà tí a yàn-án ní Olóyè Mágísíréètì ìtẹ kìíní. [2]
Àwọn Ìtọ́ka Sí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 "OJUKWU, Lucia Ijeoma". Biographical Legacy and Research Foundation. 2020-01-06. Retrieved 2023-03-12.
- ↑ 2.0 2.1 "Meet The Two Female Federal Judges Transferred To Calabar - CrossRiverWatch". CrossRiverWatch. 2021-03-16. Archived from the original on 2023-03-12. Retrieved 2023-03-12.