Ijteba Nadwi
Muḥammad Ijteba Nadwi (29 September 1933 – 20 June 2008) jẹ́ onímọ̀ Mùsùlùmí ti orílẹ̀-èdè India, tí ó sì tún fìgbà kan jẹ́ olórí ẹ̀ka ẹ̀kọ́ èdè Lárúbáwá ní ilè iwè giga ti Jamia Millia Islamia, Kashmir àti ilè iwè giga Allahabad[1].
Muḥammad Ijteba Nadwi | |
---|---|
Born | Majhawwa Meer, Basti, British India | 29 Oṣù Kẹ̀sán 1933
Died | 20 June 2008 New Delhi | (ọmọ ọdún 74)
Institutions | Jamia Millia Islamia, Kashmir University, Allahabad University |
Alma mater | Darul Uloom Nadwatul Ulama |
Notable awards | Presidential Certificate of Honor, 1991 |
Nadwi kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní Darul Uloom Nadwatul Ulama, Damascus University àti Aligarh Muslim University. Ó jẹ́ òǹkọ̀wé èdè Lárúbáwá àti Urdu, ó sì kọ àwọn ìwé bíi: Abul Hasan Ali Nadwi: al-Daaiya al-Hakeem wa al-murabbi al-Jaleel àtiIslam aur Huquq-e-Insani[2].
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeBàba bàbá Ijteba Nadwi tí ń ṣe Sayyid Jafar Ali jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Sayyid Ahmad Shaheed.[3] Ó kópa nínú ogun ìlú Balakot ní ọdún 1831 lẹ́yìn náà, ó kó lọ sí ìlú Basti, Uttar Pradesh.[3]
Ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, osù kẹsàn-án, ọdún 1933 ni a bí Nadwi ní ìlú Majhawwa Meer, tó jẹ́ ìlú kan ní apá Basti district.[2] Ó bẹ̀rrẹ̀ ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Darul Uloom Nadwatul Ulama, ó sì gboyè ní "dars-e-nizami" ní ọdún 1955.[3] Ó gboyè B.A nínú ẹ̀kọ́ lítíréṣọ̀ èdè Lárúbáwá ní ilè iwè giga ti Damascus ní́ ọdún 1960,[2][3] àti oyè M.A (1964) àti oyè PhD (1976) ní Aligarh Muslim University.[2][1] Díè nínú àwọn olùkọ́ rẹ̀ ni: Mustafa al-Siba'i, Hasan Habanaka, Ali al-Tantawi, Abul Hasan Ali Nadwi and Rabey Hasani Nadwi.[1][4]
Iṣẹ́ rẹ̀
àtúnṣeWọ́n yan Nadwi sípò olùkọ́ èdè Lárúbáwá, lítíreṣọ̀ àti òfin Islam ní Darul Uloom Nadwatul Ulama lọ́dún 1960.[5] Ní ọdún 1965, ó dara pọ̀ mọ́ ẹ̀ka ẹ̀kọ́ èdè Lárúbáwá, Iranian àti ẹ̀kọ́ Islam[lower-alpha 1] ti Jamia Millia Islamia gẹ́gẹ́ bíi ọmọ egbé èka náà, lẹ́yìn náà, wọ́n yàn án sípò ọ̀jọ̀gbọ́n.[5]
Ní ọdún 1979, wọ́n yan Nadwi sípò ọ̀jọ̀gbọ́n ní Imam Muhammad ibn Saud Islamic University. Ó ṣiṣẹ́ olùkọ́ ní Islamic University of Madinah títí wọ ọdún 1987, ó sì padà lọ sí ìlú India ní ọdún 1987.[5] Ó jé rector Jamiat ul-Hidaya ní ìlú Jaipur fún ìgbà díẹ̀ kí ó tó dara pọ̀ mọ́ ẹ̀ka èdè Lárúbáwá University of Kashmir gẹ́gẹ́ bíi ọ̀jọ̀gbọ́n àgbà ní ọdún 1988.[5] Ó padà di ọ̀jọ̀gbọ́n àgbà ní ẹ̀ka èdè Lárúbáwá ní University of Allahabad ní oṣù kẹta, ọdún 1990, láti ibẹ̀ ni ó ti fẹ̀yìntì ní ọjọ́ ọgbọ̀n, oṣù kẹfà, ọdún 1994.[5]
Iṣẹ́ lítíreṣọ̀ rẹ̀
àtúnṣeNadwi kọ àwọn ìwé bíi al-Ameer Syed Siddiq Hasan Khan: Hayatuhu wa Aasaruhu, Abul Hasan Ali Nadwi: al-Daaiya al-Hakeem wa al-murabbi al-Jaleel, al-Imam Ahmad ibn Abdul Rahim: al-maroof bih al-Shah WaliUllah al-Dehlawi, Al-Tabeer wal Muhadatha, Aurat Islam Ki Nazar Mai, Islam aur Huquq-e-Insani, Nuqush-e-Tabinda àti Tarikh Fikr-e-Islami.[9]
Àmì-èyẹ rẹ̀
àtúnṣe- Iwè ẹri ẹyẹ lati ọdọ Ààrẹ ti ilẹ India, 1991.[2]
Ikú rè
àtúnṣeNadwi kú ní ọjọ́ ogún, oṣù kẹfà, ọdún 2008 ní New Delhi, lẹ́yìn tí ó ṣe iṣẹ́ abẹ fún ọkàn rẹ̀. Wọ́n sin ín sí ibi ìsìnkú Jamia Millia Islamia.[2] Muhammad Idrees kọ Iranlọwọ Dọkita Muhammad Ijteba Nadwi si Litirèṣọ larubawa [10] Qasim Adil náà kọ Dọkita Ijteba Nadwi: Ónimimọ ti century ti ogun ni ilẹ India. [11]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 1.2 "The demise of Mawlana Sayyid Muhammad Ijteba Nadwi". Tameer-e-Hayat, Lucknow 45 (15): 30.
- ↑ 2.0 2.1 2.2 2.3 2.4 2.5 "Life Sketch of Syed Ijteba Nadwi", Al-Tabeer wal Muhadatha (in Arabic)
- ↑ 3.0 3.1 3.2 3.3 "Condolence ceremony held in the Darul Uloom Nadwatul Ulama after the demise of Professor Ijteba Nadwi". Tameer-e-Hayat 45 (15): 31.
- ↑ AHMED, MOBAROK. "Disciples of Rabey Hasani Nadwi". A study on Arabic prose writers in India with special reference to Maulana Muhammad Rabey Hasani Nadwi. Gauhati University. pp. 150–151. http://14.139.13.47:8080/jspui/bitstream/10603/115224/12/12_chapter%205.pdf.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ 5.0 5.1 5.2 5.3 5.4 "Life Sketch of Syed Ijteba Nadwi", Al-Tabeer wal Muhadatha (in Arabic)
- ↑ "Department of Arabic of JMI". Jamia Millia Islamia. Retrieved 26 September 2020.
- ↑ "The department of Islamic Studies of JMI". Jamia Millia Islamia. Retrieved 26 September 2020.
- ↑ "The Persian department of JMI". Jamia Millia Islamia. Retrieved 26 September 2020.
- ↑ Noor Alam Khalil Amini, Pas-e-Marg-e-Zindah, pp. 820–821
- ↑ National Council for Promotion of Urdu Language. "NCPUL SANCTION ORDER" (PDF). urducouncil.nic.in. p. 54. Retrieved 3 April 2020.
- ↑ "Revised Self study Report, May-2016" (PDF). zakirhusaindelhicollege.ac.in. Zakir Husain Delhi College. p. 224. Archived from the original (PDF) on 13 July 2021. Retrieved 3 April 2020.
Àṣìṣe ìtọ́kasí: <ref>
tags exist for a group named "lower-alpha", but no corresponding <references group="lower-alpha"/>
tag was found