Ilá Alásèpọ̀
Ilá Alásèpọ̀, ilá jẹ́ ọ̀rọ̀ Yorùbá fún Okra ní Èdè Gẹ̀ẹ́sì, nígbà tí Àsèpọ̀ túmọ̀ sí Concoction lédè Gẹ̀ẹ́sì àmọ́ tí a bá ṣe ògbufọ̀ rẹ̀ lọ́nà tààrà, ó túmọ̀ sí "To cook together". Ilá alásèpọ̀ tún lè jẹ́ àdàpọ̀ ilá. Ó jẹ́ oúnjẹ aládùn kan tó gbajúmọ̀ gan-an láàárín àwọn ẹ̀yà Yorùbá tó wà ní ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà.[1] Nínú àṣà Yorùbá, wọ́n sábà máa ń se ilá pẹ̀lú ìjẹ. Òtítọ́ ibẹ̀ pé àwọn èròjà tí ó máa ń wà nínú ìjẹ máa ń wà nínú ọbẹ̀ náà fúnra rẹ̀, èyí mú kí ọbẹ̀ yìí jẹ́ ọbẹ̀ tí kò lápọn fún àwọn ọmọ Yorùbá ọlọ́rọ̀. Àwọn kan gbà pé Ilá alásèpọ̀ jẹ́ irúfẹ́ oúnjẹ tí a máa ń se nígbà tí a kò bá lówó lọ́wọ́.[2]
Ohun tó jẹ́ ìpinnu fún ilá tó da ni bí ó ṣe yọ̀ tó. Ìdí yìí ni àwon kan fi máa ń fi káún sínú ilá bí wọ́n bá ń sè é.[2]
Ilá gẹ́gẹ́ bí ọbẹ̀ àti ilá alásèpọ̀
àtúnṣeOrísìí ọ̀nà ni wọ́n máa ń gbà se ilá. Ní Nàìjíríà, ọbẹ̀ ilá jẹ́ oúnjẹ aládùn, ó sì gbajúmọ̀ láàrín àwọn Igbo, Yorùbá, Efik, Hausa, àti àwọn ẹ̀yà Nàìjíríà míràn. Ọbẹ̀ ilá yàtọ̀ sí ilá alásèpọ̀ tí a fi ìkòkò kan ṣe pẹ̀lú oríṣiríṣi nínú. A máa ń se obẹ̀ ilá láti fi Omi Ọbẹ̀ tí ó ní oríṣiríṣi nǹkan kún un.[3]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Jemimah, Sisi (2015-10-30). "NIGERIAN OKRO SOUP RECIPE". Sisi Jemimah. Retrieved 2024-11-25.
- ↑ 2.0 2.1 "Ila Asepo (Alasepo) Recipe". 9jafoodie. 2012-06-24. Retrieved 2024-11-25.
- ↑ "Plain Okro Soup (Ila)". The Pretend Chef. 2017-06-01. Retrieved 2024-11-25.