Ile Ìjoba Songhai, tàbí Ile Ìjoba Songhay, je ile-ijoba ni iwoorun Afrika ní ìgbàkan rí. [3]Lati ibere orundun 15th titi de opin orundun 16th, Songhai je ikan ninu awon ile ìjoba Afrika tí ò tobi julo ni itan aye. Oruko re wá lati oruko awon eya eniyan to siwaju nibe, eyun awon Songhai. Oluilu re wa ni ilu Gao, nibi ti ile-ijoba Songhai kekere kan ti wà lati orundun 11th. Ibujoko agbara re wa ni koro apa Odo Oya ni orile-ede Niger loni ati Burkina Faso.