Ilawe Èkìtì

(Àtúnjúwe láti Ilawe Ekiti)

Ilawe Ekiti ( ilawe tabi ilawe-Ekiti ) jẹ́ ìlú ní ìpínlẹ̀ Èkiti ní orílẹ̀-èdè Naijiria.Ní ọdún 1995, àwọn olùgbé ìlú Ilawe jẹ́ 179,900 [1] Àwọn ipò-ìdojúkọ agbègbè náà jẹ́ 7° 35' 60 N ati 5° 5' 60 E.

Ilawe Èkìtì

Agbègbè

àtúnṣe

Ilawe Ekiti pín sí oríṣi ìlú mẹ́jọ.

Ọba aládé

àtúnṣe

Ọba tí ó wà lórí oyè ní Ilu Ilawe Ekiti ni Ọba Adebanji Ajibade Alabi (Afuntande 1). Ó gorí ìtẹ́ ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kẹrin ọdún 2012, ó sì gba ìjọba lọ́wọ́ Ọba Joseph Ademileka. [2]

Ìfarahàn ti Kìrìsìtẹ́ẹ́nì ní Ilawe

àtúnṣe

Láti ọdún 1890 ni àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run ti ń wá bí wọ́n ṣe máa ń wọ ilẹ̀ Yorùbá tí ó jẹ́ apá Ìwọ̀-oòrùn nígbà náà. Síwájú ìgbà yìí, àwọn ará Ìláwe ní igbàgbọ́ dájú dájú nínú àwọn òrìṣà ilẹ̀ Yorùbá.

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Ilawe Ekiti". Encarta. Microsoft. http://encarta.msn.com/encyclopedia_761583598/Ilawe_Ekiti.html. Retrieved 2007-01-11.  Archived 2005-03-23 at the Wayback Machine.
  2. "Disposition List Of Traditional Rulers As At 1st July, 2012". Archived from the original on 2017-05-04. https://web.archive.org/web/20170504135659/http://ekitistate.gov.ng/administration/local-govt/4972-2/.