Ìlú-Ìjélè

(Àtúnjúwe láti Ilu Ijele)

Ọsọbà Adeniyi Johnson

Adeniyi Johnson

Johnson

Òrìṣà Ògún Aláró Ní Ìlú Ìjélè

Oyè B.A. (Hons) Yorùbá. Department of African Languages and Literatures, Obafẹmi Awolọwọ University, Ilé-Ifẹ̀.

Orí Kìíní: Ìlú-Ìjélè Ojú-Ìwé 1-7.

àtúnṣe

Ìlú-Ìjélè jẹ́ ọ̀kan lára ìlú kéé-kéé tí ó wà ní abẹ́ Ìjọba ìbílẹ̀ Légùrù Alá ní Ìpínlẹ̀ Ògùn. Tí ènìyàn bá gba ojú ọ̀nà má-sọ-sẹ̀ wọ Ìlú Ìjélè láti Ìbàdàn Ó tó nǹkan bí kìlómítà mẹ́rìnèlò-gọ̀rún, ṣùgbọn tí a bà gba ọ̀nà Ìjẹ̀bú-òde láti Ilé-Ifẹ̀ wọ Ìlú-Ìjélè, ó tó nǹkan bí kìlómítà ọgọ́jọ.

Orí Kejì: Òrìṣà Ògún Alárọ́ àti àwọn Alàwòrò rẹ̀ ní ìlú ìjélè;

àtúnṣe

Ìtàn ìgbà ìwásẹ̀ àti bí òrìṣà yìí ṣe dé ìlú Ìjélè Ojú-Ìwé 8-16. Ìtàn ìgbà ìwásẹ̀ kan sọ wí pé lẹ́hìn ìgbà tí Olódùmarè dá ilé ayé tán, ó rán ọ̀kànlénírínwó òrìṣà látu lọ tún ilé ayé tó. Ńú àwọn òrìṣà yìí ní a ti rí Ògún, Òòsààálá, Èṣù,àti Òrúnmìlà.

Ìgbàgbọ́ àwọn ará ìlú Ìjélẹ̀ nípa òrìṣà yìí Ojú-Ìwé 17-22.

àtúnṣe

Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ẹ̀rín ò yàtọ̀ títí ó fid ó ìlú Èèbó, bẹ́ẹ̀ ni jákèjádò ilẹ̀ Yorùbá kò ṣí ibi tí wọn kò ti mọ Ògún sí Òrìṣà pàtàkì tí wọn sì ń fi ìgbàgbọ́ wọn hàn nínú agbára rẹ̀, nípa bíbọ òrìṣà yìí àti fífi ohun tí ó tọ́ àti tí ó yẹ fún un.

Oúnjẹ tí Ògún Alárọ́ fẹ́ràn àti Èèwọ̀ òrìṣà yìí Ojú-Ìwé 23-27.

àtúnṣe

Oríṣìíríṣìí òrìṣà ilẹ̀ Yorùbá ló ní oúnjẹ tirẹ̀ tí ó fẹ́ràn. Fún àpẹẹrẹ àmàlà àti gbẹ̀gìrì ni oúnjẹ Ṣàngó, epo àti iyò ni oúnjẹ Èṣù. Ṣùgbọ́n ògún ní tirẹ̀ àgíríìgbà (ajá) ẹmu àìran, àkùkọ adìyẹ, àtóró (omi tutu)

Ilé arọ́ àti ohun tí ó wà ní ojúbọ rẹ̀ Ojú-Ìwé 28-30.

àtúnṣe

Yorùbá bọ̀ wọ́n ní “Ògún dé Ilé-arọ́ ó jọba ní ilé – arẹ́, Ògún yà ní Ìrè, Ó mẹmu ní ìlú Ìrè”. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí tí mo ṣe nípa ilé arẹ́ yìí lẹ́nu alàgbà Ṣúndè Igbósànyà, ó fí yé mi wí pé ibi tí wọn ti ń bọ Ògún Alárẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó tẹ ìlú wọn dó ṣe fi lé lẹ̀ ni wọ́n ń pè ní Ilé – arọ́.

Àwọn Alàwòrò Ojú-Ìwé 31-34

àtúnṣe

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ní ọjọ́ ọdún òrìṣà yìí tẹmọdé tàgbà, tọkùnrin, tobìnrin, tarúgbò, tò pìjẹ̀, tẹrú, tọmọ, tonílé, tàlejò ni ó máa ń lọ́wọ́ nínú ayẹyẹ ọdún Ògún Alárọ́ yìí ṣíbẹ̀ a kò ṣàìrí àwọn ojùwá tí ó jẹ́ wí pé kò-ṣe-má-nìí ni ipa tí wọ́n kó ní ọjọ́ ọdún náà àti kíkàn sí Òrìṣà yìí, Àwọn méjì ni ó ṣe pàtàkì jù nínú awọn ojúwá yìí.

Orí Kẹta: Ọdún Ògún Alárọ́ ní Ìlú Ìjélè Ojú-Ìwé 35-37.

àtúnṣe

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé orìíṣìí ọdún bí ọdún Jìgbò. Orò àti ilé-ajé ni wọ́n ma ń ṣe ní ìlú ìjélè, èyí tí ó ṣe pàtàkì jù tí àwọn ọmọ ìlú nílé lóko máa ń péjú ṣe ni ọdún Ògún Alárọ́. Ìwádìí tí mo ṣe fi hàn pé oṣù kéje tàbí ìkẹjọ ni wọ́n máa ń bọ òrìṣà yìí.

Ọjọ́ Ọdún gan-an Ojú-Ìwé 38-41.

àtúnṣe

Ní kùtù hàì ọjọ́ ọdún gan an ni àwọn ọmọ ìlú lókùnrin lóbìnrin yóò ti jí lọ ṣí ọ̀dọ̀ Olú-Arọ́ lọ kí i fún ọdún, kí wọn ṣì gbàdúrà fún wí pé kí ó ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún láyé. Bí wọn bá ti ṣe èyí tán ni wọ́n yóò padà ṣí inú ilé wọn láti lọ gbáradì fún àwọn àlejò wọn tí yóò máa wọ̀ ìlú wá bá wọn ṣe ọdún.

Bíbọ Ògún ní Ọjọ́ Ọdún Ojú-Ìwé 41-55.

àtúnṣe

Bí Ògún àjọbọ ṣe wà fún gbogbo ọmọ ìlú, ni àwọn ìdílé kọ̀ọ̀kan ní Ògún tí wọn tí wọn ń bọ ní ọjọ́ náà. Mo til`ẹ gba ohùn ṣílẹ̀ nínú ìwúre tí àwọn ìdílé Ọ̀nàbólújọ ṣe ní ọjọ́ ọdun náà. Èyí sì hàn nínú àkójọpọ̀ oríkì, orin àti ìwúre òrìṣà yìí ní-wájú.

Orí Kẹrin: Oríkì Ògún Alárọ́ ní Ìlú Ìjélẹ̀ Ojú-Ìwé 56-58.

àtúnṣe

Ní àìko ní fi igbá kan bọ ìkan nínú, bí gbogbo òrìṣà ilẹ̀ Yorùbá ti ní orìkì tí wọn fi ń kì wọ́n kí orí wọn ṣì wú láti ṣe ohun tí ẹni náà ń fẹ́ ni òrìṣà Aláré náà ni tirẹ̀ ní ìlú Ìjélẹ̀. Bí Ògún ṣì ṣe ṣe pàtàkì ṣí ni a máa ń gbọ́ nínú oríkì rẹ̀ ní àkókò ọdún rẹ̀.

Kókó inú oríkì Ògún Alárọ́ tí a kó jọ (a) Jíjúbà Ojú-Ìwé 58-59.

àtúnṣe

Oríṣìíríṣìí kókó ni wọ́n mẹ́nu bà nínú oríkì òrìṣà yìí. Kò ṣì ṣí ètò kan pàtó ti wọn ń tẹ̀ lé lórí èwo ni yóò ṣíwájú àti èyí tí yóò tẹ̀ lé e. Ibà jíjú yìí maa ń wáyé nígbà tí wọn bá kọ́kọ́ kó igbá eto orin ọdún síta ti wọn yóò máa kọ kiri ní àdúgbò kọ̀ọ̀kan ní ìlú.

(b) Ìtán Ojú-Ìwé 59-60.

àtúnṣe

Nínú oríkì Ògún oríṣìíríṣìí ìtàn ni ó máa ń jẹ jáde níbẹ̀. Àwọn ìtàn yìí sì máa ń sọ nípa ìwà agbára tàbí nǹkan tí Ògùn ti gbé ṣe ní ìgbà ayé rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ nínú àkójopọ̀ oríkì Ògún Alárọ́ wọn mẹ́nu bà wí pé òun ni “Aṣìmalẹ” ni ila kẹtàdínláàádòje ìwúre kejì àti ìlà kìíní nínú ìwúre ìyá àfin Adénitẹhìn.

(d) Ìwúre Ojú-Ìwé 60-62.

àtúnṣe

Ìwúre jẹ́ ọ̀nà kan pàtàkì ti àwọn ará ìlú fi máa ń tọrọ nǹkan tí wọn ń fẹ lọ́wọ́ Ògún Alárọ́ ní àṣìkò ọdún rẹ̀. Tàbí kí wọn wá fi ẹ̀mí ọpẹ́ wọn hàn. Fún àpẹẹrẹ àwọn tí òrìṣà yìí ti ṣe lore kan tàbí òmíràn yóò wá san ẹ̀jẹ́ tí wọn ti jẹ́ fún un.

(e) Ìbẹ̀rú tí wọn ní fún Ògún Alárọ́ Ojú-Ìwé 62-68.

àtúnṣe

Yorùb á bọ̀ wọ́n ní bi ọmọdé bá de ibi ẹ̀rù, ó yẹ kí eru bá á. Yàtọ̀ ṣí oríkì tí wọn máa ń ki orìṣà yìí láti fi agbara rẹ hàn bákan náà ni wọ́n tún ń bẹ̀rù rẹ̀ nítorí akọni òrìṣà ni. Ìgbà púpọ̀ tí wọn bá ń bọ ni wọ́n ṣì máa ń sọ wí pé:

Iwe ti a yewo

àtúnṣe

Ọsọbà Adeniyi Johnson (1983) Òrìṣà Ògún Aláró Ní Ìlú Ìjélè Oyè B.A. (Hons) Yorùbá. Department of African Languages and Literatures, Obafẹmi Awolọwọ University, Ilé-Ifẹ̀.