Ìlú Òró
(Àtúnjúwe láti Ilu Oro)
- Lábáńbí la ti bí mi lórí omi òsà
- Ìlú se é wà lórí omi?
- Mo mò pébéèrè tí yóò kó so sí wa lókàn nù-un
- Bí n ó bá fún-un yín nídáhùn tó ye
- Ko ní yéé ko wá ní háà! 5
- Nítorí kí ni ń kó?
- Nítorí bírú èyí bá sè
- Tílùú forí omi selé
- Tómi ń be níwá, tí ń be léyìn
- Tí ń be lótùn-ún, tí ń be lósì 10
- Tó wa jé pé ìwònba ìyàngbe
- Ilè tí ń be láàárín
- Lá wá dó lé gégé bí ìlú
- Erékùsù nìlúù mi nù-un
- Erékùsù, ilè tómí yípo pátápátá poo 15
- Tí ò séni ó lè débè láìwokò ojú omi, okò olópón
- Ìyún-ùn ni pé
- Erékèsù Lábáǹbí ni mo forí solè sí
- Ibè la bí mi, tí mo forí rìn dé
- Ìrókò se wá se bí eré wá so osàn? 20
- Tí mo fi Lábáǹbì sílè dára Òró
- Ìyen ni pé
- Bawo ni mo se dará ìlú Òró?
- Èyí ò le
- Bí mo se dará ìlú Òró kò le páàpáà 25
- Ogun ló gbalé, totè gbòde kan
- Ìyen nígbà tá a bí mi
- Ń se ni rògbòdùyàn gba gbogbo sánmò lókè
- Ìlú wa ò kúkú tóbi, rébété báyìí ni
- Kò pé tí wón bí mi tógun kólùú wa terú tomo 30
- Eni tó bá mí pínkín
- Ń se ni wón ní kénu rè ya dépàkó
- Wón ní á panu mó, á yéé pera wa lára Lábáǹbí
- Wón ní látojó ùn gan-an la ti dará Òró
- Mo rò ó 35
- Mo rú u
- Mo là á
- N ò já a
- Emi la wá lè se? Emi la lè so?
- Olórun ló dá o léjó tó o fé pe kòtémilórùn un 40
- Ìyà tólúwa rè yóò je sí i, kò ní í mo ní wín-ńwín
- Àbí téni ó mádàá lówó bá ni á káwó sókè
- Òsé là á tún máaá pá?
- Àfeni tí ó se tán láti jÓlorun nípè
- Eni tó gbórí míìn pamó sílé 45
- Tí yóò fi pààrò èyí tó bá lo
- Báyìí ni mo se domo ìlú Òró
- Tí mo gbàgbé ìlú àbínibí mi
- Mo domo ìlú Òrò tán nù-un nì
- Isé ológun ni mo gbà 50
- Sóhun ló kúkú pé jù ní sáà yìí
- Mò ń gbàsé ológun tan
- Ń se nìgbéga ń tèlé ìgbéga fún mi
- Ó wá bùse gàda, ó bùse gèdé
- N làwon mèkúnnù panu pò 55
- Pé báwon olówó se ń sèjoba
- Ò táwon lórùn
- N ni won bá pòbìrìkòlò
- Tí wón gbára jo, tí wón láwon ó kòwòsí
- Sémi náà ti mobi tÓlórun ó ti bepo sí bòòlì fún mì 60
- Mo dara pò mó àwon púrúǹtù
- A réyùn àwon olówó ayé
- Àwon ajeniséni, àgbòn ìsàlè bí ìkéèmù
- Àwon wònyí wáà pàmò pò
- Wón ní ń wá solórí àwon 65
- Mo dolórí Òrò ìlú ròsòmù
- Sùgbón kò sí bá a ó ti sèfó òdú tí ò ní í rùngbé
- Isẹ́ ogun tí mo fi dolórí kò kúò lókàn-àn mi
- Àfì bí èyí kí ìlú Òró máà fè sí i lábé ìtójúù mi
- Nǹkan sì ń jé fún èmi náà 70
- Àfi bí èyí pé mo wègbo
- Àfi bí èyí pé mo fosé rarí
- Bí mo bá ìlú iwá jà, n ó ségun
- Bí mo bá tèyìn jà, n ó ségun
- Ìgbà ó wá se 75
- N ló wá dàbí èyí pé kí n dolórí gbogbo ilú
- Tí ń be ládùúgbòo tàwa
- Sùgbón àwon tí ń be ládùúgbòo mi ò ponú
- Béè ni, won ò pòdà
- Ń se láwon náà pèrò pò tí wón bá mi fìjà peétà 80
- Wón ségun, àwé, wón lémi lugbó
- Ìgbà mo dóhùn-ún
- Ìpò olá tí mo wà sì ń wù mí jojo
- Níbi táwon tó ségun mi ti ń sètò ìpíngún
- Ibé ni mo ti bé lù wón gìjà 85
- Pèlú àwon èrò wóńwé tí mo rí kó jo
- Ero won tí kò jo
- Die bín-ńtín báyìí ló kù n ségun won
- Sùgbón wón ní olópò èrò logun ń séé fún
- Eyi ni wón fi rí mi fi se ní nnkan 90
- Tí wón ráyè ségun
- Ìgbà yìí ni wón wá rù mí regbóńgbó
- Níbi ojú olómo ò to
- Ibè ni mo sá wà
- Tí mo ri i pé ìgbésí ayé mi féé
- Tí mo da gègé dé ìwé
- Pé kí n ko ìtàn ayé mi fáráyé kà.