Ìrè-Èkìtì
F.I. Ibitoye (1981), ‘Ìlú Ìrè-Èkìtì’, láti inú ‘Òrìṣà Ògún ní ìlú Ìrè-Èkìtì.’, Àpilẹ̀kọ fún Oyè Bíeè, DALL, OAU, Ifẹ̀, Nigeria, ojú-ìwé 1-3.
Ìrè-Èkìtì jẹ́ ìlú kan ní agbègbè àríwá Èkìtì ní ìpínlẹ̀ Oǹdó; èyí tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ bíbí inú ìpínlẹ̀ ìwọ̀-oòrùn àtijọ́. Tí ènìyàn bá gba ojú títì ọlọ́dà wọ ìlú Ìrè, ó rí bi kìlómítà márùndínlógójì sí Ìkọ̀lé-Èkìtì tí í ṣe olú ìlú fún gbogbo agbègbè àríwá Èkìtì. Ṣùgbọ́n ó fi díẹ̀ lé ni ogóje kìlómítà láti Ilé-Ifẹ̀. Èyiini tí a bá gba ọ̀nà Adó-Èkìtì. Nígbà tí a bá gba ọ̀nà yìí, lẹ́hìn tí a dé Ìlúpéjú-Èkìtì ni a óò wá yà kúrò ní títí ọlọ́dà sí apá ọ̀tún. Ọ̀nà apá ọ̀tún yẹn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣe ni a óò wá tọ̀ dé Ìrè-Èkìtì, kìlómítà márùn-ún ibi tí a ti máa yà jẹ́ sí ìlú Ìrè-Èkìtì.
Ara ẹ̀yà ilẹ̀ Yorùbá náà ní ilú Ìrè-Èkìtì wà. Àwọn gan-an pàápàá sì tilẹ̀ fi ọwọ́ sọ àyà pé láti Ilé-Ifẹ̀ ni àwọn ti wá. Wọ́n tún tẹnu mọ́ ọ dáradára pé ibẹ̀ ni àwọn ti gbé adé ọba wọn wa. Nítorí náà, títí di òní olónìí, Onírè ti Ìlù Ìre-Èkìtì jẹ́ ògbóǹtagi kan nínú àwọn ọba Aládé tí ó wà ní Èkìtì.
Gẹ́gẹ́ bí n óò ti ṣe àlàyẹ́ ní orí kejì ìwé àpilẹ̀kọ yìí, “Oní-èrè” ni ìtàn sọ fún wa pé wọ́n gé kúrú sí “Onírè” ti ìsìnyìí. Alàyẹ́ Samuel Johnson nínú The History of The Yoruba. sì ti fi yé wa pé nítorí oríṣìíríṣìí òkè tí ó yi gbogbo ẹ̀yà Yorùbá tí à ń pe ní Èkìtì ká, ni a ṣe ń pè wọ́n bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, orúkọ àjùmọ jẹ́ ní “Èkìtì”. Ìtàn sí tún fi yé mi pé ìlú kékeré kan tí ó ń jẹ́ “Igbó Ìrùn” ni àwọn ará Ìrè-Èkìtì ti ṣí wá sí ibi tí wọ́n wà báyìí; àìsàn kan ló sì lé wọn kúrò níbẹ̀. “Igbó Ìrùn” ti di igbó ní ìsinyìí, ṣùgbọn apá àríwá Ìrè-Èkìtì ló wà. Mo fi èyí hàn nínú àwòrán ìlú náà.
Ìṣesí àwọn ará Ìrè-Èkìtì kò yàtọ̀ sí tí àwọn ìlú Yorùbá yòókù, yálà nípa aṣọ wíwọ̀ tàbí àṣà mìíràn. Àrùn tí í sìí ṣe Àbọ́yadé, gbogbo Ọya níí ṣe. Àwọn náà kò kẹ̀rẹ̀ nípa gbígba ẹ̀sìn Òkèèrè mọ́ra nígbà tí gbogbo ilẹ̀ Yorùbá mìíràn ń ṣe èyí. Ẹsìn Ìjọ Páàdi àti ti Lárúbáwá ni a gbọ́ pé wọ́n gbárùkù mọ́ jù. Síbẹ̀síbẹ̀, wọ́n ṣì ń ráyẹ̀ gbọ́ ti ẹ̀sìn ìbílẹ̀ Yorùbá, bí ọ́ tilẹ̀ jẹ́ pẹ́ ó ní àwọn àdúgbò tí èyí múmú láyà wọn jù. Fún àpẹrẹ, mo tọka sí àwọn àdúgbò tí wọn ti mọ̀ nípa Òrìṣà Ògún dáadáa nínú àwòrán.
Èdè Èkìtì nì òdè Àdúgbọ̀ wọn. Nítorí náà, ìyàtọ̀ tí ó wà láàrin èdè Èkìtì àti ti Yorùbá káríayé náà ló wà ní tiwọn. Fún àpẹẹrẹ wọn a máa pa àwọn kóńsónàntì kan bíi ‘w’ jẹ. Wọn a pe “owó,” ‘Òwírọ̀’ “Àwòrò” ni “eó”, “ọ̀úrọ̀”, “Àòrò”. Wọ́n tún lè pa ‘h’ gan-an jẹ; kí wọ́n pe “Ahéré”ní “Aéré. Nítorí náà “Aéré eó” yóò dípò “Ahéré owó”
Nígbà mìíràn pàápàá, wọn a fi ẹyọ ọ̀rọ̀ kan dípò òmíràn, fún àpẹẹrẹ:
ira yóò dípò ará
erú yóò dípò erú
èyé yóò dípò ìyá.
àbá yóò dípò bàbá
ijọ́ yóò dípò ọjọ́
Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ, àwọn náà tún máa ń fi fáwẹ́lì ‘u’ bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀. Fún àpẹẹrẹ:
Ulé dípò Ilé
Ùrè dípò Ìrè
Ufẹ̀ dípò Ifẹ̀
Ukú dípò Ikú
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà ni èdè yìí fi yàtọ̀ si ti Yorùbá káríayé. Nítorí náà, mo kàn ṣì ń ṣe àlàyé rẹ̀ léréfèé ni, n óò tún máa mẹ́nu bá wọ́n nígbà tí a bá ń ṣe àtúpayá èdè orin Ògún. Ọ̀rọ̀ pọ̀ nínú ìwé kọ́bọ̀ ni.