Isah Misau

Alagba Nàìjíríà

Isah Misau (Tí a bí ní ọdún 1970 ní Bauchi, orílẹ̀ èdè Naijiria) jẹ́ olóṣèlú ọmọ ilẹ̀ Naijiria. Lọ́wọ́lọ́wọ́, oun ni Alága Ìgbìmọ̀ ti o nri sí ọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ ogun orí omi ní ilé Asojú Àgbà ti ilẹ̀ Naijiria.[1] Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Àgbà ní Naijiria tí ó n ṣojú aringbungbun tí Ìpínlẹ̀ Bauchi.[2][3]

Isah Misau
Chairman House Committee on Navy in Senate of Nigeria
Lọ́wọ́lọ́wọ́
Ó gun orí àga
2015
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí1970
ProfessionPolitician

Ẹ̀kọ́ àti iṣẹ́ àtúnṣe

Misau kọ́ ẹ̀kọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga olókìkí ti Ahmadu Bello University, ní Kaduna níbití Ó ti kọ́ ẹ̀kọ́ gba oyè àkọ́kọ́ (BSc) nínú ẹ̀kó nípa ìṣàkóso òwò (Business Administaration) ní ọdún 1997. Bakanna ní ọdún 2010, Ó tún gba oyè eléèkejì (MSc) nínú ìmọ̀ lórí agbófinró (Law Enforcement) láti ilé ẹ̀kọ́ gíga Ahmadu Bello University bakanna

Isah Misau bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ ní ọdún 2000 gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso òṣìṣẹ́ (Administrative Officer) ní ilé iṣẹ́ ọlọ́pà ti orílẹ̀ èdè Naijiria (Nigeria Police Force) tí Ó sì ṣiṣé gẹ́gẹ́ bi ọlọpa fún ọdún mẹwa kí ó tó di wípé Ó kọ̀wé fi iṣẹ́ sílẹ̀. Ní ọdún 2015, Misau fi ìfẹ́ hàn láti díje lọ sí ilé Ìgbìmọ̀ Asojú Àgbà láti lọ ṣojú àríngbùngbùn ti Ìpínlẹ̀ Bauchi. Misau yege nínú Ìdìbò yí ní oṣù kẹ́ta ọdún 2015 nígbà tí Ó borí Abdu Ningi, ẹni tí Ó jẹ́ igbákejì olùdarí ọmọ ẹgbẹ́ tí ó pọ̀ jùlọ. [4][5]

Àríyànjiyàn àtúnṣe

Ní oṣù kẹ́jọ ọdún 2017, Misau kojú àwọn ẹ̀sùn tí ó lágbára láti ọ̀dọ ọ̀gá àgbà pátápátá fún àwọn ọlọpa (IGP), Ibrahim Kpotun Idris. Ọ̀kan lára wọn ni ẹ̀sùn tí ọ̀gá àgbà pátápátá fún àwọn ọlọpa fi kan Misau pe Ó jẹ́ ẹni tí o ma nta ti o si ma nra Igbó (Indian hemp) lorekore.[6] Wọ́n tún fi ẹ̀sùn kan Misau pé níse ni o sá nínú iṣẹ́ ọlọpa àti wípé ó ṣe é ṣe kí ó jẹ́ wípé Ó ṣe ayédèrú lẹ́tà ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́.[7] Wọ́n ṣe àwọn àfihàn yí ní àkókò ẹ̀sùn ẹjọ́ ìṣowó mọ́kumọ̀ku tí wọ́n fí kan ọ̀gá àgbà pátápátá fún àwọn ọlọpa.[8][9] Ní oṣù kẹsan ọdún 2017, Ìgbìmọ̀ fún àwọn ọlọpa fi ẹsẹ̀ rẹ múlẹ̀ pé lẹ́tà ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ tí Misau fi sílẹ̀ ki i ṣe ayédèrú.[10]

Awọn itọkasi àtúnṣe

  1. "National Assembly is supreme, they should respect us - Sen. Isah Misau". Vanguard News. 2017-07-04. Retrieved 2020-03-17. 
  2. "Angry Youths Attack Pro-Saraki Senator Isah Misau In Bauchi". Sahara Reporters (in Èdè Baski). 2016-04-18. Retrieved 2020-03-17. 
  3. Jannah, Chijioke (2017-09-10). "What Nigerian Police would have done to me - Misau". Daily Post Nigeria. Retrieved 2020-03-17. 
  4. Ugwuanyi, Sylvester (2015-03-31). "Senate Leader defeated in Bauchi as Saraki wins in Kwara". Daily Post Nigeria. Retrieved 2020-03-17. 
  5. "Full list of 83 senators who passed vote of confidence on Saraki". Vanguard News. 2015-09-29. Retrieved 2020-03-17. 
  6. "Police declare Senator Misau wanted, say he patronises Indian hemps joints". Vanguard News. 2017-08-27. Retrieved 2020-03-17. 
  7. "Nigeria Police lied, my resignation followed due process – Senator". Premium Times Nigeria. 2017-08-28. Retrieved 2020-03-17. 
  8. Itodo, Yemi (2017-08-28). "Senator Misau hits back, insists IGP is corrupt". Daily Post Nigeria. Retrieved 2020-03-17. 
  9. "Alleged bribe for promotion: IGP drags Senator before the Senate » Latest News » Tribune Online". Tribune Online. 2017-08-24. Retrieved 2020-03-17. 
  10. "Police Commission confirms Senator Misau’s retirement letter - Nigeria and World News". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. 2017-09-06. Retrieved 2020-03-17.